Achievers University
Achievers University jẹ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga ifáfitì tí wọ́n tẹ̀dó sí ìlú Ọ̀wọ̀ ní ìpínlẹ̀ Oǹdó , lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà
Yunifásitì Achievers | |
---|---|
Established | 2007 |
Type | Ifáfitì Aládàání |
Vice-Chancellor | Onímọ̀-ẹ̀rọ Ọ̀jọ̀gbọ́n T. S. Ìbíyẹmí |
Location | Ìlú Ọ̀wọ̀, Nàìjíríà 7°10′27″N 5°35′00″E / 7.174188°N 5.583249°ECoordinates: 7°10′27″N 5°35′00″E / 7.174188°N 5.583249°E |
Campus | Ìlú-ńlá |
Website | http://www.achievers.edu.ng |
Ó jẹ́ ifáfitì Aládàání tí wọ́n dá sílẹ̀ lọ́dún 2017, tí Ìjọba Àpapọ̀ sìn fọwọ́ sí. Ó gúnwà sí àgbègbè Ìdásẹ̀n ní ìlú Ọ̀wọ̀. [1]
Ifáfitì Achievers University jẹ́ ọ̀kan lára ilé iṣẹ́ ẹ̀kọ́, the Achievers Group of Education and Training Organization, tí ó gúnwà sí ìlú Ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ọ̀gbẹ́ni Bọ̀dé Ayọ̀rìndé àti àwọn onímọ̀ nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn ní wọ́n dá a sílẹ̀. Ifáfitì yìí bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 2007 sí 2008. Àjọ tí ó ń ṣe kòkárí ètò ẹ̀kọ́ ifáfitì lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà the Nigerian National University Commission kà á sí ipò mẹ́tàléláàádọ́ta nínú àwọn Ifáfitì tó pójúwọ̀n lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́dún 2013.[2]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ http://icaci.org/documents/ICC_proceedings/ICC2005/htm/pdf/oral/TEMA2/Session%201/DR.%20M.E.%20UFUAH%202.pdf Idasen community
- ↑ "NUC names University of Ibadan number 1 in Nigeria – See list of top 100". Daily Post. April 22, 2013. http://dailypost.ng/2013/04/22/nuc-names-university-of-ibadan-number-1-in-nigeria-see-list-of-top-100/.