Adamu Abdu-Kafarati
Adamu Abdu-Kafarati (ọdún 1954–2021) jẹ́ adájọ́ ọmọ orílẹ̀ ède Nàìjíríà nígbà ayé rẹ̀. Ó fi ìgbà kan jẹ́ adájọ́ àgbà ti ilé ẹjọ́ àgbà orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1]
Adamu Abdu-Kafarati | |
---|---|
Adájọ́ àgbà, Federal High Court ti orílẹ̀ ẹ̀dẹ̀ Nàíjíría | |
Justice | |
In office 2018–2019 | |
Arọ́pò | Justice John Tsoho |
Ìpìlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ́
àtúnṣeA bí Kafarati ní ọdún 1954 sí Kwami, ìjọba ìpínlẹ̀ kan ní Ìpínlẹ̀ Gombe. Ó kàwé Prámárì ní ilé ìwé Kafarati Primary School ní áàrín oṣù Kínní ọdún 1962 sí oṣù Kejìlá ọdún 1968. Ó tún kàwé Government Secondary School, Gombe, láàrin ọdún 1969 àti 1973. Ó sì tún kàwé ní Northeast College of Arts & Science (NECAS), Maiduguri, láàrín oṣù Kẹ̀wá ọdún 1973 sí oṣù kẹfà ọdún 1975. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin ní Yunifásítì Àmọ́dù Béllò, Zaria, láti oṣù kẹwàá ọdún 1975 sí oṣù kẹfà ọdún 1978, ó kàwé gboyè nínú ìmò òfin ní Nigerian Law School, Lagos, ní ọdún 1979.[2]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeKafarati bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí State Counsel II ní Ministry of Justice ti Bauchi State. Ó jẹ́ principal state counsel ní ọdún 1987 ó sì jẹ́ igbá-kejì administrator-general kí ó tó di adájọ́ ní Federal High Court ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n osù kẹẹ̀wá ọdún 1991. Ó di adájọ́ àgbà ní Ilé ẹjọ́ àgbà orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ọjọ́ keje oṣù kẹfà ọdún 2018.[3] Adam Abdu-Kafarati fẹ̀hìntì lẹ́hìn oṣù mẹ́tàlá tí a yàn án sípò, ìyẹn nígbà tí ó pé ọmọ ọdún márùnlélọ́gọ́tá ní ọjọ́ karùnlélọ́gọ́tá oṣù keje (July 25) ọdún 2019.[4]
Ikú rẹ̀
àtúnṣeAdamu Abdu Kafarati fi ayé sílẹ̀ ní ọjọ́ kàrúnlélógún oṣù kejì (February 25) ọdún 2021, ní ìkan bi ago méje àbọ̀ ìrólẹ́ (7:30pm)
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Ex-Federal High Court Chief Judge, Kafarati, is dead". The Guardian Nigeria News – Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-02-26. Retrieved 2022-03-26.
- ↑ "Kafarati: The man, the tasks – The Nation Newspaper". thenationonlineng.net. Retrieved 2022-03-26.
- ↑ "Buhari appoints Chief Judge of Federal High Court" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-06-05. Retrieved 2022-03-27.
- ↑ "Ex- Nigerian Chief Judge, Adamu Abdu-Kafarati, is dead." (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-02-26. Retrieved 2022-03-26.