Adebayo Alao-Akala
Christopher Adébáyọ̀ Àlàó Akálà ni wọ́n bí ní ọjọ́ kẹ́ta oṣù kẹfà ọdún 1950, ó sì kú ní ọjọ́ Kejìlá oṣù kínní ọdún 2022 (1950 - 2022)[1]. Christopher Adébáyọ̀ Àlàó Akálà jẹ́ olóṣèlú àti Gómìnà nígbà kan rí ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[2] Ní ọdún 2019, ó díje dupò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lẹ́ẹ̀kan si lábẹ́ ẹgbẹ́-òṣèlú Action Democratic Party(ADP) ṣùgbọ́n ó yára dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ All Progressive Party(APC) kí ìdìbò ó tó wáyé.[3]
Christopher Adebayo Alao-Akala | |
---|---|
Gomina Ipinle Oyo | |
In office 29 May, 2007 – 29 May, 2011 | |
Asíwájú | Rasheed Ladoja |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 03-06-1950 Ipinle Oyo, Nigeria |
Aláìsí | 12-01-2022 |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | PDP |
Christopher Adébáyọ̀ Àlàó Akálà jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ lati oṣu karun-un ọdun 2003 si oṣu kinni ọdun 2006 ti o tẹle Rashidi Ladoja nigba ti wọn yọ ọ lẹnu, ṣugbọn nigba to tun pada si ọfiisi nigba ti Ladoja pada sipo ni oṣu kejila ọdun 2006. Ni ọdun 2007 ni wọn dibo yan gomina, o tun di ibo lodun 2011 fun Abiola Ajimobi ti Action Congress of Nigeria. O ku ni ọjọ 12, Oṣu Kini, ọdun 2022.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Alao-Akala, ex-Oyo governor, is dead". Premium Times Nigeria. 2022-01-12. Retrieved 2022-01-22.
- ↑ "Christopher Alao-Akala". Wikipedia. 2006-01-12. Retrieved 2019-09-25.
- ↑ "Alao-Akala dumps opposition coalition, aligns with APC". Punch Newspapers. 2015-12-15. Retrieved 2019-09-25.