Adedotun Aremu Gbadebo III
Adedotun Aremu Gbadebo lll (tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹsan ọdún 1943) ní Aláké ti ilẹ̀ Ẹ̀gbá lọwọlọwọ bayi. Ẹ̀gbá jẹ́ ẹ̀yà kan ní ìlú [[Abẹ́òkuta]], orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó ti wà lórí oyè láti ọjọ́ kejì oṣù kẹjọ ọdún 2005.
Alake Adedotun Gbadebo | |
---|---|
Alake of Egba | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 2 August 2005 | |
Asíwájú | Oba Oyebade Lipede |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 14 Oṣù Kẹ̀sán 1943 Abeokuta |
Ìbẹ̀rẹ̀ Ayé
àtúnṣeA bí Gbádébọ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹsan ọdún 1943 sínú ìdílé ọba ti Láarún. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ọmọ Aláké kẹfà ti ìlú Ẹ̀gbá, Ọba Gbádébọ̀, ẹni tí ó wà lórí oyè láti ọdún 1898 títí di ọdún 1920, Ó tún jẹ́ arákùnrin Ọba Gbádébọ̀ ll.[1]
Gbádébọ̀ lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ giga Baptist Boys ní Abẹ́òkuta àti ile iwe Grammar Ibadan tí ó wà ní ìlú Ìbàdàn. Ó tún tẹ̀ siwaju láti lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì Ibadan ní ọdún 1965, níbití ó ti gba oyè àkọ́kọ́ ninu ìmọ̀ Arts ní ọdún 1969.[2] Ó darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ ológun ní ọdún 1969. Ó sì lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ àwọn ológun ti Command and Staff College tí ó wà ní Jaji láti oṣù kẹsan ọdún 1978 títí di oṣù kẹjọ ọdún 1979. Níkẹ̀hìn, Ó di ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ àgbà sí ọ̀gágun Tunde Idiagbon, ẹnití ó jẹ́ olórí òṣìṣẹ́ ní olú ilé iṣẹ́ ti Baraki ologun, láti oṣù kíní ọdún 1984 títí di oṣú kẹsan ọdún 1985. Ó fẹ̀hìntì nínú iṣẹ́ ológun gẹ́gẹ́ bii Kononeli.[3]
Ìdìbò
àtúnṣeÌdìbò yan Gbádébọ̀ gẹ́gẹ́ bi Aláké ní oṣù kẹjọ ọdún 2005 gba oṣù mẹ́fà gbakó nítorí àìní ìdánilójú lori tani yíò rọ́pò Aláké ti tẹ́lẹ̀, Ọba Oyebade Lipede, tí ó wàjà ní ọjọ́ kẹta oṣù kejì ọdún 2005[4]. Gbádébọ̀ ní ìbò mẹ́ẹ̀dógún nínú àwọn ìbò mẹ́tàlélógún látàrí ètò ìdìbò yàn tí àwọn afọbajẹ ti ìlú Ẹ̀gbá gbé kalẹ̀, níbití ó ti borí àwọn mẹjọ tí wọn n ba díje, èyí tí Adeleke àbúrò rẹ jẹ́ ọ̀kan lára wọn.[5]
Àríyànjiyàn
àtúnṣeNí oṣù kẹrin ọdún 2010, wọ́n gbé àríyànjiyàn laarin Gbádébọ̀ àti Olú ti Ìgbẹ̀hìn , Ọba Festus Oluwọle Makinde lọ sí ilé ẹjọ́ gíga ti Ìpínlẹ̀ Ògùn, ẹ̀ka ìdájọ́ ti Abẹ́òkuta, Ìpínlẹ̀ Ògùn, Nàìjíríà. Olú ti Ìgbèyìn n sọ nípa ìgbìnyànjú Aláké láti yí oyè oun padà láti Olú ti Ìgbèyìn sí Olú ti Mòwé. Ó ní àyípadà yí yíò kó ipa tí ó lòdì sí ètọ́ òun láti lo àwọn ààmì Ìbílẹ̀ kan lára wọn ni ọ̀pá àse ti Ìgbèhìn.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ https://www.thepointng.com/oba-adedotun-aremu-gbadebo-the-alakes-75-years-story/
- ↑ Moses, Peter (2018-09-23). "Glamour as Alake of Egbaland marks 75th birthday – Daily Trust". Daily Trust. Archived from the original on 2020-01-27. Retrieved 2020-01-27.
- ↑ "Oando chair, Company Secretary, GM Operations receives prestigious recognitions". Premium Times Nigeria. 2019-11-01. Retrieved 2020-01-27.
- ↑ "Gbadebo emerges new Alake - Were yet to confirm any candidate Ogun govt". OnlineNigeria.com. Retrieved 2020-01-27. C1 control character in
|title=
at position 29 (help)[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́] - ↑ https://allafrica.com/stories/200508040831.html