Adegboyega Dosunmu Amororo II

Adegboyega Dosunmu Amororo II (CON) jẹ́ ọba ilẹ̀ Òwuipinlẹ Ogun, ní orílẹ̀-èdè Naijiria. À-pè-jálẹ̀ oyè rẹ̀ ni Olowu ti ilẹ Owu[1]. Ó gun orí oyè yìí nígbà tí Ọba Olawale Adisa Odeleye, Lagbedu I wàjà ní oṣù kẹfà ọdún 2003 ní ẹni ọdún márùn-dín-láàádọ́rin[2].

Adegboyega Dosunmu II
(CON)
Reign July 2005 – December 2021
Predecessor Oba Adisa Odeleye
Spouse Mrs. Adetoun Dosunmu (nee Sanni) widowed

Mrs. Olatunbosun Dosunmu, (nee Oyetayo)

House Palace of the Olowu of Owu Kingdom
Father Benjamin Okelana Dosunmu
Born Owu kingdom, Ogun State South-Western Nigeria
Died December 2021
Abeokuta, Ogun state

Ọba Adegboyega Dosunmu jẹ́ ọmọ bíbí inú Ọm'ọba Benjamin Okelana Dosunmu (ọ̀kan lára àwọn ọmọ oyè ní ìran olóògbé Ọba Adesunmbo Dosunmu, Amororo Kinni) ẹni tí ó jọba láàárín ọdún 1918 àti 1924) ní ilẹ̀ Òwu. Benjamin Okelana Dosunmu yìí ni ọmọ kẹta tí Ọba Adesunmbo Dosunmu, Amororo I bí.

Ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ìwé rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Ìjọ Onítẹ̀bọmi ní Òwu (Owu Baptist Day School), Abẹokuta ní ọdún 1941. Lẹ́yìn èyí, ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ girama ti àwọn Baptist Boys’ High School, níbẹ̀ ni ó sì ti gba ìwé ẹ̀rí oníwèé mẹ́wàá ní ọdún 1950. Ó tẹ̀síwájú nínú ìwé kíkà rẹ̀ nígbà tí ó lọ sí ìlú òyìnbó láti lọ gba imọ̀ lórí eré orí-ìtàgé àti bí a ti ń ṣe ètò orí ẹ̀rọ-amóhùn-máwòrán Drama and Television Production ní ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ (Hendon College of Technology) ní ìlú Ọba (London) ní ọdún 1963. Lẹ́yìn èyí, ó tún tẹ̀síwájú láti lọ sí ìlú Amẹrika láti lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀sìn ìgbàlódé ní ilé-ẹ̀kọ́ Ìjọ Onítẹ̀bọmi tí ó wà ní ìlú Tennessee (Landmark Baptist College Tennessee, USA) níbẹ̀ ni ó ti gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ̀ǹsì ní ọdún 1987.

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. https://www.vanguardngr.com/2012/10/odun-omo-olowu-yam-festival-in-another-style/
  2. https://www.vanguardngr.com/2013/10/odun-omo-olowu-celebrating-culture-best/