Adepeju Jaiyeoba

Adépéjú Ọpẹ́yẹmí Jayéoba tí wọ́n bí lóṣù kọkànlá ọdún 1983 jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ àti oníṣòwò àwùjọ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni olùdásílẹ̀ Brown Button Foundation àti Mother's Delivery Kits, èyí àjọ tí ó máa ń pèsè àwọn nǹkan ọmọ àti oògùn fún àwọn aláboyún ni owó pọ́kú ní Nigeria

Adepeju Opeyemi Jaiyeoba
Ọjọ́ìbíAdépéjú Opẹ́yẹ́mí Mábadéjẹ́
Ọjọ́ kẹfà oṣù November ọdún 1983
Ìlú Èkó, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigeria
Ẹ̀kọ́Yunifásítì Obafemi Awolowo
Iṣẹ́Olùṣòwò nǹkan àwùjọ, Agbẹjọ́rò àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ènìyàn
Gbajúmọ̀ fúnPípèsè àwọn nǹkan ọmọ àti oògùn fún àwọn aláboyún ni owó pọ́kú ní Nàìjíríà
Parent(s)Ọ̀gbẹ́ni Gbenga Mábadéjẹ́ àti Aya rẹ̀, Ìyáàfin Fèyíṣará Mábadéjẹ́
Notes
Àkálẹ̀ ohùn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lórí ìkànnì rédíò (Wiki féràn obìnrin)
Brown Button Foundation kit

Ìgbésí-ayéÀtúnṣe

Jayéọba jẹ́ àkàwé-gboyè amọ̀fin tí ó kàwé ní Obafemi Awolowo University Ilé-Ifè.[1][2] Bákan náà, ó kàwé ráńpẹ́ nínú ìmọ̀ olówò ní ilé-ìwé University of Texas ní Austin lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ní ilé-ìwé Coady International Institute, ní Canada.[2][3]

Jayéọba bẹ̀rẹ̀ àjọ ìrànlọ́wọ́ fún àwọn aláboyún láti dín ikú aláboyún àti màjèsín kù lẹ́yìn tí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ṣe aláìsí lásìkò ìrọbí rẹ̀ lọ́dún 2011, àti àwọn ikú aláboyún àti ọmọ mìíràn láwùjọ. Ó ṣàkíyèsí pé àwọn obìnrin tí iye wọn tó 145 ló kú nípò ìrọbí, tí àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ bí i 2300 náà máa ń kú kí wọ́n tó tó ọmọ ọdún márùn-ún ní Nigeria.[4]

Lọ́dún 2024,Ààrẹ àná Amẹ́ríkà Barack Obama sọ̀rọ̀ nípa Jayéọba níbi tí ó ti ń sọ̀rọ̀ níbi ìfọrọ̀wérọ̀ ni àkànṣe ètò kan nípa àwọn adarí àwọn ọ̀dọ́ ní ìlú Washington D.C.[5] and was also hosted at the White House in 2015.[2] Lọ́dún 2014, wón bẹ̀rẹ̀ sí ní pín àwọn nǹkan ìbímọ fún àwọn aboyún lẹ́yìn tí wọ́n rí àkóbá tí àwọn nǹkan gbàrọtùtù, tí wọn kò sè tàbí ṣé ìtọ́jú ààbò tó péye fún, pàápàá pàápàá jù lọ, abẹ tó ti dógùú tí wọn lò láti dáwọ̀ọ́ fún àwọn ọmọdé kóbá wọn nígbà ìbí. Lọ́dún 2015, wọn ti pín àwọn nǹkan ìbímọ tí ó ti tó ẹgbẹ̀rún-mẹ́jọ̀ (8000)[4] and by 2017, 300,000.[6]

Lọ́dún 2017, ó ọ nípa TEDx talk.[1]

Jayéọba tí sọ̀rọ̀ ni oríṣiríṣi àpérò lórílẹ̀ èdè wa àti ní òkè òkun, tí ó sìn ń ṣe móríyá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ káàkiri ilẹ̀ Afíríkà fún ìyípadà.

Àwọn Ìtọ́kasíÀtúnṣe

  1. 1.0 1.1 TEDx Talks (2017-06-30), How to reform the health care system | Adepeju Jaiyeoba | TEDxGbagada, retrieved 2018-05-09 
  2. 2.0 2.1 2.2 "Adepeju Jaiyeoba". Africa Shared Value Summit (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-03. 
  3. "From law to health: Adepeju Jaiyeoba’s entrepreneurship journey". Businessday NG (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-07-01. Retrieved 2020-05-03. 
  4. 4.0 4.1 Minter, Harriet (2015-03-27). "10 minutes with: Adepeju Jaiyeoba, maternity campaigner". the Guardian (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-05-09. 
  5. "Delivering Hope to Mothers | YALI". Young African Leaders Initiative Network (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-07-16. Retrieved 2020-05-03. 
  6. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named aw2017