Adolphe Muzito (ojoibi 1957[1] in Gungu, Igberiko Kwilu) ni oloselu ara Kongo OOT lowolowo to je Alakoso Agba Orile-ede Olominira Toseluarailu ile Kongo. Muzito, omo egbe oloselu Egbe Lumumbisti Piparapo (PALU), teletele ti je Alakoso Isuna labe Alakos Agba Antoine Gizenga lati 2007 de 2008.

Adolphe Muzito
Alakoso Agba OOT ile Kongo
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
10 Osu Kewa 2008
ÀàrẹJoseph Kabila
DeputyNzanga Mobutu
Emile Bongeli Yeikolo Yaato
Mutombo Bakafwa Nsenda
AsíwájúAntoine Gizenga
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí1957?
Ẹgbẹ́ olóṣèlúEgbe Lumumbisti Piparapo

Muzito, to wa lati Gungu, Igberiko Kwilu, je onimo oro-okowo.[1] Ninu ijoba to je yiyansipo ni ojo 5 Osu Keji 2007, Muzito je mimupo bi Alakoso Isuna.[2] Leyin ti Gizenga, to je olori PALU, kosesile bi Alakoso Agba ni 25 Osu Kesan 2008 fun idi to jemo ojo-ori ati ilera, Muzito je yiyansipo latowo Aare Joseph Kabila lati ropo Gizenga ni 10 Osu Kewa 2008.[1]

Ijoba Muzito bere ise ni ojo 26 Osu Kewa 2008. Yato si Muzito funra re, ijoba re ni eniyan 53: awon igbakeji alakoso agba meta, awon alakoso 36, ati awon igbakeji alakoso 14.[3] Opo awon eniyan inu ijoba yi wa lati Egbe Araalu fun Itunleko ati Oseluarailu, beesini Kabila pe bi "egbe ti ise won je lati se abo ati itunleko".[4]