Afi River Forest Reserve

Afi River Forest Reserve jẹ́ igbó tí ó wà lábẹ́ àbò ìjọba ìpínlẹ̀ Cross Rivers ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Igbó yí fẹ̀ nìwọn bàtà ọ̀ọ́dúnrúnléméjìlá 312 square kilometres (120 sq mi). Igbó yí ni ó jẹ́ igbó tí ó ṣẹ́kù nínú àwọn igbó tí ìjọba ìpínlẹ̀ Cross Rivers ń dáàbò bò yàtọ̀ sí Cross River National Park. Igbó yí wà láàrín Afi Mountain Wildlife Sanctuary àti Mbe Mountains Community Forest, tí méjèjì sì jẹ́ ilé ati ibùgbé fún àwọn ìnàkí ní ìpínlẹ̀ náà. Gẹ́gẹ́ bí abọ̀ ojú ìwòye kan ní ọdún 2008, wọ́n sọ wípé àwọn ìnakí tí wọ́n ń gbé nínú àwọn igbó wọ̀nyí ti ń ní ìpènijà láti ọmọ ọmọnìyàn látàrí bí àwọn ènìyàn ṣe ń lọ fi inú àwọn igbó wọ̀nyí dá oko tí wọ́n sì tú n ń dẹdẹ àwọn ẹranko wọ̀nyí.[1]

Púpọ̀ àwọn ènìyàn ní orílẹ̀-èdè yí ati lókè òkun ni ni wọ́n ti ń ṣí'jú sí àwọn igbó tí wọ́n jẹ́ ibùgbé àwọn ẹranko lóríṣirí wọ̀nyí látàrí iṣẹ́ àkànṣe títì ọ̀nà márosẹ̀ ńlá tí ìjọba gbé gba ẹ̀gbẹ́ Afi Mountain Wildlife Sanctuary. Èyí sì mú kí àwọn ẹranko bí erin, ìnàkí, ọ̀nì, ọ̀yà àti àwọn ẹranko míràn ó fẹ́ wà nínú ewu tó lágbára nítorí ìdàgììrì ẹsẹ̀ ọmọ ènìyàn.[2]

Àwọn itọ́kasí àtúnṣe

  1. "Important Forest Corridor for Gorillas under Threat". Gorilla Journal 37. December 2008. Archived from the original on 2011-06-15. Retrieved 2010-10-21.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Nigerian superhighway project draws international attention over threats to local communities and wildlife". Mongabay Environmental News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-11-02. Retrieved 2020-08-18. 

Ẹ kà siwájú si àtúnṣe