Ahmad Ali Saharanpuri
Aḥmad Ali Saharānpuri (ọdún 1810 sí ọjọ́ ẹẹ́ta-dín-lógún oṣù kẹrin ọdún 1880) jẹ́ ọ̀mọ̀wé hadith ní ilẹ̀ India tí ó kó ipa pàtàkì nínú títè jáde lítíréṣọ̀ hadīth ní India. Ó wà láàrin àwọn olùkọ́ àkọ́kọ́ tí Mazahir Uloom, àti pé ìgbàgbogbo ni a kàá bí olùdásílẹ̀ fún àwọn ìlọwọ́sí rẹ̀ sí ìdàgbàsókè ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́mínárì hadith. Àwọn ọmọ ilé-ìwé rẹ̀ ni Muhammad Qasim Nanautawi àti Shibli Nomani.
Ìgbésí Ayé
àtúnṣeWọ́n bí Aḥmad Ali ní ọdún 1810 ní Saharanpur.[1]. Ó gba Al-Qur’an sórí ní Meerut ó sì kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé àkọ́kọ́ ní èdè Lárúbáwá pẹ̀lú Sa’ādat Ali Faqīh ní Saharanpur..[1] Ó lọ sí Delhi níbi tí ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ lábẹ́ àmojútó Mamluk Ali Nanautawi [2]. Ó kẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ka Sahih Bukhari pẹ̀lú Wajīhuddīn Siddīqi, ó sì parí ẹ̀kọ́ nípa hadith pẹ̀lú Shah Muḥammad Ishāq Dehlawi ní ọdún 1261 hijra ní Mekka.
Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ẹ̀kọ́ India, Syed Ahmad Khan; Ahmad Ali ka gbogbo wọn ni wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa gbogbo ìwé hadith pẹ̀lú Sihah Sitta láti ìbẹ̀rẹ̀ sí ìparí pẹ̀lú Muḥammad Isḥāq. Abu Salman Shahjahanpuri síbẹ̀síbẹ̀ tọ́ka sí wípé ọ̀rọ̀ Syed Aḥmad Khan wípé Aḥmad kọ́ ẹ̀kọ́ Saḥiḥ Bukhāri pẹ̀lú Muḥammad Isḥāq kò yẹ kí wọ́n gbà. Syed Mehboob Rizwi ti gba Aḥmad Ali lọ́wọ́ pé ó kẹ́kọ̀ọ́ apá pàtàkì nínú Saḥiḥ Bukhāri pẹ̀lú Wajīhuddīn Siddīqi ní Saharanpur, ó sì tún kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pẹ̀lú Muḥammad Isḥāq ní Mekka.[3]
Aḥmad Ali padà sí India ní ọdún 1845 ó sì bẹ̀rẹ̀ "Aḥmadi Press" ní Delhi láti ṣe àtẹ̀jáde àwọn ìwé hadith.[3] Ó ṣe àtẹ̀jáde àwọn ẹ̀yà tí a dàkọ ti Sihah Sitta àti àwọn ìwé àfọwọ́kọ́ hadith tí a dàkọ ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀.[4] Ó kọ́ ojú ìwé márùndínlọ́gbọ̀n ti Sahiḥ Bukhāri.[4] Ilé-iṣẹ́ títẹ̀wẹ́ rẹ̀ jìyà pípàdánù nígbà tí ìṣọ̀tẹ̀ Indian ti 1857; ó sì gbé e sí Meerut.[5] Ó lo ọdún mẹwàá ní Kolkata tí ó ń fún àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ní Hafiz Jamaluddin Masjid.[1] Ó padà sí Saharanpur ní ọdún 1291 AH, níbi tí ó ti kọ ẹ̀kọ́ ní Mazahir Uloom.[6]
Wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ìsìn lẹ́yìn ikú Sa'ādat Ali Faqīh; ó ṣiṣẹ́ olórí ilé-ìwé ní Mazhar Nanautawi ní ọdún 1294 AH.[6] Nígbà gbogbo wọ́n jẹ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí olùdásílẹ̀ Mazahir Uloom fún ipa pàtàkì rẹ̀ nínú ìdàgbàsókè ilé-ẹ̀kọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́.[7] Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pẹ̀lú Muhammad Qasim Nanautawi, Muhammad Yaqub Nanautawi, Ahmad Hasan Amrohi, Ahsan Nanautawi àti Shibli Nomani.[8]
Aḥmad Ali kú ní ọjọ́ kẹ́ta-dín-lógún oṣù kẹrin ọdún 1880 ní Saharanpur.[9][4] Ikú rẹ̀ jẹ́ ìtùnú nípasẹ̀ Syed Ahmad Khan.[9]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 Shahid Saharanpuri. Ulama e Mazahir Uloom aur unki Ilmi wa tasnīfi khidmāt. 1 (2005 ed.). p. 83.
- ↑ Syed Mehboob Rizwi. Deobandi, Nawaz. ed. Sawaneh Ulama-e-Deoband. 1. p. 243.
- ↑ 3.0 3.1 Syed Mehboob Rizwi. Deobandi, Nawaz. ed. Sawaneh Ulama-e-Deoband. 1. p. 244.
- ↑ 4.0 4.1 4.2 Asir Adrawi (in Urdu). Tazkirah Mashāhīr-e-Hind: Karwān-e-Rafta (2 April 2016 ed.). Deoband: Darul Muallifeen. pp. 22–23.
- ↑ Syed Mehboob Rizwi. Deobandi, Nawaz. ed. Sawaneh Ulama-e-Deoband. 1. p. 245.
- ↑ 6.0 6.1 Shahid Saharanpuri. Ulama e Mazahir Uloom aur unki Ilmi wa tasnīfi khidmāt. 1 (2005 ed.). p. 84.
- ↑ Shahid Saharanpuri. "Bāniyān-e-Madrasa (The founders of the madrasa)". Ulama e Mazahir Uloom aur unki Ilmi wa tasnīfi khidmāt. 1 (2005 ed.). pp. 70–108.
- ↑ Khan, Syed Aḥmad. Shahjahānpuri, Abu Salmān. ed. Tadhkira Khānwāda-e-Waliullāhi. p. 295.
- ↑ 9.0 9.1 Syed Mehboob Rizwi. Deobandi, Nawaz. ed. Sawaneh Ulama-e-Deoband. 1. p. 251.
- Muntasir Zaman. Hadith Scholarship in the Indian Subcontinent: Aḥmad Alī Sahāranpūrī and the Canonical Hadith Literature. Leicester: Qurtuba Books. ISBN 978-1-9160232-4-6.
- Shahid Saharanpuri (in ur). Ulama e Mazahir Uloom aur unki Ilmi wa tasnīfi khidmāt. 1 (2005 ed.). Saharanpur: Maktaba Yādgār-e-Shaykh. pp. 83-95.
- Syed Mehboob Rizwi. "Hadhrat Mawlāna Aḥmad Ali Muhaddith Sahāranpuri". In Deobandi, Nawaz (in Urdu). Sawaneh Ulama-e-Deoband. 1 (January 2000 ed.). Deoband: Nawaz Publications. pp. 243–255.
- Khan, Syed Aḥmad. "Janāb Mawlvi Aḥmad Ali Saheb Marhūm". In Shahjahānpuri, Abu Salmān (in ur). Tadhkira Khānwāda-e-Waliullāhi. Jamshoro: University of Sindh. pp. 289–296.