Aisha Yesufu

Ajafeto omo ènìyàn ni orílè-èdè Nàìjirià

Aisha Yusufu (tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kejìlá ọdún 1973 ní Ipinle Kano) jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ ọ́ ọmọ ènìyàn, ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti alábàṣiṣẹ́pọ̀ ẹgbẹ́ tí ó ń polongo fún ìdápadà àwọn ọmọ obìnrin wa (Bring Back Our Girls Movement), èyí tí í ṣe ẹgbẹ́ alágbàwí tí ó ń pe Ìjọba sí àkíyèsi lórí í àwọn ọmọbìnrin tí ó lé ní igba láti ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdìrì ti Chibok ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí àwọn ẹgbẹ́ oníjàgídíjàgan Boko Haram jí gbé ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹrin ọdún 2014. Yesufu wà lára àwọn obìnrin tí wọ́n ń fi ẹ̀rónú hàn ní ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, èyí tí ó wà ní Abuja, Olú-ìlú Nàìjíríà, ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹrin, ọdún 2014.[1][2]

Aisha Yesufu
Aisha Yesufu leading the EndSARS Protest in Abuja, on October 10, 2020.
Ọjọ́ìbíAisha Yesufu
12 Oṣù Kejìlá 1973 (1973-12-12) (ọmọ ọdún 51)
Kano State
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iléẹ̀kọ́ gígaBayero University Kano
Iṣẹ́Socio-political activist, microbiologist, businesswoman
Gbajúmọ̀ fúnBring Back Our Girls, End SARS
Àwọn ọmọ2

Yesufu tún wà lára àwọn tí ó léwájú nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń pè fún fífòpin sí SARS (END SARS), èyí tí ó ń pe àkíyèsi si àṣejù tí ẹ̀yà kan nínú iṣé ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n ń pè ní Special Anti Robery Squad (SARS) ń ṣe. Yesufu sọ wípé òun kò ní fi ìjà kíkéde ìfòpin sí àwọn ọlọ́pàá SARS ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sílẹ̀ fún àwọn ọmọ òun.[3]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ

àtúnṣe

Ipinle Kano, níbi tí wọ́n bí Yesufu sí ná à ni wọ́n tí tọ ọ dàgbà. Yesufu ní ìrírí lórí i ìṣòro tí ó wà nínú n kí ènìyàn jẹ́ ọmọbìnrin ní àyíká tí kò fibẹ́rẹ̀ sí ìmọ̀ ẹ̀kọ́.[4] Nínú ọ̀rọ̀ rẹ tí ó sọ, ó wípé "Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mọ́kànlá, ń kò ní àwọn ọmọbìnrin kankan ní ọ̀rẹ́ nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n ti gbé níyàwó, ṣùgbọ́n nítorí mo fẹ́ ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ni mo ṣe kúrò ní agbègbè tí kò lajú."[5][6] Aisha Yusufu tún sọ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ọmọ tí àwọn ẹlẹgbẹ́ òun bí ti fẹ́rẹ̀ tún má a bí ọmọ nígbàtí òun ṣe ìgbéyàwó ní ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún.[7]

Ìgbésí ayé rẹ

àtúnṣe

Yesufu àti ọkọ rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Aliu, ẹni tí ó ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú rẹ ní ọdún 1966,[8] ni wọ́n bí ọmọ méjì tí orúkọ wọn ń jẹ́ Amir àti Aliyah.

Awọn itọkasi

àtúnṣe
  1. "Aisha Yesufu, the hijab-wearing revolutionary". TheCable. 2020-10-11. Retrieved 2020-11-03. 
  2. Africa, Information Guide (2020-09-11). "Aisha Yesufu Biography, Age, Early Life, Family, Education, Career And Net Worth ~ Information Guide Africa". Information Guide Africa. Retrieved 2020-11-03. 
  3. Silas, Don (2020-10-09). "End SARS: 'I’m ready to sacrifice my life for my children to live' – Aisha Yesufu". Daily Post Nigeria. Retrieved 2020-11-03. 
  4. "Aisha Yesufu: The Voice Of Humanity". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2019-08-25. Archived from the original on 2020-10-21. Retrieved 2020-11-03. 
  5. "Full biography of Nigerian political activist, Aisha Yesufu". DNB Stories. 2020-09-05. Retrieved 2020-11-03. 
  6. "Aisha Yesufu Biography, Age, Early Life, Family, Education, Career And Net Worth ~ Information Guide Africa". Information Guide Africa. 2020-09-11. Retrieved 2020-11-03. 
  7. punchng (2018-04-21). "Most of my mates were almost grandmothers when I married at 24 – Aisha Yesufu – Punch Newspapers". punchng.com. Retrieved 2020-11-03. 
  8. The Blogger Scientist (2020-10-12). "Aisha Yesufu Biography, Education, Wikipedia, Real Age, Net Worth, Contact". Top Leaks and Review Blog. Archived from the original on 2020-10-31. Retrieved 2020-11-03.