Akọ ibà jẹ aarun àkoràn lati ara ẹ̀fọn tí àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko míìràn tí kòkòrò ńfà protozoans (irúfẹ́ oní sẹ́ẹ̀lì kan kòkòrò kékèèké) ti irúfẹ́ kòkòrò àṣòkunfà.[1] Akọ ibà maa ń fa àwọn ààmì èyí tí ó wà lára akọ ibà, ìgara, bíbì àti ẹ̀fọ́rí. Ní àwọn ìpò líle ó lè fa ara pípọ́n, ìmú lójìjì, dákú tàbí ikú.[2] Àwọn ààmì wọ̀nyíi maa ń sábà bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́wà tàbí mẹ́ẹdógún lẹ́hìn ìgéjẹ. Ní àwọn tí a kò tọ́jú dáradára ààrùn tún lè jẹyọ ní àwọn oṣù mélòó bóyá.[1] Lára àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ àkóràn, àtún-kóràn maa ń mú àwọn ààmì tí kò le jáde. Ti díẹ̀ ìkọ́jùjàsí pòorá ní àwọn oṣù sí ọdún bí kò básí pé ibà kọluni.[2]

Akọ ibà
Akọ ibàKòkòrò aṣòkùnfà láti inú itọ́ òbí ẹ̀fọn tí o ń rìn kiri láyiká ẹ̀fọn
Akọ ibàKòkòrò aṣòkùnfà láti inú itọ́ òbí ẹ̀fọn tí o ń rìn kiri láyiká ẹ̀fọn
Kòkòrò aṣòkùnfà láti inú itọ́ òbí ẹ̀fọn tí o ń rìn kiri láyiká ẹ̀fọn
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10B50.-B54. B50.-B54.
ICD/CIM-9084 084
OMIM248310
DiseasesDB7728
MedlinePlus000621

Níwọ́pọ̀, ààrùn yii maa ń múni nípa ìgéjẹ lọ́wọ́ aabo ẹ̀fọn tí ó ní àkóràn Anọfẹ́lísì. Ìgéjẹ yii maa ń mú àwọn kòkòrò àkóràn láti itọ́ ẹ̀fọn sínu ẹ̀jẹ̀ènìyàn.[1] Kòkòrò àkóràn yíì yóò rìn kiri lọ inú ẹ̀dọ̀ níbi tí wọn a ti dàgbà láti pọ̀si. Ẹ̀yà máàrùn Kòkòrò àṣòkunfà lè ranni kí ènìyàn tán kiri.[2] Ọ̀pọ̀ ikú ni o ń wáyé nípa P. falciparum pẹ̀lú P. vivax, P. ovale, àti P. malariae maa ń sábà fa ibà tí kò lera.[1][2] Àwọn ẹ̀yà P. knowlesi kìí sábà fa ààrùn lára àwọn ènìyàn.[1] A sábà maa ń ṣàwarí ibà nípa àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ nípa lílo ohun elò awo kòkòrò fíìmù ẹ̀jẹ̀, tàbí pẹ̀lú ìdálórí ántígínì- àyẹ̀wò ìṣawarí kíákíá.[2] Àwọn ìlànà lílo polymerase ìtàgìjí àṣokunfà láti ṣàwarí kòkòrò náà DNA ti di àgbékalẹ̀, ṣùgbọ́n a kí sábà lò ní àwọn agbègbè tí ibà ti wọ́pọ̀ nítorí ọ̀wọ́n àti ipá gbòòrò líle wọn.[3]

Ìjàmbá tí ààrùn ni a lè dínkù nípa dídẹ̀kun ìgéjẹ ẹ̀fọn nípa lílo àwọ̀n apẹ̀fọn àti òògùn alé kòkòrò, tàbí ìlànà ìṣàkóso ẹ̀fọn bíi ìfúnka òògùn kòkòrò àti ìlànà fún adágún omi.[2] Ọ̀pọ̀ àwọn oogùn ni ó wà ìdẹ́kun ibà lára àwọn arinrin-àjò sí ibi tí ààrùn wọ́pọ̀. Lílo oogùn lẹ́kọ́ọ̀kan sulfadoxine/pyrimethamine ni a gbà nímọ̀ràn ọmọwọ́ ati ṣaaju ìbẹ̀rẹ̀ oṣù mẹ́ta oyún ti oyún ní àwọn àgbègbè tí ìbà wọ́pọ̀ sí. Bí ìlò bá tìlẹ̀ wà, kòsí ojúlówó òògùn, bí-o-tìlẹ̀-jẹ́pé èròngbà wà àti ṣe ọ̀kan ńlọ lọ́wọ́.[1] ìgbàníyànjú ìtọjú ibà ni apàpọ̀ òògùn aṣòdì sí ibà tí ó ní artemisinin.[1][2] òògùn ìkejì léjẹ̀ bóyá mefloquine, lumefantrine, tàbí sulfadoxine/pyrimethamine.[4] Quinine pẹ̀lú doxycycline alèló bí kòbásí artemisinin.[4] A gbàníyànjú pé ní agbègbè tí ààrùn náà ti wọ́pọ̀, a gbọ́dọ̀ ṣàwarí ibà kí a tó bẹ̀rẹ̀ ìtọjú nítorí ìpọsi ìlòdìsí òògùn. Ìlòdìsi ti gboorò sí ọ̀pọ̀ oogùn aṣòdìsí ibà; fún àpẹẹrẹ, -aṣodisi chloroquineP. falciparum titàn káákìri agbègbè ibà, àti aṣòdìsí artemisinin ti di ìṣòro ní àwọn apá ibìkan ní Gúúsù-ilà-oorùn Aṣia.[1]

Ààrùn náà titàn kiri ní agbègbè orùn àti agbègbè orùn díẹ̀ àwọn ẹkùn tí ó wà ní àyiká ti arín ilà aayé.[2] Èyí pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ti Gúúsù Áfíríkà, Asia, àti Latin Amẹ́ríkà. Àjọ Ìlera Àgbayé lápapọ̀ pé ní 2012, àwọn ìṣẹlẹ̀ 207 mílíónù ibà ni ó wáyé. Ní ọdún yì, ààrùn yí ti pa ó kééré láàrin 473,000 àti 789,000 ènìyàn, ọ̀pọ̀ tí ó jẹ́ àwọn ọmọdé ní Áfíríkà.[1] Ìbà ń wáyé níbití oṣì wà ó sì ní ipa odì lórí ìdàgbà ọ̀rọ̀ ajé.[5][6] Ní Áfíríkà a ti wò lápapọ̀ pé ó fa ìpàdánù $12 bílíọ́nù owó Amẹ́ríkà ní ọdún kan èyí tí ó wáyé lára ìgbówó lórí ìtọjú-ìlera, àínífẹ̀ sí iṣẹ́ ṣíṣe àti ìpalára arìn-ajò.[7]

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 1.6 1.7 1.8 "Malaria Fact sheet N°94". WHO. March 2014. Retrieved 28 August 2014. 
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 2.5 2.6 2.7 Caraballo, Hector (May 2014). "Emergency Department Management Of Mosquito-Borne Illness: Malaria, Dengue, And West Nile Virus". Emergency Medicine Practice 16 (5). http://www.ebmedicine.net/topics.php?paction=showTopic&topic_id=405. 
  3. Nadjm B, Behrens RH (2012). "Malaria: An update for physicians". Infectious Disease Clinics of North America 26 (2): 243–59. doi:10.1016/j.idc.2012.03.010. PMID 22632637. 
  4. 4.0 4.1 Organization, World Health (2010). Guidelines for the treatment of malaria (2nd ed. ed.). Geneva: World Health Organization. p. ix. ISBN 9789241547925. 
  5. Gollin D, Zimmermann C (August 2007) (PDF). Malaria: Disease Impacts and Long-Run Income Differences. Institute for the Study of Labor. http://ftp.iza.org/dp2997.pdf. 
  6. Worrall E, Basu S, Hanson K (2005). "Is malaria a disease of poverty? A review of the literature". Tropical Health and Medicine 10 (10): 1047–59. doi:10.1111/j.1365-3156.2005.01476.x. PMID 16185240.   
  7. Greenwood BM, Bojang K, Whitty CJ, Targett GA (2005). "Malaria". Lancet 365 (9469): 1487–98. doi:10.1016/S0140-6736(05)66420-3. PMID 15850634.