Ikú
Ikú jẹ́ ìdáwọ́ iṣẹ́ dúró gbogbo éyà ara tí wọ́n ń ṣisẹ́ nínú àgọ́ ara tí wọ́n fi ń pe ènìyàn tàbí ẹranko ní abẹ̀mí [1] Lẹ́yìn tí ẹ̀dá kan bá ti kú ni àwọn ẹ̀yà ara t'ókù yóò wá bẹ̀rẹ̀ sí ń jẹrà lẹ́yìn wákàtí díẹ̀.[2] Ikú tún jẹ́ ohun kan tí kò ṣe é yẹra fún; tí yoo sì ṣẹlẹ̀ sí gbogbo abẹ̀mí. Àwọn onímọ̀ sọ wípé iye ènìyàn tí wọ́n ń kú ní ọdọdún láti ìbẹ̀rẹ̀ 21st century ni wọ́n ń tó mẹ́rìndínlọ́gọ́ta mílíọ́nù, ohun tí ó sì ń ṣe sábàbí ikú wọn náà ni àrùn ọkàn tí ó ń jẹyọ látara àìṣe déédé ọ̀pá iṣan agbẹ́jẹ̀rinra tí ó sì ń ṣe ṣakóbá fún lílù-kìkì ọkàn. [3] Nígbà tí yóò fi di ọdún 2002, iye àwọn ènìyàn tíọ́n ti kú ti tó bílíọ́nù.[4] Orísiríṣi àwọn elédè àti ẹ̀yà ènìyàn láyé ni wọ́n ní ìgbàgbọ́ nípa ayé lẹ́yìn ikú, tí wọn yóò sì gba ìdájọ́ ẹ̀san ire tabi ibi lórí iṣẹ́ ọwọ́ wọn tí wọ́n ti gbé ilé ayé ṣe. Onírúurú ọ̀nà ni àwọn ènìyàn tí gbé kalẹ̀ láti ma fi ṣe ẹ̀yẹ fún àwọn òkú wọn, lára rẹ̀ ni ìsìnkú, òkú jíjó tàbí súnsun, òkú síso rọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[5]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Àdàkọ:Dictionary.com
- ↑ Hayman, Jarvis; Marc Oxenham (2016). Human body decomposition. Amsterdam: Elsevier. ISBN 978-0-12-803713-3. OCLC 945734521.
- ↑ Richtie, Hannah; Spooner, Fiona; Roser, Max (February 2018). "Causes of death". Our World in Data. https://ourworldindata.org/causes-of-death#:~:text=Cardiovascular%20diseases%20are%20the%20leading,second%20biggest%20cause%20are%20cancers.. Retrieved February 14, 2023.
- ↑ Routley, Nick (2022-03-25). "How Many Humans Have Ever Lived?". Visual Capitalist. Archived from the original on 2022-03-28. Retrieved 2023-10-03. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "GCSE Religious Studies Revision". BBC Bitesize. 2018-11-19. Retrieved 2024-04-23.