Àjàgbó fìgbà kan jẹ́ Aláàfin Ìlú Ọ̀yọ́, tí ìjọba rẹ̀ wáyé ní sẹ́ńtúrì kẹtàdínlógún.[1]

Ajagbo
Iṣẹ́Alaafin

Ajagbo jẹ oyè yìí, lẹ́yìn tí bàbá-bàbá rẹ̀ wàjà, ìyẹn Aláàfin Ọbalokùn.[1] Ìtàn àtẹnudẹ́nu fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó jọba fún ogóje ọdún.[2] Àti pé ó jẹ́ ìbejì.[2]

Ó gbajúmọ̀ fún oyè Ààrẹ Ọ̀nà Kakanfò tó ṣẹ̀dá (èyí tí a lè fi wé oyè ológuna) ní ìlú Ọ̀yọ́. Yàtọ̀ sí èyí, àwọn ìgbèríko tó yí Ọ̀yọ́ ká mọ̀ ọ́n fún ìwà ogun rẹ̀, nítorí ó rán àwọn jagunjagun láti kọjú ogun sí àwọn ará Pópó, Ilé Ọlọ́pàá àti ìlú ìyá rẹ̀, ìyẹn Ikereku-were.

Ọmọ rẹ̀ Aláàfin Ọdarawu ló jẹ oyè Aláàfin lẹ́yìn tó wàjà.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 Law, R. C. C. (1971). "The constitutional troubles of Ọyọ in the eighteenth century". The Journal of African History 12 (1): 25–44. doi:10.1017/s0021853700000050. ISSN 0021-8537. 
  2. 2.0 2.1 Johnson, Samuel (August 2011). The history of the Yorubas : from the earliest times to the beginning of the British Protectorate. ISBN 0948390891. OCLC 989713421.