Aláàfin Àjàká
Aláàfin Àjàká ni ó jẹ́ Aláàfin ìlú Ọ̀yọ́ tí ò jẹ̀ Alààfin lẹ́ẹ̀mejì nígbà ayé rẹ̀. Bàbá rẹ̀ ni Ọ̀rányàn tàbí Ọ̀rànmíyàn, nígbà ti àbúrò rẹ̀ jẹ́ Ṣàngó.
Ìgbé ayé rẹ̀
àtúnṣeAláàfin Àjàká jẹ́ ènìyàn tí kò lágbaja bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé oríṣirìṣi ìpènijá àti ogun ni ó ń kojú nígbà tí ò wà lórí oyè, ìwà jẹ́ẹ́jẹ́ rẹ̀ yí ni àwọn ènìyan rí gẹ́gẹ́ bí alèébù rẹ. Ohun tí ò fàá ni wípé Àjàká ma ń sábà gbájúmọ́ ètò ìṣèlú lààfin tí kìí sì fi bẹ́ẹ̀ ráyè ọ̀rọ̀ ogun tí ó sì dá gbogbo ọ̀rọ̀ ogun yìí dá àwọn jagunjagun rẹ̀ nìkan. Àìkọbiara sí ọ̀rọ̀ ogun ni ó fàá tí púpọ̀ nínú àwọn ìjòyè rẹ̀ fi rìi gẹ́gẹ́ bí ojo tí wọ́n sì yọọ́ nípò gẹ́gẹ́ bí ọba tí wọ́n sì fi àbúrò rẹ̀ Ṣàngó rọ́pò rẹ̀. Wọ́n fi Aláàfin Àjàká jẹ ọba padà lẹ́yìn ikú Aláàfin Ṣàngó. Lẹ́yìn tí Àjàká di Aláàfin lẹ́ẹ̀kejì yí, ó wà di Aláàfin jagunjagun dípò Aláàfin jẹ́ẹ́jẹ́ tì wọ́n ti mọ̀ọ́ sí nìgbàkanrí gẹ́gẹ́ bí ̀abúrò tẹ̀ Ṣàngó tó papòdà ti rí. Ẹni tó jẹ́ Ọṣọ̀run nígbà ìjọba Àjàká lẹ́ẹ̀kejì ni Baṣọ̀run Salekoudi, lásìkò yí náà ni wọ́n gbé ìlù ògìdìgbó wọ ìlú Ọ̀yọ́. Ìlù yí ni wọ́n sì ma ń lù níbi ayẹyẹ tí Aláàfin àti Baṣọ̀run bá gbé wàpọ̀ títì́ di òní.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- Johnson, Samuel. The history of the Yorubas: From the earliest times to the beginning of the British protectorate. London, 1921.