Alphonse Menyo, jẹ́ òṣèrékùnrin ti orílẹ̀-èdè Ghana. Ó gbajúmọ̀ fún ẹ̀dá-ìtàn tó ṣe nínú àwọn fíìmù bí i Freetown àti Gold Coast Lounge.[1]

Alphonse Menyo
Ọjọ́ìbíAlphonse Menyo
Ghana
Orílẹ̀-èdèGhanaian
Ẹ̀kọ́National Film and Television Institute (NAFTI)
Iṣẹ́Actor, director
Ìgbà iṣẹ́2009–present
Parents
  • Bernard Menyo (father)
  • Eugenia Menyo (mother)
AwardsGhana Movie Awards

Ìgbésí ayé ara ẹni

àtúnṣe

Ìlú Accra ni wọ́n bi sí, ní orílẹ̀-èdè Ghana. Bàbá rẹ̀, Bernard Menyo, wá láti apá Ìlà-oòrùn ìlẹ̀ Africa. Ó fìgbà kan jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ National Film and Television Institute (NAFTI). Bernard gba àmì ẹ̀yẹ ní Panafrican Film and Television Festival of Ouagadougou (FESPACO) fún fíìmù Whose fault. Ìyá Menyo, Eugenia, wá láti Ghana, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú NGO kan.

Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Menyo lọ sí Ghallywood Academy of Film Acting ní Accra, Ghana láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa sinimá àti erẹ́-oníṣe. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ní ọdún 2009, pẹ̀lú eré orí-ìtàgé kan. Ní ọdún 2015, ó kópa nínú fíìmù sinimá fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú fíìmù Freetown èyí Garrett Batty darí.[2] Wọ́n ṣàfihàn fíìmù náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayẹyẹ fíìmù èyí tí ó sì mú kí wọ́n yan fíìmù náà fún àmì-ẹ̀yẹ ní Ghana Movie Awards.[3]

Utopia ní fíìmù àkọ́kọ́ tí Menyo máa kọ́kọ́ darí. Wọ́n yan fíìmù náà fún àmì-ẹ̀yẹ ní Ghana Movie Awards. Ní ọdún 2017, Utopia di fíìmù ilẹ̀ Ghana nìkan tí wọ́n ṣàfihàn ní Helsinki African Film Festival (HAFF). Ní ọdún 2017, ó kópa nínú fíìmù ajẹmọ́fẹ̀ẹ́ tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Black Rose, èyí tí Pascal Aka darí. Ní ọdún 2018, ó darapọ̀ mọ́ fíìmù mìíràn tí Pascal Aka ṣe, tí àkọ́leh rẹ̀ jẹ́ Corruption. Menyo gba àmì-ẹ̀yẹ ti Yaa Asantewaa ní Black Star International Film Festival fún ìkópa rẹ̀ ó sì tún gba àmì-ẹ̀yẹ fún òṣèrẹ́kùnrin tó dára jù lọ ní Fickin International Film Festival ní Kinshasa, Congo.[4]

Wọ́n yàn án láti ṣojú Ghana ní 2019 World Youth Theater ní Egypt. Ní ọdún kan náà, ó ṣe ẹ̀dá-ìtàn 'Daniel' nínú fíìmù Gold Coast Lounge. Fún ẹ̀dá-ìtàn yìí, ó gba àmì-ẹ̀yẹ fún òṣèrékùnrin tó dára jù lọ ní 2019 Ghana Movie Awards.

Àwọn fíìmù rẹ

àtúnṣe
Year Film Role Genre Ref.
2015 Freetown Meyers Film
2017 Black Rose Daniel Short film
2020 Gold Coast Lounge Daniel Film

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Alphonse Menyo, Ghana's reigning male lead actor". ameyawdebrah. Retrieved 19 October 2020. 
  2. "Alphonse Menyo films". MUBI. Retrieved 19 October 2020. 
  3. "Full list of winners at Ghana Movie Awards 2015". GhanaWeb. http://www.ghanaweb.com/GhanaHomePage/entertainment/Full-list-of-winners-at-Ghana-Movie-Awards-2015-404293. 
  4. "Alphonse Menyo". The Movie Database. Retrieved 2024-08-20.