Gold Coast Lounge
Gold Coast Lounge jẹ́ fíìmù ti orílẹ̀-èdè Ghana tó jáde ní ọdún 2020, èyí tí Pascal Aka ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ tí ó sì darí fíìmù ọ̀hún. Àwọn òṣèré tó kópa nínú fíìmù náà ni Alphonse Menyo, Adjetey Anang, Zynnell Zuh, Raquel.[1][2][3]
Gold Coast Lounge | |
---|---|
Poster | |
Adarí | Pascal Aka |
Àwọn òṣèré | Adjetey Anang Fred Nii Amugi Akofa Edjeani Asiedu Alphonse Menyo Cina Soul Zynnell Zuh |
Orílẹ̀-èdè | Ghana |
Èdè | English |
Ìsọníṣókí
àtúnṣeIlé-iṣẹ́ Gold Coast Lounge, èyí tí John Donkor tó jẹ́ ọ̀daràn ń darí jẹ́ agbègbè kan tí àwọn ọ̀daràn máa ń pọ̀ sí jù. Ìjọba tuntun sì pinnu láti ti ibẹ̀ pa. Lásìkò yìí, Donkor fúnra ẹ̀ wà ní ẹ̀wọ̀n, èyí sì mú kí àwọn ọmọọṣẹ́ Donkor máa ṣamójútó iṣẹ́ náà, ìyẹn Daniel àti Wisdom.
Àwọn méjèèjì ni Donkor gbà tọ́ láti ìgbà tí wọ́n wà ní ọmọ kékeré. Daniel àti Wisdom bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe orogún ara wọn nítorí ipò olùdarí iṣẹ́ yìí. Ìṣorogún yìí wá pọ̀ si lẹ́yìn tí Donkor fi ìdí ẹ̀ lélẹ̀ pé Daniel ni ó máa jogún iṣẹ́ òun.
Lẹ́yìn tí wọ́n pa olórí wọn, èyí tó dàgbà jù lọ bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣàkóso iṣẹ́, èyí sì fa ìwádìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ìjọba.
Àwọn òṣèré tó kópa
àtúnṣe- Alphonse Menyo gẹ́gẹ́ bí Daniel
- Pascal Aka gẹ́gẹ́ bí Wisdom
- Raquel Ammah gẹ́gẹ́ bí Rose
- Fred Nii Amugi gẹ́gẹ́ bíi Inspector Adwene Mu Ti
- Adjetey Anang gẹ́gẹ́ bíi John Donkor
- Akofa Edjeani Asiedu gẹ́gẹ́ bíi Auntie Adjoa
- Gideon Boakye gẹ́gẹ́ bíi Yaw
- Etta JoMaria gẹ́gẹ́ bíi àbúròbìnrin Daniel
- Cina Soul gẹ́gẹ́ bíi Ama
- Zynnell Zuh gẹ́gẹ́ bíi Akatua
Àwọn àmì-ẹ̀yẹ
àtúnṣeNí ọdún 2019, fíìmù náà gba àmì-ẹ̀yẹ mẹ́jọ ní Ghana Movie Award, bẹ́ẹ̀ sì ni ó gba àmì-ẹ̀yẹ mẹ́fà ní Golden Movie Awards ní ọdún 2020.[7]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Asankomah, Tony (2020-01-05). "Movie Review: Gold Coast Lounge, Pascal Aka Breaking the Mould With 'Afro-Noir'.". GhMovieFreak (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-02-06.
- ↑ 2.0 2.1 Asankomah, Tony (2022-01-05). ""Gold Coast Lounge" secures streaming deal with US streaming company TOPIC". GhMovieFreak (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-02-03.
- ↑ "Award winning Ghanaian director on his movie ‘Gold Coast Lounge’ premiering in the United States and Canada". www.gq.co.za (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-02-03.
- ↑ "GOLD COAST LOUNGE". FILM AFRICA 2020 (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-09-28. Archived from the original on 2021-01-17. Retrieved 2021-02-06. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Gold Coast Lounge". www.luxorafricanfilmfestival.com. Retrieved 2021-02-06.
- ↑ Okehie, Sonia (2019-11-02). "Pascal Aka's new Movie "Gold Coast Lounge" Premieres in January 2020". Ghana Film Industry (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-05-12. Retrieved 2021-02-06. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Asankomah, Tony (2022-01-05). ""Gold Coast Lounge" secures streaming deal with US streaming company TOPIC". GhMovieFreak (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-02-05.