Amanda Black
Amanda Benedicta Antony (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù keje, ọdún 1993), tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Amanda Black,[1] jẹ́ olórin ti orílẹ̀-èdè South Africa àti òǹkọrin. Ìlú Gcuwa ni wọ́n bi si, ibẹ̀ ló sì dá̀gbà sí pẹ̀lú. Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olórin bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1999, nígbà tí ó wà ní ọmọdún mẹ́fà, níbi tí ó ti ń kọ orin ní ilé-ìjọsìn. Amanda jẹ́ ọ̀kan lára àọn olùdíje Idols South Africa apá kọkànlá.[2] Black kó lọ sí ìlú Johannesburg ní ọdún 2016 láti tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ orin kíkọ rẹ̀. Ó tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn pẹ̀lú Ambitiouz Entertainment ní ọdún 2016, ó sì di ìlúmọ̀ọ́ká ní ọdún kan náà lẹ́yìn tí ó ṣàgbéjáde orin àdàkọ rẹ̀, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Amazulu",[3] èyí tí wọ́n yàn fún àmì-ẹ̀yẹ lóríṣiríṣi. Àwo-orin àkọ́kọ́ rẹ̀, ìyẹn Amazulu (2016), mu kí ó gba àmì-ẹ̀yẹ lóríṣiríṣi bíi "Àwo-orin tó dára jù lọ fún ọdún náà", "Best Newcomer of the Year," "Best Female Artist of the Year" àti "Best R&B Soul/Reggae Album".[4] Ní ọdún 2019, ó di olórin tí àwọn ènìyàn ń gbọ orin rẹ̀ jù lọ ní orí Apple Music.[5]
Amanda Black | |
---|---|
Background information | |
Orúkọ àbísọ | Amanda Benedicta Antony |
Ọjọ́ìbí | 24 Oṣù Keje 1993 Mthatha, Eastern Cape, South Africa |
Irú orin | |
Occupation(s) |
|
Years active | 2015–present |
Labels |
|
Associated acts |
Àwo-orin Amanda kẹta, èyí tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́, Mnyama jáde ní ọdún 2021. Lẹ́yìn náà ni ó ṣá̀gbéjáde orin àdákọ méjì, tí àkọ́lé wọn ń jẹ́; "Kutheni Na" àti "Let It Go".
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeAmanda Benedicta Antony jẹ́ Xhosa.[6] Ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù keje, ọdún 1993 ni wọ́nbi, sí ìlú Mthatha, Eastern Cape, ní South Africa, ó sì dàgbà sí ìlú Butterworth, Eastern Cape, níbi tí ó ti lo ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀. Bákan náà ni ó gbé ní East London. Ó kó lọ sí Port Elizabeth, níbi tí ó ti parí ètò-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní Kabega Christian School, Port Elizabeth, kí ó ṣẹ̀ tó wá tẹ̀síwájú ní Nelson Mandela Metropolitan University, níbi tí ó ti kékọ̀ọ́ nípa Ẹ̀kó.[7]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Nkwanyana, Fundiswa (13 December 2016). "I always knew I'd be famous – Amanda Black". The Citizen. South Africa. Retrieved 21 May 2017.
- ↑ "Top 5 Idols SA contestants with successful music careers". Archived from the original on 19 May 2022. Retrieved 11 October 2021. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Songstress Amanda Black releases new single Amazulu". South African Broadcasting Corporation. 16 October 2016. Archived from the original on 10 October 2017. Retrieved 21 May 2017. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Bambalele, Patience. "Amanda Black proves her star power". Sowetan LIVE. Retrieved 28 May 2017.
- ↑ Samanga, Rufaro (16 August 2019). "In Conversation with Amanda Black: 'I've grown incredibly from the girl who wrote 'Amazulu' - OkayAfrica". OkayAfrica.
- ↑ TshisaLIVE. "Amanda Black: I once believed that being black wasn't cool". Times LIVE. Retrieved 28 May 2017.
- ↑ Bambalele, Patience. "Amanda Black proves her star power". Sowetan LIVE. Retrieved 21 May 2017.