Ambrose Olútáyọ̀ Ṣómidé

Ambrose Olútáyọ̀ Ṣómidé jẹ́ olóòtú ètò lórí ẹ̀rọ TV/Radio. Ó kàwé gboyè nínú ẹ̀kọ́ Urban and Regional Planning ní ilé-ẹ̀kọ́ Ọbáfẹ́mi Awolọ́wọ̀ University ní ìlú Ilé Ifẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni Adarí àgbà fún ilé iṣẹ́ ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ ti DAAR Communications Plc (DCP), tí ó sì dá ìkànì Fàájì FM sílẹ̀ .[1]

Ambrose Olútáyọ̀ Ṣómidé
Birth nameAmbrose Olútáyọ̀ Ṣómidé
BornAbẹ́òkúta, Ìpínlẹ̀ Ògùn
Alma materOAU
ShowMìnì-jọ̀jọ̀
Station(s)Raypower 100.5 FM
Fàájì FM
CountryNàìjíríà

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Olútáyọ̀ ní ìlúAbẹ́òkúta,ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Baptist tí ó wà ní ìlú Abẹ́òkúta. Ní ọdún 1976, wọ́n gbàá wọlé sí Fásitì Ilé-Ifẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí a ti ń ṣe ààtò ìlú (urban and regional planning). Olútáyọ̀ sè wípé òun fẹ́ràn láti ma wà láàrín àwọn obìnrin jùlọ. [2] Ó dara pọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ Ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ ti Raypower 100.5 FM ní ọdún 1994.[3]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀

àtúnṣe

Ó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ní ọdún 1982, ní ilé iṣẹ́ Radio Nigeria (RN) ti ìjọba àpapọ̀ tí ó wà ní ìlú Abẹ́òkúta gẹ́gẹ́ bí oníṣirò ìròyìn (news accountant), lẹ́yìn tí ó jáde ìwé mẹ́wá. Ní ọdún 1984, ìjọba ológun tí ọ̀gágun Muhammadu Buhari ń ṣàkóso rẹ̀ ti ilé-iṣẹ́ Rédíò náà pa. [2] Ní ọdún 1985, Olútáyọ̀ tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú àjọ OPIC ìyẹn (Ogun State Property and Investment Corporation) ní ìlú Abẹ́òkúta kan náà ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, ṣájú kí ó tó wọ ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì. Ní ọdún 1994. Ambrose pàdé ọ̀rẹ́ rẹ̀ Bashiru Àdìsá tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Bàbá Gbọin. [4] Ní ọdún 2006, ó ṣèrìn-àjò lọ sí [United Kingdom]] láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa okòwò talk show nílé iṣẹ́ BBC. Ó bẹ̀rẹ̀ ilé-iṣẹ́ Faaji 106.5 FM ní ọdún 2012, tí ó jẹ́ ẹ̀ka ti DCP.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Veteran Presenter, Ambrose Shomide Talks To CityScoop On His 33yr Career In Broadcasting". city people. Archived from the original on 2 May 2016. Retrieved 12 May 2016. 
  2. 2.0 2.1 adeola balogun. "I don’t have many male friends, but I enjoy the company of women". nigeriafilm.com. Retrieved 20 February 2016. 
  3. ckn nigeria. "Ambrose Somide Loses Mum". Retrieved 20 February 2016. 
  4. daniel adeleye. "‘I have a way of handling female fans’". the nation online. Retrieved 24 November 2015.