Amina Zakari
Amina Bala Zakari (tí a bí ní ọjọ́ kẹtalélógún oṣù kẹfà ọdun 1960) jẹ́ alága[1] aájò Àjọ elétò ìdìbò lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà[2] (INEC) tẹ́lẹ̀rí. Ìyàn sípò rẹ̀ fìdí múlè ní ìgbà tí ààrẹ Muhammadu Buhari fi sí ipò náà lẹ́yìn tí sáà Attahiru Jega wá sí ìparí ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù keje ọdun 2015.
Amina Zakari | |
---|---|
Alága Àjọ elétò ìdìbò lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà | |
In office 30 July 2015 – 9 November 2015 | |
Asíwájú | Attahiru Jega |
Arọ́pò | Mahmood Yakubu |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 23 Oṣù Kẹfà 1960 |
Zakari ni obinrin àkọ́kọ́[3] tí ó kókó dé ipò adarí àjọ INEC.[4][5]
Ìpìlẹ̀ àti Ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeZakari jẹ́ ọmọ ọba ní Ìpínlẹ̀ Jígàwà. A bi ní ọjọ́ kẹtalélógún oṣù kẹfà ọdun 1960 sínú Emir ti Kazaure, Hussaini Adamu. Zakari parí ìwé mẹ́wàá rẹ̀ ní Shekara Girls Primary School, ti Ìpínlẹ̀ Kano ní ọdun 1971[6] àti ìwé sẹ́kọ́ndìrì rẹ̀ ní[6] Queens College ti ìpínlè Èkó. Ó ní àmì ẹyẹ Bachelor Science degree[1] nínú ìmò Pharmacy(òun sì ni akẹ́kọ̀ọ́ tí èsì ìdánwò rẹ̀ da jù nígbà tirẹ̀) Yunifásítì Àmọ́dù Béllò tí Zaria ní ọdun 1980.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 "The Acting Chairman" Archived 2015-09-10 at the Wayback Machine.. inecnigeria.org.
- ↑ "INEC Nigeria". inecnigeria.org.
- ↑ "I am not desperate to become substantive INEC chairman - Zakari". DailyPost Nigeria.
- ↑ Clement Ejiofor (30 June 2015). "Amina Zakari Is New INEC Chairman". Naij.com - Nigeria news..
- ↑ Morgan Winsor (1 July 2015). "Who Is Amina Bala Zakari? Buhari Appoints Nigeria's First Woman Election Chair". International Business Times.
- ↑ 6.0 6.1 "15 facts about new INEC boss, Amina Zakari". Vanguard News. 30 June 2015.