Anamero Sunday Dekeri
Anamero Sunday Dekeri jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ ède Nàìjíríà, òun ni aṣojú àgbègbè Etsako lọ́wọ́ lọ́wọ́ ní ilé ìgbìmọ̀ aṣojú Nàìjíríà.
Anamero Sunday Dekeri | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 25 Oṣù Kẹ̀wá 1969 Ogute-Oke, Okpella |
Ẹ̀kọ́ | Ambrose Alli University, Ekpoma |
Iṣẹ́ | Member House of Representative Etsako Federal Constituency |
Political party | All Progressives Congress |
Website | anamero.com |
Ìpìlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeA bí Anamero Sunday Dekeri sí abúlé Ogute-Oke, Okpella, Ìpínlẹ̀ Edo, Nàìjíríà. Àwọn òbí rẹ̀ ń sin ẹranko. Dekeri gba ìwé-ẹ̀rí rẹ̀ àkọ́kọ́ láti ilé ìwé Ugbedudu Primary School àti ìwé ẹ̀rí Ṣekọ́ndírì láti ilé ìwé Ogute-Oke Secondary. Ó tún gba ìwé-ẹ̀rí Bachelor of Law ní Yunifásítì Ambrose Alli, Ekpoma. Ó kàwé gboyè náà ní Nigeria Police College, Ikeja.[citation needed]
Òṣèlú
àtúnṣeDekeri bẹ̀rẹ̀ òsèlú ní ọdún 2019, a sì yàn án gẹ́gẹ́ bi aṣojú ìwọ Etsako ní Ilé ìgbìmọ̀ aṣojú Nàìjíríà lábé ẹgbẹ́ òsèlú All Progressives Congress (APC) party. Ó mú àdá dídá of Federal Medical Center kalẹ̀ ní Uluoke, Edo State,[1][2] àti ìdá Federal College of Technical Education, Okpella Ìpínlẹ̀ Edo.[1]
Ní ọdún 2023, Dekeri fi ète rẹ̀ láti du ipò gómìnà fún gómìnà Ìpínlẹ̀ Edo hàn,[3][4] lábé ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Àwọn ìpolongo rẹ̀ dá lórí ète rẹ̀ láti mú ìyípadà ọ̀tun bá ẹ̀kọ́, ìlera ara, isẹ́ àgbè, oúnjẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[5]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 "BILLS DEPARTMENT HOUSE OF REPRESENTATIVES 10TH NATIONAL ASSEMBLY" (PDF). nass.gov.ng. Retrieved 2024-01-16.
- ↑ "Bills". Anamero (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-01-16.
- ↑ TVCN (2023-12-04). "Anamero Dakari Declares For Edo Governorship Under APC - Trending News" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-01-16.
- ↑ Hon Anamero Dekeri's Declaration Speech for Edo Governorship 2024 (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì), retrieved 2024-01-16
- ↑ "Hon Anamero Dekeri Declaration Speech for Edo Governorship" (PDF). anamero. 2023-12-04. Retrieved 2024-01-16.