Anthonia Kehinde Fatunsin

Anthonia Kehinde Fatunsin jẹ́ awalẹ̀pìtàn ọmọ Nàìjíríà, èyí tí àwọn onímọ̀ Gẹ̀ẹ́sì mọ̀ sí archaeologist. Wọ́n kà á sí obìnrin àkọ́kọ́ tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ìṣẹ̀ǹbáyé ní Nàìjíríà, àti obìnrin àkọ́kọ́ tó jẹ́ olórí ilé mùsíọ́mù orílẹ̀-èdè Ìbàdàn [1](National Museum of Ibadan).[2]Iṣẹ́ ìṣe ààyè rẹ̀ ti dojúkọ púpọ̀ jùlọ lórí amọ̀ mímọ Yorùbá, pàápàá láti agbègbè Ọ̀wọ̀.[3]

Anthonia Kehinde Fatunsin
Àwọn àlàyé onítòhún
Known forBeing the first female archaeologist from Nigeria

Iṣẹ́ Rẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Wúlẹ̀wúlẹ̀ Ti Awọn Òwúlẹ̀wútàn àtúnṣe

Fátúnsìn bẹ̀rẹ̀ wúlẹ̀wúlẹ̀ nínu ilẹ̀ ìlú Igbólàjà àti Ìjẹ̀bú-Ọ̀wọ̀ láti ṣàwárí ohun alùmọ́nì tí wọ́n ń pè ní [ terracotta] lọ́dún 1981. Ọ̀gbẹ́ni Babásẹ̀hìndé Adémúléyá lati ifáfitì Obafemi Awolowo University ṣàkíyèsí pé àyẹ̀wò rẹ̀ ni ìgbà kejì tí iṣẹ́ ìwádìí wúlẹ̀wúlẹ̀ báyìí wáyé lẹ́yìn ti Ekpo Ẹyọ[4] tí ó wáyé lọ́dún 1976. Bí ó tilẹ̀ wù kí ó rí, ìwádìí Fátúnsìn ni ó sàlàyé ọ̀ríkínniwín lórí àwọn ère. [5]

Iṣẹ́ Rẹ̀ Lórí Àwọn Mùsíọ́mù àtúnṣe

Fatunsin ti kọ nípa ipa tí Wúlẹ̀wúlẹ̀ ti àwọn òwúlẹ̀wútàn ní àwọn Museum Naijiria àti ipa rẹ̀ lórí àwọn ohun-ìní àṣà ní orílẹ̀-èdè náà.[6] A ti mọ̀ ọ́ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọnà fún ìrònú àti ìtumọ̀ wúlẹ̀wúlẹ̀ ti àwọn òwúlẹ̀wútàn lẹ́hìn òmìnira ní Ilẹ̀ Áfíríkà.[7]

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. National Museum of Unity, Ibadan - Wikipedia
  2. Oziogu, Apollos Ibeabuchi (17 June 2012). "Owo culture of ancient Nigeria". Vanguard. Retrieved 2021-06-09. 
  3. "Fatunsin, Anthonia". WorldCat. Retrieved 2018-04-02. 
  4. en.wikipedia.org/wiki/Ekpo_Eyo
  5. Babásèhìndé, Adémúlèyá (July 2015). "Stylistic Analysis of Igbo 'Laja Terracotta Sculptures of Owo". Mediterranean Journal of Social Sciences 6 (4 S2). http://www.mcser.org/journal/index.php/mjss/article/download/7071/6774. Retrieved 2021-07-01. 
  6. Fatunsin, Anthonia K. (1994). "Archaeology and the protection of cultural heritage: the Nigerian situation" (in en). Archéologie et sauvegarde du patrimoine: Actes du VIe colloque, Cotonou, Bénin, 28 mars - 2 avril 1994 = Archaeology and safeguarding of heritage: Proceedings of the 6th colloquium, Cotonou, Benin, 28th March - 2nd April 1994: 63–69. https://www.bcin.ca/bcin/detail.app?id=170008. 
  7. Theory in Africa. doi:10.4324/9781315716381-7. https://www.taylorfrancis.com/books/e/9781315716381/chapters/10.4324/9781315716381-7. Retrieved 2019-11-14.