Aríṣekọ́lá Àlàó

Arisekola Abdulazeez Àlàó (tí a bí ní Ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì ọdún 1945 tí ó sì kú ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Kàrún ún ọdún 2014) jẹ́ gbajúmọ̀ oníṣòwò láti ìlú Ìbàdàn .[1] Ó joyè Ààrẹ Mùsùlùmí tí gbogbo ilẹ̀ Yorùbá, èyí wáyé nípa ìrànlọ́wọ́ lóríṣiríṣi tí ó máa ń ṣe láti gbé ẹ̀sìn Mùsùlùmí ga. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ́ṣáláṣí ló kọ́ káàkiri ilẹ̀ Yorùbá nígbà ayé rẹ̀. [2] [3]

Ìgbé-ayé rẹ̀ ni ìbẹ̀rẹ̀

àtúnṣe

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú, wọ́n bí Aríṣekọ́lá Àlàó ni Ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì ọdún 1945 sì abúlé Ajia, ní ìjọba-ìbílẹ̀ Ọ̀nà àrà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Orúkọ bàbá rẹ̀ ni Alhaji Abdul Raheem Ọlátúnbọ̀sún Ọláníyan Àlàó, orúkọ ìyá rẹ̀ ni Alhaja Rábìàtù Ọlátútù Àlàó. Aríṣekọ́lá bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ní St. Luke’s School ní Ìbàdàn, Adigun, ó tún kàwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ ní ICC Primary School, Igosun, ní Ìbàdàn Ibadan kan náà ó sì kà á parí lọ́dún 1960. Ó gbìyànjú láti tẹ̀ síwájú nínú èkó rẹ̀ ṣùgbọ́n owó ṣàgbà fún àwọn òbí rẹ̀, ìdí nìyí tí ó fi kúkú kọ́ ẹ̀kọ́ kéwú, èyí tí ń ṣe ẹ̀kọ́ nípa èdè Lárúbáwá. Ó pegedé nínú èyí, Ọlọ́run ràn án lọ́wọ́ tí ó sì di pàràkòyí olókowò ili-mọ́ọ́nká. Nídìí okowò rẹ̀, ó là, ó sì di olówó rẹpẹtẹ. Ó fi owó rẹ̀ sin Ọlọ́run nípa ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ fún ẹ̀sìn Mùsùlùmí káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, èyí ló fà á tí wọ́n fi í joyè Ààrẹ Mùsùlùmí fún gbogbo ilẹ̀ Yorùbá lọ́dún 1980. Aríṣekọ́lá Àlàó fi àyè sílẹ̀ lọjọ́ kejìdínlógún oṣù Kàrún ún ọdún 2014. [4] [5] [6] [2]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Ibadan Businessman, Abdulazeez Arisekola Alao, Dies In Switzerland". Sahara Reporters. 2014-06-18. Retrieved 2019-11-23. 
  2. 2.0 2.1 vanguard; vanguard (2018-02-16). "Arisekola: A half of Ibadan mistaken for a single person - Vanguard News". Vanguard News. Retrieved 2019-11-23. 
  3. "UPDATE: Arisekola-Alao dies at 69". Premium Times Nigeria. 2014-06-18. Retrieved 2019-11-23. 
  4. "Arisekola Alao's mansion for termites, rodents - The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2016-07-08. Archived from the original on 2016-11-04. Retrieved 2019-11-23. 
  5. "Aare Arisekola's life and some of his quips - The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2017-06-18. Archived from the original on 2021-08-04. Retrieved 2019-11-23. 
  6. "Will Of Late Ibadan Billionaire, Arisekola Alao, Read". Information Nigeria. 2014-06-27. Retrieved 2019-11-23.