Arrow of God

ìwé lítíréṣọ̀ láti ọwọ́ Chinua Achebe.

Ìwé eré onítàn Arrow of God [[[1] |Arrow of God]]. Arrow of God. Heinemann. ISBN 1101666382, 9781101666388. , ni wọ́n gbé jáde tí ọdún 1964, ni ó jẹ́ ìwé àpilẹ̀kọ ti gbajú-gbsjà ònkọ̀wé Chinua Achebe. Ìwé yí àti Things Fall Apart pẹ̀lú No Longer at Ease, ni wọ́n sọ wípé wọ́n jẹ́ iwé eré oníṣe onítàn tí ìlapa-èrò wọn dọ́gba jùlọ, tí ẹ̀kọ́,ibùdó ìtàn, àti olú-kókó ọ̀rọ̀ inú wọn náà sì fara jọra, tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì ń pè níTrilogy. Ìwé yí dá lórí olú ẹ̀dá ìtàn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ "Ezeulu", tí ó jẹ́ bàbá Aláwo fún abúlé àwọn Ìgbò tí ó pọ̀ ní àsìkò ìmúnisìn àwọn Gẹ̀ẹ́sì tí ó kojú ìtẹ̀mẹ́rẹ̀ àwọn amúnisìn àti àwọn olùpologo ẹ̀sìn Kírísítì ní àsìkò ọdún 1920. [2] Wọ́n gbé ìwé náà jáde látàrí ipa ribi ribi tí ilé iṣ ìtẹ̀wé Heinemann African Writers Series kó kí ó lè ṣeéṣe.

Arrow of God
Olùkọ̀wéChinua Achebe
CountryÀwọn Ìpínlẹ̀ Aṣọ̀kan
LanguageGẹ̀ẹ́sì
PublisherHeinemann
London
Publication date
1964
Media typePrint (hardback)
Pages287 pp
Preceded by'No Longer at Ease 
Followed by'A Man of the People 

Orúkọ tí wọ́n pe ìwé yí Arrow of God ni wọ́n fàyọ láti inú òwe àwọn ẹ̀yà ìgbò tí ó túmọ̀ sí 'iṣẹ́ olúwa àwá márídìí'. [3] Ìwé eré onítàn elére oníṣe Arrow of God gba àmì-ẹ̀yẹ ìdálọ́lá ti Jock Campbell àti New Statesman alákọ̀ọ́kọ́ irú rẹ̀ fún ìkọ̀wé ilẹ̀ Adúláwọ̀[4]

Ìtàn inú ìwé náà léréfèé

àtúnṣe

Ìwé ereé onítàn eléré oníṣe yí ni wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ nínú àwọn abúlé àwọn ẹ̀yà Ìgbò tí ó jẹ́ ìkan lára ìletò àwọn Gẹ̀ẹ́sì amínisìn ní àsìkò ọdún 1920s. Ezeulu jẹ́ baba abọrẹ̀ òrìṣà Ulu tí ó kalẹ̀ sí abúlé Alusi, tí oríṣi ìlú tí àpapọ̀ orúkọ wọn ń jẹ́ Umuaro ń sìn. Ìjà kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin ìlú Umuaro àti Okperi tí ó jẹ́ ìlú kan nítòsí Umuaro, ìjà yí wá sópin nígbà tí ọ̀gbẹ́ni T.K Winterbottom tí ó jẹ́ aṣojú àwọn Gẹ̀ẹ́sì amúnisìn bá wọn dá si.

Àwọn Ìtọ́ka sí

àtúnṣe
  1. "Chinua Achebe - Biography, Books, & Facts". Encyclopedia Britannica. 1998-07-20. Retrieved 2023-06-03. 
  2. "Arrow of God by Chinua Achebe". Time Magazine. November 10, 1967. Archived from the original on 2012-10-20. https://web.archive.org/web/20121020132753/http://www.time.com/time/magazine/article/0,9171,837568,00.html?iid=chix-sphere. Retrieved 2007-09-19. 
  3. Smith, Daniel Jordan (September 22, 2001). "'The Arrow of God': pentecostalism, inequality, and the supernatural in South-Eastern Nigeria.". Africa (Edinburgh University Press) 71 (4): 587. doi:10.2307/1161581. ISSN 0001-9720. JSTOR 1161581. 
  4. Ezenwa-Ohaeto Chinua Achebe: A Biography __:James Currey Ltd ISBN 0-85255-545-8 page 105