Arugbá jẹ́ gbankọgbì sinimá àgbéléwò kan tí gbajúmọ̀ olóòtú àti olùdarí, ọ̀jọ̀gbọ́n Túndé Kèlání gbé jáde lọ́dún 2008. Eré yìí dá lórí àṣà àti ìtàn tí ó wọpọ̀ nínú ìtẹ̀síwájú ẹ̀sìn àti ètò ìjọba ní ilẹ̀. Yorùbá Sinimá yìí dá lórí àṣà Arugbá tí ó máa ń wáyé nínú ọdún ìbílẹ̀ kan tí wọ́n máa ń ṣe ní ìlú Òṣogbo, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ọ̀ṣun Òṣogbo. Gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin, Bùkọ́lá Awóyẹmí tí ó fẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré Dàmọ́lá Ọlátúnji ni ó kópa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá-ìtàn Arugbá nínú eré náà.

Arugba
Fáìlì:Arugba Movie Poster.jpg
arugba movie poster se
AdaríTunde Kelani
Olùgbékalẹ̀Mainframe Productions
Òǹkọ̀wéyemi Peter Badejo Segun Adefila Kareem Adepoju Lere Paimo
OrinWole Oni Adunni & Nefretiti Segun Adefila
Ìyàwòrán sinimáLukman AbdulRahman
OlóòtúFrank Anore Hakeem Olowookere
Déètì àgbéjáde
  • 2008 (2008)
Àkókò95 minutes
Orílẹ̀-èdèNigeria
ÈdèYoruba
Ìnáwó₦22 million[1]

Nínú eré yìí, ọ̀jọ̀gbọ́n Tunde Kelani ṣe àfihàn ìlànà ohun tí a ń pè ní arugbá nínú Ayébọ̀, èyí tí ó jẹ́ àṣà Yorùbá. Arugbá ni àwọn obìnrin ti a yàn láti máa rú ẹrù Ifá tàbí ohun èlò ètùtù tí wọ́n á lò nínú àṣà ìbọrà. Ìtàn náà sọ́ nípa Arúgbá kan, Adetutu, ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀dá ìtàn pàtàkì.

Ohun tí eré yìí fi hàn ni bí àwọn àṣà àti ètò Yorùbá ṣe ní ipa tó ṣe pàtàkì nínú èdá àti ìgbàgbọ́, àti bí ó ṣe yẹ kí àwọn èwe máa tẹ̀ lé ètò náà bó ti yẹ. Eré náà tún sọ nípa ìyípadà àti ija nínú àwùjọ wa, nígbà tí àwọn aláṣẹ máa ń ṣe àtàtìpó àwọn ètò ìjọba àti àwọn àṣà àtàtà wọn.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Abulude, Samuel (31 May 2014). "Pirates Have Made Movie Makers Paupers– Tunde Kelani". Leadership. Leadership Newspapers. Archived from the original on 22 April 2016. Retrieved 29 September 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)