Asiru Olatunde (1918–1993) jẹ́ ayàwòrán, alágbẹ̀dẹ ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ó jé ọkan lára àwọn gbajúgbajà ayàwòrán ní ìlú Òṣogbo.[1] Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ayàwòrán kékeré kan tí wọ́n darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn oníṣẹ́-ọnà kan, ìyẹn Oshogbo School of art.[2] Àwọn àwòrán rẹ̀ dá lórí àwọn ìtàn ìgbaani ti ilẹ̀ Yorùbá àti àwọn ìtàn inú Bíbélì.

Asiru Olatunde

Ìgbésíayé rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Asiru Olatunde sínú ìdílé àwọn alágbẹ̀de àmọ́ àìsàn[3] fi ipá gba iṣé yìí ní ọwọ́ rẹ̀ ní ọdún 1960. Ó ṣe àwọn ohun ọ̀ṣọ́ fún títà fún ìgbà díẹ̀ kí ó tó yí iṣẹ́rẹ̀ sí ìyàwòrán, gẹ́gẹ́ bí i àmọ̀ràn tí Uilli Beier àti Suzanne Wenger fun ní ọdún 1961. Ó máa ń fi bàbà, alumíníọ́ọ̀mù àti irin ṣe iṣé rẹ̀,[4] ó sì máa ń fi irin rọ àwọn ẹranko lóríṣiríṣi. Wọ́n ṣàfihàn iṣé rẹ̀ ní IMF headquarters, àti ní Smithsonian Institution bákan náà.[5]

Ikú rẹ̀ àtúnṣe

Ó kú ní ọdún 1993.

Àṣàyàn iṣẹ́ rẹ̀ àtúnṣe

  • Tree of Life[6]

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Ikpakronyi unveils Post COVID-19 vision for NGA, artists". Guardian. 
  2. "Asiru Olatunde". Archived from the original on 2007-06-10.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "Asiru Olatunde | Indigo Arts". indigoarts.com. Retrieved 2020-10-01. 
  4. "ASIRU OLATUNDE". Retrieved 2020-09-09. 
  5. "Asiru Olatunde". Art Network. Retrieved 2020-09-09. 
  6. "Nairobi Gallery exhibition celebrates 50 years Nigerian art". 2018-04-23. Retrieved 2020-09-09.