Ataare
Ataare jẹ́ ata, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èròjà fún ṣíṣe ọbè ní ilẹ̀-Adúláwọ̀.[1]Ó sì wúlò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan bíi iṣẹ́ àmúṣagbára àti fífi ṣe ìwúre láwùjọ Yorùbá.
Ìwúlò
àtúnṣe- Wọ́n ń lo ó láti fi se ọbẹ̀. Tí wọ́n bá fẹ́ fi se ọbẹ̀, wọ́n á kọ́kọ́ gun nínú odó kí wọ́n tó dà á sínú ọbẹ̀.[2]
- Nínú àṣà Ìsọmọ-lórúkọ nílẹ̀ Yorùbá, àwọn Yoruba máa ń lò ó láti fi ṣàdúrà fọmọ titun.Tí àdùrá na lọ báyìí "Ataare kì í di tirẹ̀ láàbọ̀ kíkún ni ataare n kún, ayé rẹ a kún fówó, ayé rẹ a kún fọ́mọ, ayé rẹ a kún fún onírúurú dúkìá jìngbìnnì.
- Ní ilẹ̀ Igbo, àwọn Igbo náà máa ń lò ó fún ìsọmọlórúkọ.
- Nínú ìgbàlejò, wọ́n a máa ń fún àwọn àlejò ní Obì, àti ataare, wọ́n á sì fi ṣàdúrà.[3]
- Lásìkò ààrùn èrànkòrónà ní ọdún 2019, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí oògùn.During the Covid-19 pandemic, it was used in medicine.[4]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Ataare". Yoruba Imports. Retrieved 2023-01-23.
- ↑ "Enjoy medicinal value of alligator pepper (Aframomum melegueta)". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-07-05. Retrieved 2021-08-10.
- ↑ (in en) A handbook of Nigerian culture. Dept. of Culture, Federal Ministry of Information and Culture. 1992. p. 30. ISBN 9789783131613. https://books.google.com/books?id=n1AuAQAAIAAJ.
- ↑ "More plants with antiviral properties validated". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-08-13. Archived from the original on 2021-08-10. Retrieved 2021-08-10.