Àwọn ènìyàn dúdú

(Àtúnjúwe láti Awon alawodudu)

Ẹ̀yà àwọn Ènìyàn dúdú jẹ́ ọ̀kqn ìpínsísọ̀rí àwọn èya lágbàáyé, látàrí ìrísí àwọ̀ àti ìrísí wọn. Àmọ́ ṣá, kìí ṣe.gbogbo ẹni tí abá pè ní Aláwọ̀ dúdú náà ni wọ́n dú láwọ̀, bí kò ṣe wípé wa fi ma ń ṣàdáyanrí irúfẹ́ ẹ́yà tí ẹnìkan tabí ẹlòmíràn jẹ́ ni. Ní ìlú àwọn aláwọ̀ funfun, wọ́n ma ń tọ́ka sí ẹni tí kò bá fín láwọ̀ bíi tiwọn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn dúdú. Wọ́n sábà ma ń lo gbólóhùn "Dúdú" fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti Sub-Saharan Africa àti àwọn ènìyàn tí wọ́n bá ti wá láti Oceania. Ẹ̀wẹ̀, àwọn ènìyàn Áfíríkà kìí nàka kìí le ara wọn ní "Dúdú" gẹ́gẹ́ bí àwọn aláwọ̀ funfun ṣe ma ń tọ́ka sí wọn. Wọ́n ka gbólóhùn "Dúdú kún èdè ìperí àwọn aláwọ̀ funfun.[1][2] The AP Stylebook[1][2] [3] Ọ̀nà oríṣiríṣi ni àwọn ènìyàn àwùjọ kọ̀ọ̀kan ma ń lò láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyá aláwọ̀ dúdú ni ẹnìkan tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Àmọ́ àwọn ọ̀nà wọ̀nyí ti yí padà ní òde òní. Púpọ̀ nínú àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé lónìí ni wọ́n lè pe ẹnìkan ní aláwọ̀ dúdú látàrí àwọ̀ tàbí irúfẹ́ ipò tí ẹni bẹ́ẹ̀ bá wà ní àwùjọ àwọn ènìyàn kan. Ní orílẹ̀-èdè Bríténì, wọ́n lè tọ́ka sí Dúdú gẹ́gẹ́.bí ẹ́ni àwọ̀ rẹ̀ dúdú, tí kìí ṣe ọmọ bíbí orílẹ̀ Yúróòpù. Ní ẹkùn Australasia, àwọn ma ń tọ́ka sí Dúdú gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ìran wọn láwọ̀l. Ní ọkàn ẹnikẹ́ni, àwùjọ, Ìlú, agbègbè tàbí orílẹ̀-èdè yóòwù lágbàáyé, gbólóhùn Dúdú jẹ́ gbólóhùn ijọ́un, tí ó ń tàbùkù, kó ẹrẹ̀ báni tabí gbólóhùn ìfojú pani rẹ́ tí kò yẹ.kí ẹnikẹ́ni ó ma lò láti ṣàpèjúwe, tọ́ka, tàbí ṣàdáyanrí ẹnìkan, tàbí àwùjọ ènìyàn kankan lágbàáyé. Bí kìí ṣe láti fi sọ irúfẹ́ àwọ̀ tí irúfẹ́ ẹni tàbí àwọn ènìyàn náà ní. [4]

Ọkùnrin aláwọ̀ dúdú láti inú ẹ̀yà Khoisan ní Gúsù ilẹ̀ Áfíríkà.

Ilẹ̀ Áfíríkà

àtúnṣe

Apá Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà

àtúnṣe
 
Ojú-ọ̀nà fún òwò-ẹrú àwọn LárúbáwáÀárín Ìlà-Oòrùn àti Apá Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà ní àsìkò Middle Ages.

Ọpọ àwùjọ àwọn ènìyàn aláwọ̀ dúdú apá Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà ni wọ́n ti wà ṣáájú kí wọ́n ó to ní ìmọ̀ àti òye a ń kọ̀tàn nípa àwọn ènìyàn. Àwọn mìíràn lára wọn jẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n tẹ̀dó sí àwọn ìletò káàkiri látàrí òwò àti kárà-kátà tí wọ́n ma ń ṣe, tàbí lẹ́yìn tí àwọn Lárúbáwá kò wọn lẹ́rú ní ńkan bí ọ̀rùndún méje sèyìn (7th centuries). [5][6]

 
Haratin women, a community of recent Sub-Saharan African origin residing in the Maghreb.

In the 18th century, the Moroccan Sultan Moulay Ismail "the Warrior King" (1672–1727) raised a corps of 150,000 black soldiers, called his Black Guard.[7][8]


Àwọn Itokasi

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 "AP changes writing style to capitalize "b" in Black". Associated Press. 20 June 2020. https://apnews.com/71386b46dbff8190e71493a763e8f45a. 
  2. 2.0 2.1 Henry, Tanyu (17 June 2020). "Black with a Capital "B": Mainstream Media Join Black Press in Upper-casing Race". www.blackvoicenews.com. 
  3. Lab, Purdue Writing. "Manuscript Writing Style // Purdue Writing Lab". Purdue Writing Lab (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-09-06. 
  4. Levinson, =Meira (2012). No Citizen Left Behind. Harvard University Press. p. 70. ISBN 978-0674065291. https://www.google.com/books?id=LztBPNsDLBYC&pg=PA70. 
  5. Frigi et al. 2010, Ancient Local Evolution of African mtDNA Haplogroups in Tunisian Berber Populations, Human Biology, Volume 82, Number 4, August 2010.
  6. Harich et .al (2010). "The trans-Saharan slave trade – clues from interpolation analyses and high-resolution characterization of mitochondrial DNA lineages". BMC Evolutionary Biology 10 (138): 138. doi:10.1186/1471-2148-10-138. PMC 2875235. PMID 20459715. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=2875235. 
  7. Lewis, Race and Slavery in the Middle East Archived 2001-04-01 at the Wayback Machine., Oxford University Press, 1994.
  8. "Abīd al-Bukhārī (Moroccan military organization)". Encyclopædia Britannica.