Àyàn
Iṣẹ́ Àyàn
Iṣẹ́ ìlù lílú ni a n pe ni ìṣẹ́ àyàn, àwọn ti o n sẹ iṣẹ yii ni a n pe ni “Aláyàn tàbí ‘Àyàn’. Iṣe àtìrandíran ni èyi, nitori iṣẹ afilọmọlọwọ ni. Gbogbo ọmọ ti Onílù bá bí sí ìdi Àyàn Agalú ni o ni láti kọ ìlù lílù, paapaa akọbi onílù. Dandan ni ki àkọ́bí onílù kọ iṣẹ ìlù, ko si maa ṣe e nitori àwọn onìlu ko fẹ ki iṣẹ́ náà parun.
Yàtọ̀ si àwọn ti a bì ni ìdile onìlu tabi awọn o ọmọde ti a mu wọ agbo ifa, Ọbàtálá, Eégún tàbí Ṣàngó ti wọn si n ti pa bẹ́ẹ̀ mọ oriṣiiriṣii ìlù wọn a maa n rì awọn to ti ìdílé miíran wa láti kọ ìlù lìlú lọwọ awọn onìlu. Àwọn Yorùbá bọ wọn ni “àtọmọde dé ibi orò ń wò fínní-fínní, àtàgbà dé ibi orò ń wò ranran” Òwe yìi tọka si i pe ko si ohun ti a fi ọmọdé kọ ti a si dàgbà sínú rẹ̀ ti a ko ni le se dáadáa.
Láti kékeré làwọn Yorùbá ti n kọ orìṣiiriṣi ìlù lìlú. Nígba ti ọmọde ba ti to ọmọ ọdún mẹ́wàá sí méjìlá ni yóò ti máa bá baba rẹ ti o jẹ onílù lọ òde aré. Láti kékeré yìí wá ni yóò ti máa foju àti ọkàn si bi a ti n lu ìlù. Àwọn ọmọdékùnrin tí ń bẹ nínú agbo àwọn tí ń bọ̀ Ọbàtálá yóò máa fojú síi bi a ti ń lu ìgbìn, àwọn tí n bẹ lágbo àwọn onífá yóò máa kọ bi a ti ńlu Ìpèsè. Ọ̀nà kan náà yii làwọn tí ń bẹ lágbo àwọn Eléégún àti onísàngó ń gbà kọ́ bi a ti ńlu Bàtá. Àwọn ọmọdé mìíran máa ń gbé tó ọdún mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀dógún lẹ́nu iṣẹ́ ìlù kíkọ́ yìí.