Ayo Fasanmi
Ayọrinde Fasanmi (tí a bí ní ọdún 1925-2020) jẹ́ onímọ̀ nípa òògùn àti olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]
Ayo Fasanmi | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Ìpínlẹ̀ Èkìtì, Nàìjíríà |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ | politician pharmacist |
Ìgbà iṣẹ́ | 1978–2020 |
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé
àtúnṣeA bí Ayọrinde Fasanmi ní ọdún 1925 ní Ìye Èkìtì, agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ kan ní Ìpínlẹ̀ Ekiti ní guusu ìwọ-òòrùn Nàìjíríà.[2] Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀kóbẹ̀rẹ̀ ti Saint Paul tí ó wà ní Ebute Mẹta àti ilé-ìwé ìjọba tí ó wà ní Ibadan kí ó tó wà tẹ̀síwájú lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ nípa egbògi tí ó wà ní Yaba níbití Ó ti gba ìwé ẹ̀rí diploma lórí ìmọ̀ nípa egbògi.[3] Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa òògùn ní Oshogbo fún ìgbà dí ẹ̀ kí ó tó di wípé Ó darapọ̀ mọ́ òṣèlú ní ilẹ̀ Nàìjíríà.[4]
Iṣẹ́ òṣèlú
àtúnṣeFasanmi darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú oníṣọ̀kan ti ilẹ̀ Nàìjíríà (Unity party of Nigeria) ní ọdún 1978. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn adíje nínú ìdìbò abẹ́lé fún ipò gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Ondo sùgbọ́n Ó pàdánù ìdìbò abẹ́lé yi sí ọwọ́ Michael Adekunle Ajasin, ẹni tí ó jẹ́ gómìnà tẹ́lẹ̀ fún Ipinlẹ Ondo.[5] Ní ọdún 1983, wọ́n dìbò yan Fasanmi gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ ilé ìgbìmọ̀ aṣojú kékeré ti gbogbo orilẹ̀ èdè Nàìjíríà (Federal House of Representative) láti lọ ṣe aṣojú fún àríwá Ipinlẹ Ondo. Lẹhinna, Ó ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ olùdarí fún ìla òòrùn àtijọ́ Nàìjíríà lórí àwọn ilé alákọ̀ọ́pọ̀.[6] Ní àkókò òṣèlú ẹlẹ́ẹ̀kẹrin ní Nàìjíríà, Fasanmi tún ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí igbákejì alága fún ẹgbẹ́ òṣèlú Alliance for Democracy ti agbègbè guusu ìwọ-òòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[7]
Ìgbésí ayé rẹ
àtúnṣeFasanmi ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú olóògbé ìyáàfin Àjọkẹ́ ẹnití ó di olóògbé ní ọmọ ọdún méjìlélọ́gọ́rin ní oṣù kẹwa ọdún 2014.[8]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Akinsola, Babatunde (2014-08-29). "I Never Discussed Bola Ige with Olaniwun Ajayi, Says Ayo Fasanmi". Naija247news. Retrieved 2020-03-30.
- ↑ "PDP is big for nothing - Fasanmi". The Punch - Nigeria's Most Widely Read Newspaper. 2015-02-28. Archived from the original on 2015-02-28. Retrieved 2020-04-07.
- ↑ "My greatest challenge is ensuring Awo’s legacies do not die – Senator Ayo Fasanmi". The Punch - Nigeria's Most Widely Read Newspaper. 2015-02-28. Archived from the original on 2015-02-28. Retrieved 2020-04-07.
- ↑ "Afenifere has no consensus on Jonathan – Sen. Durojaye". sunnewsonline.com. 2015-02-21. Archived from the original on 2015-02-22. Retrieved 2020-04-07.
- ↑ Babatope, Ebenezer (2015-02-22). "Senator Ayo Fasanmi at 89". tribune.com.ng. Archived from the original on 2015-02-22. Retrieved 2020-04-07.
- ↑ "Yoruba leaders should forge a synergy –Senator Ayo Fasanmi". P.M. News. 2014-04-18. Retrieved 2020-04-07.
- ↑ Adebanwi, W. (2014) (in la). Yoruba Elites and Ethnic Politics in Nigeria: Ọbáfemi Awólowo and Corporate Agency. Cambridge University Press. p. 282. ISBN 978-1-107-05422-6. https://books.google.com/books?id=Q6BcAwAAQBAJ&pg=PA282. Retrieved 2020-04-07.
- ↑ "Ayo Fasanmi’s wife dies at 82". The Punch - Nigeria's Most Widely Read Newspaper. 2015-02-28. Archived from the original on 2015-02-28. Retrieved 2020-04-07.