Ìpínlẹ̀ Èkìtì

Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà

Ìpínlẹ̀ Èkìtì jẹ́ Ìpínlè ní apá ìwọ̀ oòrùn Nàíjíríà tí ó jẹ́ dídásílẹ̀ ní ọjọ́ kìíní oṣù ọwàwà,1996 pẹ̀lú àwọn ìpínlẹ̀ tuntun márùn-rún mìíràn látọwọ́ ọ̀gágun Sani Abacha.

Ìpínlẹ̀ Èkìtì
Nickname(s): 
Location of Ekiti State in Nigeria
Location of Ekiti State in Nigeria
Country Nigeria
Date created1 October 1996
CapitalAdo Ekiti
Government
 • Governor
(List)
Kayode Fayemi [1]
Area
 • Total6,353 km2 (2,453 sq mi)
Area rank31st of 36
Population
 • Estimate 
(2005)
2,737,186
 • Rank29th of 36
GDP (PPP)
 • Year2007
 • Total$2.85 billion[2]
 • Per capita$1,169[2]
Time zoneUTC+01 (WAT)
ISO 3166 codeNG-EK

Èkìtì ti jẹ́ ìpínlẹ̀ olómìnira kí àwọn òyìnbó tó dé. Èkìtì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìpílẹ̀ Yorùbá ní ibi tí a mọ̀ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní òní. Àwọn ará Èkìtì jẹ́ àwọn tí a lè tọpasẹ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọmọ Odùduwà, bàbá àti babańlá ìran Yorùbá.[3]

Èrò méjì lówà nípa ìtàn Èkìtì. Àkọ́kọ́ ni èyí tí ó so Èkìtì mọ́ Ilé-Ifẹ̀. Ìtàn náà sọ pé Ọlọ́fin, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Odùduwà tí ó bí ọmọ mẹ́rìndílógún. Nípa pé wọ́n ń wá ilẹ̀ mìíràn láti gbé, wọ́n kúrò ní Ilé-Ifẹ̀ wọ́n sì pọ̀ sókè rajà. Wọ́n gba Iwò- Elérú ní Isarun wọ́n sì ní láti dúró síbì kan tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Igbó-Aka tí kò jìnà sí Ile-Oluji.[4]

Ọlọ́fin àti àwọn ará rẹ̀ tẹ̀síwájú nínú ìrìn-àjò wọn, Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Ọwá-Obòkun (Ọba ilẹ̀ Ijẹṣà) Orangun tí ó jẹ́ ọba Ìlá pinnu láti dúró sí ibi tí à ń pè nih Ìjẹ̀ṣà ní òní àti Igbomina ní ìpínlẹ̀ Osun.[5] Àwọn ọmọ mẹ́rìlá yòókù tẹ̀síwájú nínú ìrìn àjọ̀ wọn, wọ́n sì gúlẹ̀ sí ibi tí a mọ̀ sí Èkìtì ní òní. Wọ́n ṣe àkíyèsi pé òkè pọ̀ ní ibi tí wọ́n tẹ̀dó sí wọ́n sì pe ibẹ̀ ní 'ilẹ̀ olókìtì' èyí tí ó padà di Èkìtì, báyìí ni Èkìtì ṣe gba orúkọ.Àdàkọ:Cn

Èrò kejì nípa orísun Èkìtì ni pé Odùduwà tó jẹ́ babańlá ìran Yorùbá rin ìrìn-àjò lọ sí Ilé-Ifẹ̀, ó ri pé àwọn kan ti tẹ̀dó sí ibẹ̀. Lára àwọn olórí tí ó bá níbẹ̀ ni Agbonniregun, Obatala, Orelure, Obameri, Elesije, Obamirin, Obalejugbe, ká mẹ́nu ba díẹ̀ nínú wọn. Ohun tí ìtàn sọ nipé àwọn àrọ́mọdọ́mọ Agbọnniregun ni wọ́n wà ní Èkìtì, àpẹẹrẹ ni Alara àti Ajero tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ifá. Orunmila [Agbonniregun] gan-gan fún ra ẹ̀ gbé púpọ̀ ayé rẹ̀ ní Adó ìdí nìyín tí wọ́n fi máa sọpé 'Adó ni ilé-Ifá' . Àtìgbà náà ni àwọn ará Èkìtì tih wà níbi tí wọ́n wà dì ọ̀ní.[6]

Kò sí ẹni tí ó lè sọ pàtó ìgbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀, ìdí ni pé ìmọ̀ mọ̀-ọ́-kọ-mọ̀-ó-kọ̀ ò tí ì dé nígbà náà, ohun kan tí ó dájú tádàá ni pé àwọn èèyàn ti ń gbé ní Èkìtì fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ìtàn jẹ́ kí a mọ̀ pé àwọn ọba Èkìtì ní ọlá nígbà ayé wọn ní sẹ́ńtúrì kẹtàlá. Àpẹẹrẹ ni Ewi Ata ti Ado-Ekiti ní ọdún.

Gòmìnà ìpínlè Èkìtì nì Biodun Oyebanji

Àwọn àwòrán.

àtúnṣe
  1. "Ekiti State, Nigeria Genealogy". FamilySearch Wiki. 2020-04-11. Retrieved 2022-03-22. 
  2. 2.0 2.1 "C-GIDD (Canback Global Income Distribution Database)". Canback Dangel. Retrieved 2008-08-20. 
  3. "About Ekiti State" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-07-12. Retrieved 2021-07-12. 
  4. "How The Ara People Of Ekiti Committed Mass Suicide To Avoid Enslavement". Spread.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-03-23. Archived from the original on 2021-07-12. Retrieved 2021-07-12. 
  5. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :02
  6. "Ekiti Kete - Canada". Archived from the original on 2013-07-17. Retrieved 2018-02-14.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)