Olabanke "Banke" Meshida Lawal je make-up artist àti Olùdásílẹ̀ àti Olùdarí ilé iṣé BMPro Makeup Group, èyí tí ó jẹ́ ilé iṣé make-up ati cosmetology ní Nigeria.[1]

Banke Meshida Lawal
Ọjọ́ìbí21 Oṣù Kẹjọ 1978 (1978-08-21) (ọmọ ọdún 46)
Ile-Ife, Osun State, Nigeria
Iṣẹ́Make-up artist, and businesswoman
Olólùfẹ́Lanre Lawal
Websitebmpromakeup.com

Ó gba àmì ẹ̀yẹ Brand of the Year ní ọdún 2009 ní Eloy Awards, àti tí Nigerian Event Awards ní ọdún 2012 fún Best Makeup Artist àti Makeup Artist of The Year ní FAB AWARDS ní ọdún (2010).[2]

Ìbẹrẹ pẹpẹ Ayé

àtúnṣe

Wọn bí Banke Meshida sí Ile-Ife ni ìpínlẹ̀ Osun, ní gúúsù ìwọ oòrùn orílé èdè Nigeria[3] ní ilé ìwòsan tí yunifásítì Obafemi Awolowo tí wọn pé ní Obafemi Awolowo University Teaching Hospital. Banke Meshida beẹ̀rẹ̀ síní ṣé Fine Arts ní ilé ìwé gíga, [3]ṣùgbọ́n nígbà tí yóò fí wọ ilẹ ìwé gíga fásitì University of Lagos, ọ tí ń kò bí a tí ń ṣe Make-up fún àwọn ọrẹ àti ojúlùmò.[3] Ọ kà Èdè gẹ̀ẹ́sì (English) ọ sí gbọyè Second Class Bachelor's Degree ní ọdún 2000.[4]

Àwọn Àmì àti Ìdánimọ

àtúnṣe

Banke Meshida tí gbà àmi ẹ̀ye lórísiríri, àwọn náà sì ní Make-Up Artist of The Year (City People Awards 2005), Make-up Brand of The Year (ELOY Awards 2009),[5] Make-up Artist of The Year (FAB Awards 2010),[2] Best Make-up Artist (The Nigerian Event Awards 2012) àtiMakeup Brand of the Year (APPOEMN 2017).

Ìgbé ayé

àtúnṣe

Banke Meshida ṣé ìgbéyàwó pẹlu Lanre Lawal ní 10 February 2007.[6] Wọn sì ní ọmọ Méjì.[7]

Àwọn Itọkasi

àtúnṣe

Àdàkọ:Authority control