Bazin jẹ́ búrẹ́dì tí kò ní yeast nínú tí wọ́n máa ń ṣe ní Libya pẹ̀lú barley, omi àti iyọ̀.[1] Tí wọ́n bá fẹ́ se Bazin, wọ́n máa se ìyẹ̀fun nínú omí, tí wọ́n sì máa lù ú bí ẹni fẹ́ ṣe doughnut. Ohun èlò tí wọ́n fi máa ń lù ú ní magraf, èyí jẹ́ igi kan pàtàkì fún iṣẹ́ yìí.[2] Lẹ́yìn tí wọ́nbá ti lù ú tán, wọ́n máa gbe sí inú abọ́ kan, wọ́n sì máa fi sílẹ̀ kí ó le dáadáa,[3] lẹ́yìn náà ni wọ́n máa wá sè é jiná. Iyọ̀ tí wọ́n máa ń fi si náà máa ń dá kún líle rẹ̀. Bazin máa ń le lọ́wọ́. Yàtọ̀ aí èyí, wọ́n tún le lo ìyẹ̀fun ti wheat, òróró, àti ata láti fi sẹ̀ é.[3][4]

Bazin
Bazin (center) served with a stew and whole hard-boiled eggs.
Main ingredientsbarley, water and salt
Àdàkọ:Wikibooks-inline 

Wọ́n máa ń fi ata tomato, yin, Ọ̀dùnkún àti ẹran màlúù gbè é lẹ́gbẹ̀ẹ́, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti sè é tán. Ọ̀nà ìgbà se oúnjẹ yìí ní ṣe pẹ̀lú fífi búrẹ́dì náà ṣe àmì pyramid tàbí dome, lẹ́yìn tí wọ́n máa wá lo ọbẹ̀ tomato tàbí ọbẹ̀-ẹran tí wọ́n fi ọldùnkún sínú ẹ̀ àti ẹyin gbè é lẹ́gbẹ̀ẹ́. Bákan náà, wọ́n lè fi ẹyin síse sínú ọbẹ̀ gbígbóná náà. Aseeda jẹ́ oúnjẹ tí wọ́n máa ń fi bazin, oyin, date, bọ́tà àti òróró sè. Ohun mìíràn tí ó tún lè lọ pẹ̀lú Bazin ni úgú àti ọbẹ̀ tòmátò.

Tí wọ́n bá fẹ́ jẹ ẹ́, wọ́n le fi ọwọ́ fọ sí wẹ́wẹ́ kí wọ́n sì fi ọwọ́ jẹ ẹ́ bákan náà. ọwọ́ ọ̀tún ni wọ́n fi máa ń jẹ oúnjẹ yìí. Bazin jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oúnjẹ ìbílè ní Libya.

Ọbẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n lè fi ẹran màlúù se ọbẹ̀ Bazin pẹ̀lú àlùbọ́sà, ata ilẹ̀, iyọ̀, ata gígún, helba (fenugreek), sweet paprika, ata dúdú, àti tomato lílọ̀. Ẹ̀wà ńlá, lentils àti ọ̀dùnkún le wà nínú ọbẹ̀ náà. Ọbẹ̀ yìí, ẹyin, ọ̀dùnkún àti ẹran ni wọ́n máa tò káàkiri dough yìí.

Láyé àtijọ́, kì í ṣe bí wọ́n ṣe ń se bazin rè é, ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ ni wọ́n máa ń lò. Wọ́n máa kọ́kọ́ se dough ọ̀hún nínú pot kan tí wọ́n ń pè ní qidir. Tih ó bá sì ti le, wọ́n máa wá fọ wẹ́wẹ́ sínú pot náà, kí wọ́n tó sọ ọ́ di odinndin padà.

Ọ̀rọ̀

àtúnṣe

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Rozario, P. (2004). Libya. Countries of the world. Gareth Stevens Pub.. p. 40. ISBN 978-0-8368-3111-5. https://archive.org/details/libyaroza00roza. 
  2. Davidson, A.; Jaine, T.; Davidson, J.; Saberi, H. (2006). The Oxford Companion to Food. Oxford Companions. OUP Oxford. p. 1356. ISBN 978-0-19-101825-1. https://books.google.com/books?id=pZ-1AQAAQBAJ&pg=PT1356. 
  3. 3.0 3.1 Long, L.M. (2015). Ethnic American Food Today: A Cultural Encyclopedia. Rowman & Littlefield Publishers. p. 376. ISBN 978-1-4422-2731-6. https://books.google.com/books?id=DBzYCQAAQBAJ&pg=PA376. 
  4. Blady, K. (2000). Jewish Communities in Exotic Places. Jason Aronson, Incorporated. p. 327. ISBN 978-1-4616-2908-5. https://books.google.com/books?id=T0g2RsZI1yMC&pg=PA327. 

Àṣìṣe ìtọ́kasí: <ref> tag with name "Footprint" defined in <references> is not used in prior text.
Àṣìṣe ìtọ́kasí: <ref> tag with name "The Libyan Journal of Agriculture 1977" defined in <references> is not used in prior text.

Àṣìṣe ìtọ́kasí: <ref> tag with name "Grolier" defined in <references> is not used in prior text.