Beni Lar (tí a bí ní ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹjọ ọdun 1967) jẹ́ olóṣèlú ọmọ ẹgbẹ́ People's Democratic Party láti Ìpínlẹ̀ Plateau, Nàìjíríà. Ó jẹ́ asojú ìkọ̀ Langtang North àti Langtang South ti Ìpínlẹ̀ Plateau ní ilé ìgbìmò asofin kékeré.[1] A kọ́kọ́ yán sí ipò náà ní 2007, wọ́n sì tún dìbò yán ni ọdun 2019 fún sáà kẹrin ní ipò náà.[2]

Beni Lar
Aṣojú ilé ìgbìmò Asòfin kékeré ti Langtang North, Langtang South Federal Constituency of Plateau State
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbíAugust 12, 1967
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
Ẹgbẹ́ olóṣèlúPeople's Democratic Party (PDP)
Àwọn òbíSolomon Lar and Prof. Mary Lar
OccupationPolitician

Ìtàn ayé àti iṣẹ́ rẹ̀ àtúnṣe

Òun ni ọmọbìnrin àkọ́kọ́ Solomon Lar, Gómínà ìpínlẹ̀ Plateau tẹ́lẹ̀rí àti ọ̀jọ̀gbọ́n Mary Lar. Beni wípé,

“Bàbá mi kọ́ mi pé kò sí ìyàtọ̀ láàrin ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Ó kó mi láti jẹ́ onísẹ́ takuntakun; nítorí náà, mo gbìyànjú láti jẹ́ agbẹjọ́rò bi bàbá mi."[3]

Ó gba àwọn ọmọ Nàìjíríà níyànjú láti má gbàgbé isẹ́ takuntakun tí bàbá rẹ̀ se láti mú ìsokan, àlàáfíà àti ìfẹ́ wà, ó ní pe àwọn nkan yìí jẹ́ àwọn ǹkan tí ó se pàtàkì láti mú kí Nàìjíríà tẹ̀ síwájú.[4]

Ní ọdun 2007, a dìbò yán sí ilé ìgbìmò aṣòfin kékeré.[5] Ní ọdun 2008, ilé ìgbìmò asòfin yàn gẹ́gẹ́ bi alága ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kékeré lórí ọ̀rọ̀ obìnrin.[6]Títí di Oṣù Keje 2014, ó jẹ́ asojú Ikọ̀ Langtang North àti South. Ó tún jẹ́ Alága ilé ìgbìmò aṣòfin lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ènìyàn.[7][8]

Ó fọwọ́ sí fífi owó ran ààjọ National Agency for the Prohibition of Trafficking in Persons (NAPTIP) lọ́wọ́,[9] fífi owó líle òfin mú àwọn tí ó ń bá ọmọdé ṣe ǹkan àìtó[10] àti dídá ààjọ National Child Protection and Enforcement Agency kalẹ̀.[11]

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Lawmaker wants more funds for science and technology". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-10-20. Retrieved 2022-02-22. 
  2. "Beni Lar Returns to Reps in a Landslide". The Lagosian Magazine Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-03-01. Archived from the original on 2020-11-29. Retrieved 2020-02-24. 
  3. "The pillar of my life is gone, says Beni Lar". Vanguard News. 16 October 2013. http://www.vanguardngr.com/2013/10/pillar-life-gone-says-beni-lar/. 
  4. "Eight Months Later, Mrs Jonathan Promises To Stand By Lar's Widow". Information Nigeria. 24 June 2014. http://www.informationng.com/2014/06/eight-months-later-mrs-jonathan-promises-to-stand-by-lars-widow.html. 
  5. "Nigerian Women who will shape Seventh National Assembly". Nigeria Daily News. 6 July 2011. Archived from the original on 29 March 2014. Retrieved 18 July 2014. 
  6. Godwin, Ihemeje (August 2013). "The need for participation of women in local governance: A Nigerian Discourse". International Journal of Educational Administration and Policy Studies 5 (4): 59–66. https://files.eric.ed.gov/fulltext/EJ1084169.pdf. 
  7. Hamza Idris; Yahaya Ibrahim (15 July 2014). "Nigeria: 38 Killed As Boko Haram Attacks Borno Village". Daily Trust – AllAfrica. http://allafrica.com/stories/201407150905.html. 
  8. Murdock, Heather (28 April 2014). "Abuja Blast Impacts Lives, Livelihoods". Voice of America. Retrieved 18 July 2014. 
  9. "House committee seeks emergency funds for NAPTIP". P.M. NEWS Nigeria. 11 May 2014. http://www.pmnewsnigeria.com/2014/05/11/house-committee-seeks-emergency-funds-for-naptip/. 
  10. "House C'ttee on Health calls for amendment of law on child abuse". Radio Nigeria: News. Retrieved 18 July 2014. 
  11. "Establish Child Protection, Enforcement agency- Lar – Vanguard News". Vanguard News. 18 May 2014. http://www.vanguardngr.com/2014/05/establish-child-protection-enforcement-agency-lar/.