Betsy Heard (tí wọ́n bí ní1759, tí ó sì ṣaláìsí ní ọdún 1812) [1] jẹ́ obìnrin oníṣòwò ẹrú àti oníṣòwò ará Africa kan.

Bàbá rẹ̀ jẹ́ oníṣòwò kan tó máa ń rin ìrìn àjò ní àwọn ọdún 1700 láti Liverpool, lọ England, sí Los Islands, èyí tó wá di Guinea báyìí.[2] Ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Africa.[2] Ó ṣeé ṣe kí bàbá rẹ̀ tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀, èyí tó sọ pé àjèjì kan gbọ́dọ̀ fìdí ipò rẹ̀ múlẹ̀ láwùjọ nípa fífẹ́ ẹrú onílé tàbí ọmọbìnrin ẹrúbìnrin kan. [1]

Bàbá Heard ran lọ sí England, nítòsí Liverpool (níbi tí àwọn oníṣòwò ilẹl Africa máa ń pọ̀ sí, àti àwọn òǹtàjà tó jẹ́ ẹlẹ́yàméjì, tí wọ́n sì gbẹ̀kọ́ àwọn aláwọ̀ funfun[3] ). [1] [2] Nígbà tí ́ parí ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó padà lọ sí apá Ìwọ-oòrùn, ó sì ṣètò ilé-iṣẹ́ ìṣòwò kan, nítòsí Bereira River, láti tẹ̀lé òwò bàbá rẹ̀.[2] [4] Lákòótán, ó jogún òwò-ẹrú bàbá rẹ̀, àti àwọn àsopọ̀ tó ní.[1] Ní ọdún 1794, ó ti fìdi òwò rẹ̀ múlẹ̀, ní agbègbè náà, ó sì ni ọkọ̀ ojú-omi ní Bereira, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó wà fún títà, àti ilé-ikọjá-sí.[1] Àṣeyọrí yìí jẹ́ apá kan, nítorí àwọn Mùsùlùmí ti Jihad ní Futa Jallon; àwọn tí a ṣẹ́gun ti di ẹrú. Àwọn Mùsùlùmí gba Bereira fúnra wọn, ṣùgbọ́n èyí kò ní ipa búburú lórí ìṣòwò rẹ̀.[2] Ó dì gbajúmọ̀, bí ọbabìnrin odò, títí wọ òpin sẹ́ńtúrì náà.[2]


Gẹ́gẹ́ bí àlejò kan ṣe sọ, ó kọ́ ilé rẹ̀, ó sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́ ní àbámu pẹ̀lú àṣà àwọn ará Europe.[3] Ní ọdún 1807, ó kọ́ ilé mìírán.[3]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 Pechacek, Laura Ann (7 February 2008). Bonnie G. Smith. ed. The Oxford Encyclopedia of Women in World History. Oxford University Press. p. 442. ISBN 978-0195148909. https://books.google.com/books?id=EFI7tr9XK6EC&pg=RA1-PA442.  Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; name "Pechacek" defined multiple times with different content
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 2.5 Thomas, Hugh (16 April 2013). The Slave Trade: The Story of the Atlantic Slave Trade: 1440-1870. Simon and Schuster. p. 342. ISBN 9781476737454. https://books.google.com/books?id=lzuEzmO81GwC&pg=PA342.  Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; name "Thomas" defined multiple times with different content
  3. 3.0 3.1 3.2 Hughes, Sarah Shaver; Hughes, Brady (29 April 2015). Women in World History: V. 2: Readings from 1500 to the Present. Routledge. pp. 131–135. ISBN 9781317451822. https://books.google.com/books?id=Jru5CAAAQBAJ&pg=PA131.  Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; name "Hughes" defined multiple times with different content
  4. O. Collins, Robert; James M. Burns (8 February 2007). A History of Sub-Saharan Africa. Cambridge University Press. ISBN 978-0521867467.