Big Men jẹ́ fíìmù ọdún 2014, tí Rachel Boynton ṣe olùdarí fún. Fíìmù náà ṣe àgbéyẹ̀wò ìdókòwò epo-rọ̀bì, ìdàgbàsókè àwọn ẹ̀ka epo tuntun ní apá Ìwọ̀-oòrùn ilè Africa, àwọn ìwà òbàyéjẹ́ tó ń lọ níbẹ̀. Fíìmù náà jẹ mọ́ ìgbìyànjú ilé-iṣẹ́ Kosmos Energy láti ṣe ìdásílẹ̀ àgbéjáde epo rọ̀bì tuntun ní Ghana. Pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó tí wọ́n ti fẹ́ pàdánù, Kosmos tiraka pẹ̀lú àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ ní Ghana, àwọn onídòókòwò ní New York, pẹ̀lú ìbadàsẹ́yìn tó ń dé bá òwò epo rọ̀bì. Fíìmù náà wo Niger Delta, tó jẹ́ agbègbè tí epo rọ̀bì pọ̀ sí jù ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, níbi tí ìwà ìbàjẹ́ pọ̀ sí, tí wọn ò sí ní ìdàgbàsókè kankan tó ń dé bá epo rọ̀bì, àmọ́ tí wọ́n ń fẹ́ láti pín nínú èrè orí òwò náà. Wọ́n ṣe àgbéjáde fíìmù náà ní oṣù kẹta ọdún 2014.

Big Men
Fáìlì:File:Big Men poster.jpg
AdaríRachel Boynton
Olùgbékalẹ̀Rachel Boynton
Brad Pitt
Òǹkọ̀wéRachel Boynton
Àwọn òṣèréJim Musselman, Brian Maxted, George Osuwu, Jeffrey Harris
OrinNathan Larson
Ìyàwòrán sinimáJonathan Furmanski[1]
OlóòtúSeth Bomse[1]
Ilé-iṣẹ́ fíìmùGravitas Ventures
Boynton Films
Impact Partners
Screen Pass Pictures
Whitewater Films
BBC Films
Danish Broadcasting Corporation
Plan B Entertainment
Sundial Pictures
OlùpínAbramorama (United States)[2]
Déètì àgbéjáde
  • Oṣù Kẹta 14, 2014 (2014-03-14)[3]
Àkókò99 minutes
Orílẹ̀-èdèUS, UK, Denmark
ÈdèEnglish

Àgbéjáde

àtúnṣe

Wọ́n ya fíìmù náà láàárín ọdún 2007 wọ ọdún 2011, ní orílẹ̀-èdè Ghana àti Nigeria.[4]

Ìgbàwọlé

àtúnṣe

Big Men jáde sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àríwísí lọ́wọ́. Fíìmù yìí gba àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún ìgbóríyìn lórí Metacritic[2] àti Ọgọ́rùn-ún lórí Rotten Tomatoes.[5] Ní orí The New York Times, Jeannette Catsoulis kọ àyọkà kan láti gbóríyìn fún iṣẹ́ náà.[6] Lára àwọn oníròyìn mìíràn tó ṣe àríwísí fún fíìmù yìí ni Alan Scherstuhl ti The Village Voice [7], àti Stephanie Merry ní The Washington Post.[8]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 "Big Men The Movie: Filmmakers". Retrieved February 7, 2017. 
  2. 2.0 2.1 "Big Men Reviews". Metacritic. Retrieved February 7, 2017. 
  3. "Rachel Boynton". Variety. https://www.variety.com/exec/rachel-boynton. Retrieved February 7, 2017. 
  4. "Big Men The Movie". Retrieved February 7, 2017. 
  5. "Big Men (2014)". Rotten Tomatoes. 14 March 2014. Retrieved February 7, 2017. 
  6. Catsoulis, Jeannette (March 14, 2014). "Oil Money, and Where It Flows". The New York Times. https://www.nytimes.com/2014/03/14/movies/big-men-looks-at-ghanaian-oil-discovery.html?&_r=0. Retrieved February 7, 2017. 
  7. Scherstuhl, Alan (March 12, 2014). "Big Men Reveals How the World of Oil Actually Turns". The Village Voice. http://www.villagevoice.com/film/big-men-reveals-how-the-world-of-oil-actually-turns-6441243. Retrieved February 7, 2017. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  8. Merry, Stephanie (March 27, 2014). "'Big Men' movie review: Pandora's Box filled with black gold in Africa". The Washington Post. https://www.washingtonpost.com/goingoutguide/movies/big-men-movie-review-pandoras-box-filled-with-black-gold-in-africa/2014/03/26/ecdf71ec-b049-11e3-a49e-76adc9210f19_story.html. Retrieved February 7, 2017.