Binta Masi Garba
Binta Masi Garba (Wọ́n bí i lọ́jọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹrin ọdún 1967) jẹ́ gbajúmọ̀ oselu, pàràkòyí oníṣòwò àti àti aṣàkóso, tí ó jẹ́ aṣòfin-àgbà tí ó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò apá àríwá ní Ìpínlẹ̀ Adamawa láti ọdún 2025. Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́-òṣèlú All Progressives Congress, APC, bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ alága Ìpínlẹ̀ fún gbajúmọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú tí àjọ Independent National Electoral Commission fọwọ́ sí lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1]
Binta Masi Garba | |
---|---|
Senator of the Federal Republic of Nigeria | |
In office June 2015 – June 2019 | |
Asíwájú | Bindo Jibrilla |
Arọ́pò | Ishaku Elisha Abbo |
Constituency | Adamawa North |
Representative, Federal House of Representative | |
In office 1999–2011 | |
Constituency | Adamawa North |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 17 Oṣù Kẹrin 1967 Kaduna, Nigeria |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | All Progressives Congress (APC) |
Àwọn ọmọ | 3 |
Alma mater | Harvard University, Kaduna Polytechnic |
Nickname(s) | Iron Lady, Lady B and BMG |
Lọ́dún 1999 sí 2011, Binta jẹ́ ọmọ aṣojúṣòfin, House of Representatives, ní ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.[2][3] Ó jẹ́ ọmọbìnrin àkọ́kọ́ tí ó ṣojú ẹkùn ìdìbò ìjọba àpapọ̀ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣojúṣòfin lọ́dún 2009, Wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí igbá-kejì fún àjọ Commonwealth Women Parliamentarians (CWP), lábẹ́ àjọ Commonwealth Parliamentary Association (CPA) ni orílẹ̀ èdè Cameroon, bákan náà, ó jẹ́ obìnrin kan ṣoṣo tí ó ṣojú Ìpínlẹ̀ Adamawa ní àpérò, National Conference ní Abuja.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Muhammad, Muhammad K. (2009-06-13). "My father was IBB's driver —Hon. Binta Masi Garba". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-10-07.
- ↑ Assembly, Nigerian National. "National Assembly - Federal Republic of Nigeria". www.nassnig.org. Retrieved 9 July 2017.
- ↑ "Binta Masi Garba: The story of first female party chairperson". Dailytrust.com.ng. 2014-05-25. Archived from the original on 2 April 2015. Retrieved 2017-07-09. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)