Bukky Ajayi

Òṣéré orí ìtàgé

Zainab Bukky Àjàyí (2 Osù Keèjì 1934 – 6 Osù keèje 2016) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]

Bukky Ajayi
Fáìlì:Bukky Ajayi.jpg
Bukky Ajayi ninu ere
Ọjọ́ìbí(1934-02-02)Oṣù Kejì 2, 1934
AláìsíJuly 6, 2016(2016-07-06) (ọmọ ọdún 82)
Surulere, Ipinle Eko, Naijiria
Orílẹ̀-èdèNaijiria
Orúkọ mírànZainab Bukky Ajayi
Iṣẹ́osere
Ìgbà iṣẹ́1966–2014

Ìgbé ayé àti iṣẹ́ rẹ̀ àtúnṣe

Bukky Àjàyí ní a bí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣùgbọ́n ó parí ẹ̀kọ́ gíga rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè England, United Kingdom pẹ̀lú àtìlẹyìn síkọ́láshípù ìjọba àpapọ̀ kan. Ní ọdún 1965, ó kúrò ní England wá sí Nàìjíríà níbití iṣẹ́ rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi oníròyìn fún Nigerian Television Authority ní ọdún 1966.[2] Ó ṣe àkọ́kọ́ fiimu rẹ̀ nínu eré tẹlifíṣọ́nù "Village Headmaster" ní àwọn ọdún '70s ṣáájú kí ó tó lọ kópa nínuCheckmate, eré tẹlifíṣọ́nù Nàìjíríà kan tí wọ́n gbé síta ní àkókò ìgbẹ̀yìn àwọn ọdún 1980 sí ìbẹ̀rẹ̀ àwon ọdún 1990

Ní àkókò iṣẹ́ ìṣe eré rẹ̀, ó ṣe ìfihàn nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fiimu tó pẹ̀lú Critical Assignment, Diamond Ring, Witches làárín àwọn míràn. Ní ọdún 2016, àwọn ìlọ́wọ́sí rẹ̀ sí iṣẹ́ fiimu ti Nàìjíríà sokùn fa n tí wọ́n fi fun òun àti Sadiq Daba ní ẹ̀bun Industry Merit Award níbi ayẹyẹ 2016 Africa Magic Viewers Choice Awards.[3][4]

Àkójọ eré rẹ̀ àtúnṣe

Fiimu
Ọdún Fiimu Ipa Àfikún
2013 Mother of George gẹ́gẹ́ bi Ma Ayọ̀ Balógun dídarí eré látọwọ́ Andrew Dosunmu
2009 Bolode O'ku
Òréré Layé
2008 Amoye
Iya Mi Tooto
2007 A Brighter Sun ó hàn níbi gbogbo àwọn ẹ̀yà
Big Heart Treasure
Fine Things
Keep My Will
2006 Women of Faith
2005 Bridge-Stone
Destiny's Challenge
Women's Cot ó hàn níbi gbogbo àwọn ẹ̀yà
2004 Indecent Girl gẹ́gẹ́ bi Mrs. Orji ó hàn níbi gbogbo àwọn ẹ̀yà
Little Angel
Obirin Sowanu
Temi Ni, Ti E Ko ó hàn níbi gbogbo àwọn ẹ̀yà
Worst Marriage
2003 The Kingmaker
My Best Friend
2001 Saving Alero
Thunderbolt
2000 Final Whistle ó hàn níbi gbogbo àwọn ẹ̀yà
Oduduwa
1998 Diamond Ring
Witches gẹ́gẹ́ bi ìya Desmond
1997 Hostages
1989 – 1991 Checkmate
Village Headmaster

Ikú rẹ̀ àtúnṣe

Àjàyí kú ní ìbùgbe rẹ̀ ní Surulere, Ìpínlẹ̀ Èkó ní ọjọ́ 6, oṣù keèje ọdún 2016 ní ọmọ ọdún 82.[5][6]

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe