CACovid jẹ́ àjọ tí àwọn oníṣòwò àti ilé-iṣẹ́ aládàáni dá sílẹ̀ láti ṣègbè fún ìgbógun tí àjàkálẹ̀ àrùn ẹ̀ràn kòrónà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1]

Àwọn pàràkòyí oníṣòwò bíi Àlíkò Dàńgótè, Fẹ̀mi Ọ̀tẹ́dọlá, ọ̀pọ̀ àwọn olówó mìíràn àti àwọn ilé-iṣẹ́ ńlá-ńlá ní wọ́n gbìmọ̀pọ̀ dá àjọ yìí sílẹ̀ láti ṣe ìkówójọ fún àjọ ìjọba àpapọ̀, tí ó ń ṣe kòkárí fún ìgbógun tí àjàkálẹ̀ àrùn coronavirus, Nigeria Centre for Disease Control, NCDC. Wọn dá CACOVID sílẹ̀ lọ́dún 2020 ni Naijiria [2] Lọ́wọ́lọ́wọ́, ẹgbẹlẹmùkú owó ni wọ́n tí kó jọ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ìjọba-àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti gbógun ti jíjàkálẹ̀ àrùn coronavirus

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Published (2015-12-15). "CACOVID: Nigeria private sector operators unite against coronavirus". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-15. 
  2. "Contributions to CACOVID relief fund hit N15 billion". TVC News Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-05-03. Archived from the original on 2020-07-18. Retrieved 2020-04-15.