Celestial Church of Christ
Benin - batism ceremony in Cotonou.jpg
The Celestial Church of Christ tí a tún mọ̀ sí Ìjọ Mímọ́ ti Kristi(CCC) jẹ́ ilé-ìjọsìn tí Samuel Oshoffa dá sílẹ̀ ní Áfríkà ní ọjọ́ 29 oṣù kẹsàn-án ní ìlú Porto-Novo, nih Benin.[1] Ó wà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé pẹ̀lú Orílẹ̀ èdè America àti àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ ní Africa.[2]
Ìtàn
àtúnṣeOshoffa tí a bí sí Dahomey ní ọdún 1909 fìgbà kan jẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà tí ó ti di Benin báyìí.[3] Ìjọ Methodist ni ó dàgbà sí. Ó ní ìṣípayá àtọ̀runwá nígbà tí ó sọnù sínú igbó ní ọjọ́ 23 oṣù karùn-ún, ọdún 1947 tí ìṣẹ̀lẹ̀ eclipse ṣẹ̀. Ó nímọ̀lára láti gbàdúrà, láti mú àwọn aláìsàn lára dá, àti láti jí àwọn òkú dìde. Ó dá ìjọ rẹ̀ sílẹ̀ ní oṣù kẹsàn-án, ọdún 1947.[4] Lẹ́yìn tí ó ti yan ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì, Olùṣọ́-àgùtàn, àti Olùdásílẹ̀. Ipò tí ó ga jù lọ ni ó wà nígbà náà.[3]
CCC gba ìdánimọ̀ àti àṣẹ láti tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ wọn láti ọwọ́ orílẹ̀-èdè Dahomey ní ọdún 1965. Láti ọdún 1976, ìjọ náà bẹ̀rẹ̀ ìpolongo ìhìnrere ní orílẹ̀-èdè yẹn, tó fìgbà kan jẹ́ French West Africa, tó ti gba òmìnira ní ọdún 1960. Láti òpin ọdún 1960, ìjọ náà bẹ̀rẹ̀ sí ní lo ẹ̀rọ-ayélujára fún ìpolongo ìhìnrere, èyí sì mú kí ìbánisọ̀rọ̀ wà láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka ìjọ náà tó ti wà ní ìdásílẹ̀ káàkiri ilẹ̀ òke-òkun tí ọmọ Africa wà, bíi United Kingdom, Germany, Austria, France àti United States. Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni ìjọ yìí gbajúmọ̀ sí.[5]
Lẹ́yìn ikú Oshoffa, ìjọ náà ń tẹ̀síwájú, àmọ́ kò ṣàìrí àwọn ìdojúkọ kọ̀ọ̀kan, èyí tó wọ́ pọ̀ jù lọ ní ọ̀rọ̀ olórí àti adarí ìjọ náà lẹ́yìn ikú Oshoffa.[6] Lẹ́yìn Bàbá Oshoffa, Alexander Abiodun Adebayo Bada ló jẹ́ adarí ìjọ náà títí di ìgbà ikú rẹ̀ ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹsàn-án, ọdún 2000.[7] Lẹ́yìn náà ni Philip Hunsu Ajose gorí ipò náà fún ìgbà díẹ̀, torí ikú rẹ̀ ní oṣù kẹta, ọdún 2001. Awuyewuye ṣẹlẹ̀ lórí arọ́pò Ajose. Àwọn ọ̀wọ́ ènìyàn kan kéde Gilbert Oluwatosin Jesse gẹ́gẹ́ bíi olórí tuntun, nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ Reverend Emmanuel Oshoffa, tí ó jẹ́ ọmọ Samuel Oshoffa Bada bíi olórí tuntun.[8] Lẹ́yìn ikú Jesse, ẹgbẹ́ rẹ̀ polongo pé Ajíhìnrere Gíga Jù Lọ Paul Suru Maforikan ni aṣáájú ẹ̀mí tuntun ti ìjọ. Ní ìlòdì sí ìlànà ìtẹ́lọ́rún ní Naijiria, Porto-Novo tó jẹ́ olú ilé-ìjọsìn gíga jù lọ, yan Benoit Agbaossi (1931–2010) láti jẹ olórí ilé-ìjọsìn, ẹni tí ó wá yan Benoit Adeogun ní àkókò tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Olùṣọ́-àgùtàn láìpẹ́, kí ó tó kú ní ọdún 2010.
Iwe akosile
àtúnṣe- (in French) Pierre Ndjom, Lumière sur l'Eglise du Christianisme Céleste, Paris (France), 2016, 283 p. ISBN 978-2-9557548-0-1
- (in French) Apollinaire Adetonah, Lumière sur le Christianisme Céleste, 1972, 85 p.
- (in French) Christine Henry, Pierre-Joseph Laurent and André Mary, « Du vin nouveau dans de vieilles outres : parcours d'un dissident du Christianisme Céleste (Bénin) », in Social Compass, 2001, vol. 48, no 3, pp. 353–68
- (in French) Christine Henry, La force des anges : rites, hiérarchie et divination dans le Christianisme Céleste, Bénin, Brepols, Turnhout (Belgique), 2008, 280 p. (ISBN 978-2-503-52889-2)
- (in French) Codjo Hébert Johnson, Le syncrétisme religieux dans le golfe du Bénin : le cas du 'Christianisme céleste' , Université Panthéon-Sorbonne, Paris, 1974, 139 p.
- (in French) Joël Noret, « La place des morts dans le christianisme céleste », in Social compass, 2003, vol. 50, no 4, pp. 493–510
- (in French) Laurent Omonto Ayo Gérémy Ogouby, « L'Église du christianisme céleste », in Les religions dans l'espace public au Bénin: vodoun, christianisme, islam, L'Harmattan, Paris, 2008, pp. 46–48 (ISBN 978-2-296-06111-8)
- (in French) R. Saint-Germain, « Les chrétiens célestes, description d'une Église indépendante africaine: Questions d'éthique en sciences des religions », in Religiologiques (Montréal), 1996, vol. 13, pp. 169–94
- (in French) Codjo Sodokin, Les 'syncrétismes' religieux contemporains et la société béninoise: Le cas du christianisme céleste, Université Lumière, Lyon, 1984, 306 p.
- (in French) Albert de Surgy, L'Église du Christianisme Céleste: Un exemple d'Église prophétique au Bénin, Karthala editions, 2001, 332 p. (ISBN 2845861303)
- (in French) Claude Wauthier, « L'Église du christianisme céleste », in Sectes et prophètes d'Afrique noire, Seuil, Paris, 2007, chapter XV, p. 227 and f. (ISBN 9782020621816)
- Afeosemime U. Adogame, Celestial Church of Christ: the politics of cultural identity in a West African prophetic-charismatic movement, P. Lang, Francfort-sur-le-Main, New York, P. Lang, 1999, 251 p.
- (in English) Edith Oshoffa, The Enigmatic spiritual leader of our time S.B.J. Oshoffa: Celestial Church of Christ Beulah Parish, 1st Edition April 2014, Edith Oshoffa, (ISBN 9789789378692)
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Adetonah, A. (1972) (in French). Lumière sur le Christianisme Céleste. pp. 85.
- ↑ "Le Christianisme Céleste en France et en Belgique". Cairn. Retrieved 2 August 2010.
- ↑ 3.0 3.1 Crumbly, Deidre Helen (2008). Spirit, Structure, and Flesh: Gendered Experiences in African Instituted Churches Among the Yoruba of Nigeria p. 54 on. University of Wisconsin Press. pp. 182. ISBN 978-0-299-22910-8. https://books.google.com/books?id=olMmvHsB-C4C&dq=Samuel+Bilehou+Oshoffa&pg=PA54. Retrieved 7 April 2017.
- ↑ Partridge, Christopher (2004). New Religions A Guide.New York: Oxford. ISBN 978-0-19-522042-1.
- ↑ Obafẹmi Kẹhinde Olupọna, Jacob; Rey, Terry (2008). Òrìşà devotion as world religion: the globalization of Yorùbá religious culture. Univ of Wisconsin Press. pp. 257–58. ISBN 978-0-299-22464-6. https://books.google.com/books?id=QlW3ZMxrCKMC&pg=PA257.
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ "Celestial signs lighten Bada's burial". The Comet. Celestial Church. 2 October 2000. Archived from the original on 1 October 2011. Retrieved 2011-06-12. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Yemi Akinsuyi (11 October 2003). "Celestial Church: Oschoffa Renews Call for Peace". ThisDay. Archived from the original on 1 October 2011. Retrieved 12 June 2011. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)