Benin (pípè /bɨˈnɪn/) tàbí Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Benin jẹ́ orílẹ̀-èdè ní Ìwọ̀orùn Áfríkà. Ó ní bodè pẹ̀lú Togo ní apá ìwọòrùn, Nàìjíríà ní apá ìlaòrùn, àti Burkina Faso àti Nijẹr ní àríwá. Ní gúúsù ó jásí Etíòkun Benin (Bight of Benin).

Republic of Benin
Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Benin
République du Bénin
Àsìá Àmì ọ̀pá àṣẹ
Motto"Fraternité, Justice, Travail"  (French)
"Fraternity, Justice, Labour"
Orin-ìyìn orílẹ̀-èdèL'Aube Nouvelle  (French)
The Dawn of a New Day

OlúìlúPorto-Novo1
6°28′N 2°36′E / 6.467°N 2.6°E / 6.467; 2.6
ilú títóbijùlọ Cotonou
Èdè àlòṣiṣẹ́ Faransé
Orúkọ aráàlú Ará Benin
Ìjọba Oselu egbe oloselu pupo
 -  Aare Yayi Boni
Òmìnira kúrò lọ́wọ́ Fransi 
 -  Ọjọ́ August 1,1960 
Ààlà
 -  Àpapọ̀ iye ààlà 112622 km2 (101st)
43484 sq mi 
Alábùgbé
 -  Ìdíye July 2005 84390002 (89th)
 -  2009 census 6769914 
 -  Ìṣúpọ̀ olùgbé 75/km2 (118th3)
194/sq mi
GIO (PPP) ìdíye 2008
 -  Iye lápapọ̀ $13.014 billion[1] (140th)
 -  Ti ẹnikọ̀ọ̀kan $1,605[1] (166th)
GIO (onípípè) Ìdíye 2008
 -  Àpapọ̀ iye $6.940 billion[1] 
 -  Ti ẹnikọ̀ọ̀kan $856[1] 
Gini (2003) 36.5 (medium
HDI (2007) 0.437 (low) (163rd)
Owóníná West African CFA franc (XOF)
Àkókò ilẹ̀àmùrè WAT (UTC+1)
 -  Summer (DST) not observed (UTC+1)
Ìwakọ̀ ní ọwọ́ otun
Àmìọ̀rọ̀ Internet .bj
Àmìọ̀rọ̀o tẹlifóònù 229
1 Cotonou is the seat of government.
2 Estimates for this country explicitly take into account the effects of excess mortality due to AIDS; this can result in lower life expectancy, higher infant mortality and death rates, lower population and growth rates, and changes in the distribution of population by age and sex than would otherwise be expected.
3 Rank based on 2005 estimate.

Itobi re ko fi be ju 110000 km2 lo pelu arabudo to fe e to 8,500,000. Botileje pe oluilu re je Porto Novo ibujoko ijoba wa ni Kútọnu.

Leyin ijoba oloselu lati 1960 de 1972, ijoba Marxist-Leninist je lati 1972 titi de 1991, ijoba yi se inira pupo, o si se idabaru inadura. Bere lati odun 1991, awon idiboyan egbe oloselupupo ti n waye.

OrukoÀtúnṣe

"Benin" gege bi oruko re ko ni ohunkohun se pelu Ilẹ̀ọba Benin tabi Ilu Benin ni Naijiria. Oruko re tele je Dahomey (Dan-ejo (snake),Homey-Ilu tabi Ile,Ilu awon ejo) ki a to yi si Orile-ede Olominira Omoilu ile Benin ni odun 1975 nitori pe egbe odo to wa un je Etiodo Benin. Won mu oruko yi nitoripe ko fi s'egbe kan larin gbogbo awon eya eniyan bi adota ti won wa ni ile Benin. Dahomey je oruko iluoba Fon ti ayeijoun, nitori eyi won ro pe ko to.

ÌtànÀtúnṣe

Ile-Oba Dahomey je didasile lat'owo awon orisirisi eya ni Abomey. Awon akọ̀tàn ro pe boya aisi abo ti owo eru dasile ni o fa ogunlogo ero eniyan lati ko lo si Abomey, larin won ni a ti ri Aja, awon omo eya Gbe ti awon akotan nigbagbo pe awon ni won se idasile ilu na. Ibasepo larin awon eya Aja ati eya Fon to fa idasile eya titun ti a mo si "Dahomey".

Igbagbo ni pe awon Gbe wa lati Wyo. Gangnihessou ni o koko je oba ni Ile-Oba Dahomey. Asa jagunjagun won je ki won fe bode tobi pelu oluilu ni Abomey.

ÌṣèlúÀtúnṣe

Iru iselu je ti opolopo egbe oloselu ti won yan awon asoju pelu aare abasewa nibiti Aare ile Benin, ti se Yayi Boni lowolowo bayi, je olori orile-ede ati olori ijoba. Agbara iseoba wa lowo ijoba. Agbara isofin wa lowo ijoba ati ile asofin. Ile Adajo ni ominira lowo ijoba ati asofin. Iru ona iselu lowolowo bayi bere ni 1990 pelu Ofinigbepo ile Benin ati iyipada si ti oloselu ti o tele ni odun 1991.

Awon ipinle ijobaÀtúnṣe

AliboriAtakoraAtlantiqueBorgouCollinesDongaKouffoLittoralMonoOuéméPlateauZou 
Àwọn ìpínlẹ̀ ìjọba Benin

Ile Benin je pinpin si apá mejila (French: départements), awon wonyi si tun je pinpin si ibile 77. Ni odun 1999 ni won pin awon apa ijoba abele mefa to wa tele si mejila.

 1. Alibori
 2. Atakora
 3. Atlantique
 4. Borgou
 5. Collines
 6. Donga
 7. Kouffo
 8. Littoral
 9. Mono
 10. Ouémé
 11. Plateau
 12. Zou

Jẹ́ọ́gráfìÀtúnṣe

Benin je ile san lati Ariwa de Guusu ni ilaoorun Afrika, o dubule larin Agbedeméjì ayé (Equator) ati Ìlà-ooru Alákàn (Tropic of Cancer). Ìlàìdùbúlẹ̀ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti 6°30′A dé 12°30′A, bẹ́ ẹ̀ sì ni ìlàìnàró rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti 1°L dé 3°40′L.

Pelu agbegbe ile to to 112622 km2 Benin fe lati Odò Niger ni ariwa titi de Okun Atlantiki ni guusu, ijinnasi to je 650 km (400 mi). Botilejepe ni iwon ile eba odo re je 121 km (75 mi) iwon ile orile-ede na ni ibi totifeju je 325 km (200 mi).

Ikan ninu awon orile-ede tokerejulo ni Iwoorun Afrika ni Benin. O kere ni ilopo mejo si Naijiria to ni bode mo si ilaoorun. Sugbon o tobi ni ilopo meji si Togo to ni bode mo si iwoorun. Maapu ile Benin fihan pe awon oke re ko fi be yato si ara won (idasarin awon oke re je 200 m).[2]

A le pin oril-ede na si apa merin lati gusu de ariwa. Ibi ẹ̀kun omi irele, oniyanrin (igbeleke togajulo 10 m) je, lopojulo, 10 km ni fife. O je ile erofo to ni awo adagun odo ati osa ti won japo mo okun. Awon ilegiga apagusu Benin (igasoke larin 20 m ati 200 m) pinya si ra won nitori awon afonifoji to la koja lati ariwa de gusu legbe awon odo Couffo, Zou, and Oueme.

IsunaÀtúnṣe

Isuna ile Benin je ti alaidagbasoke, o si gbojule ise agbe aroje, ogbin owu ati okowo agbegbe. Owu tita lo je 40% GDP ati bi 80% ipawo oja okere iseoba.[3] Idagbasoke eso-ise dasarin 5% ni bi odun meje seyin, sugbon iposi iyearabudo ko je ki iposi yi o ni ipa kankan. Igbowolori (owon) ti din sile ni bi odun melo se yin. CFA franc ni owonina ile Benin.


DimográfìÀtúnṣe

 
Maapu Bénin

Ogunlogo iyearabudo ile Benin n gbe ni gusu. Won je ọ̀dọ́, pelu àsìkò ìgbẹ̀mí to je odun 59. Awon eya ede Afrika bi 49 lo wa ni Benin; awon wonyi tedo kakiri. Awon eya ede yi ni Yoruba ni gusuilaoorun (ti won wa lati Naijiria ni odunrun 12la); Dendi ni agbegbe ariwa-arin (won kowa lati Mali ni orundun 16un); Bariba ati Fulbe ni ariwailaoorun; Betammaribe ati Somba ni Atacora Range; Fon ni ayika agbegbe Abomey ni Arin Gusu; ati Mina, Xueda, ati Aja (ti won wa lati Togo) ni ekun odo.[2]

Fon ni eya ede topojulo pelu 1.4 legbegberun iyearabudo to n so ede Fon, Yoruba tele won pelu 1.2 legbegberun, Aja (600,000), Bariba (460,000), Ayizo (330,000), the Fulbe (tabi Fulani, Peul ati Fula) (310,000), ati awon Gun (240,000). Bakanna ni leba awon ebute ni gusu a le ri awon omo-omo awon eru ti won kopada wa lati Brasil. Bakanna die tun wa lati ile Europe, agaga awon ara Fransi ati awon eniyan lati apaariwa Asia bi Lebanon ati Ilaoorun Asia bi India.

EsinÀtúnṣe

Gege bi onka 2002 se fihan, 42.8% je Elesin Kristi (27.1% je Katholiki, Selestial 5%, Methodisti 3.2%, other Protestanti 2.2%, awon miran 5.3%), 24.4% je Musulumi, 17% je Elesin ibile, 15.5% awon miran.[4]

ÈdèÀtúnṣe

Ede iseoba je Faransé sugbon sibesibe awon ede abinibi bi Fon ati Yoruba na tu gbajumo agaga ni apa gusu. ni apa ariwa awon ede bi bariba ati fula gbajumo.

Awon eya eniyanÀtúnṣe

99% je àwon omo Afrika (Yoruba, Fon, Aja, Bariba at.bb.lo), awon omo Europe ko ju 10,000 lo.

Ilera ati itojuÀtúnṣe

Ni arin ewaodun '80, awon omo ile Benin ti won le gba itoju ilera to yeke din ni 30% iyearabudo, nitori eyi Benin ni ofo omode togajulo ni Afrika. Leyin Idawose Bamako iyato to dara sele, eyi si je ki ipese ilera o wa fun opo awon iyearabudo.[5][6]

IkekoÀtúnṣe

Ikeko ko pondandan be si ni ki se ofe.[7] Bakanna awon odomokunrin poju awon odomobirin lo ni ile eko. Ipin awon akeko si awon oluko posoke lati 36:1 ni 1990 de 53:1 ni 1997. Aimookomooka je 60% awon iyearabudo.[8].

Sistemu EkoÀtúnṣe

Awon akoko ti ile-eko kookan n gba[9]

 • Ile-eko Alakobere: odun 6
 • Ile-eko Keji kekere: odun 4
 • Ile-eko Keji agba: odun 3
 • Iwe-eri Barchelor: odun 3
 • Iwe-eri Master: odun 4ItokasiÀtúnṣe

 1. 1.0 1.1 1.2 1.3 "Benin". International Monetary Fund. Retrieved 2009-04-22. 
 2. 2.0 2.1 "Background Note: Benin". U.S. Department of State (June 2008). Àyọkà yìí mú ìkọ̀wé láti orísun yìí tí ó wà ni ìgboro.
 3. Background Note: Benin
 4. International Religious Freedom Report 2007: Benin. United States Bureau of Democracy, Human Rights and Labor (14 Osu kesan, 2007).
 5. "Bamako Initiative revitalizes primary health care in Benin". Retrieved 28-12-2006.  Check date values in: |access-date= (help)
 6. "Implementation of the Bamako Initiative: strategies in Benin and Guinea". Retrieved 28-12-2006.  Check date values in: |access-date= (help)
 7. "Benin". Findings on the Worst Forms of Child Labor (2001). Bureau of International Labor Affairs, Ile-ise Alakoso Ikeko ile Amerika (2002).
 8. Education: Programs. USAID Benin
 9. Eto Eko ni Orile-ede Benin. Ile-ise Alasoju ile Amerika, Κutonu