Chelsea Eze (tí a bí gẹ́gẹ́ bi Chelsea Ada Ezerioha ní 15 Oṣù kọkànlá) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó di gbajúmọ̀ pẹ̀lú kíkópa nínu àkọ́kọ́ fíìmù rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Silent Scandals ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Genevieve Nnaji àti Majid Michel.[2] Fún ipa rẹ̀ nínu fíìmù náà, ó gba àmì ẹ̀yẹ òṣèré tí ó ní ìlérí jùlọ níbi ayẹyẹ 6th Africa Movie Academy Awards .

Chelsea Eze
Ọjọ́ìbíChelsea Ada Ezerioha
15 November [1]
Kano State
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iléẹ̀kọ́ gígaYunifásítì ìlú Màídúgùri
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́2009–present

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

A bí Chelsea ní Ìpínlẹ̀ Kánò ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọmọ ìran ti Umuahia, Ìpínlẹ̀ Ábíá. Òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ ní àwon òbí rẹ̀ méjéèjì. Ó lọ ilé-ìwé Federal Government Girls College àti St.Louis Secondary School ní ìlú Kánò. Ó kẹ́kọ̀ọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní Yunifásítì ìlú Màídúgùri. Gẹ́gẹ́bi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò rẹ̀ kan pẹ̀lú ìwé ìròyìn The Punch, ó wípé ìgbà èwe òun dùn gan nítorípé ìlú Kánò kún fún àlááfíà nígbà náà.[3]

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀

àtúnṣe

Ṣááju kíkópa rẹ̀ nínu eré Silent Scandals, ó jẹ́ afẹwàṣiṣẹ́, kò sì tíì ma ṣe iṣẹ́ òṣèré àyàfi àwọn eré orí ìpele tí ó ṣe ní ilé ìjọsìn. Ṣíṣe iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Vivian Ejike ránṣẹ́ pèẹ́ láti wá ṣe àyẹ̀wò fún ipa amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fún ti eré Silent Scandals. Láti ìgbà náà, ó ti kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù míràn bíi Two Brides and a Baby (2011), Hoodrush (2012) and Murder at Prime Suites (2013).[4][5]

Àkójọ àwọn eré rẹ̀

àtúnṣe
Ọdún Fíìmù Ipa Àwọn àkọsílẹ̀
2009 Silent Scandals Ella with Genevieve Nnaji
2011 Two Brides and a Baby Ugo With OC Ukeje, Kalu Ikeagwu and Stella Damasus
Twist
Timeless Passion
2012 Hoodrush Shakira with Bimbo Akintola, OC Ukeje & Gabriel Afolayan
Closed Door
Laugh won kill me die
The Kingdom
Tears of Passion
2015 Ikogosi Emem with IK Ogbonna

Àwọn ìyẹ́sí

àtúnṣe
Ọdún Àmì ẹ̀yẹ Ẹ̀ka Fíìmù Èsì
2010 Africa Movie Academy Awards Most Promising Talent Silent Scandals Gbàá
Best of Nollywood Awards Most Promising Talent Wọ́n pèé
Revelation of the Year Gbàá
ZAFAA Awards Best Upcoming Actress Gbàá
2011 Best of Nollywood Awards Best Actress in a Supporting Role (English) Two Brides and a Baby Wọ́n pèé
2013 Nollywood Movies Awards Best Actress in a Supporting role Hoodrush Wọ́n pèé

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Chelsea Eze Birthday". nollywoodmindspace.com. Retrieved 17 April 2014. 
  2. "Fame has Pain- Chelsea Eze". punchng.com. Archived from the original on 19 April 2014. Retrieved 17 April 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "Most Nigerian Men arent Romantic". punchng.com. Archived from the original on 27 November 2013. Retrieved 17 April 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "Kid to Watch - Chelsea Eze". thenetng. Archived from the original on 15 April 2014. Retrieved 17 April 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. "Chelsea Eze on iMDb". imdb.com. Retrieved 17 April 2014.