Ìpínlẹ̀ Abia
Ìpínlẹ̀ Abia (Igbo: Ȯha Abia) jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ní agbègbè gúúsù-ìlà-oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó pín ààlà sí àríwá àti àríwá-ìlà-oòrùn pẹ̀lú àwọn Ìpínlẹ̀ Enugu, àti Ebonyi, Imo State sí ìwọ̀-oòrùn, ìpínlẹ̀ Cross River sí ìlà-oòrùn, ìpínlẹ̀ Akwa Ibom sí gúúsù-ìlà-oòrùn, àti ní ìpínlẹ̀ Rivers sí gúúsù. Tí wọ́n sọ lórúkọ látara ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ orúkọ àwọn agbègbè mẹ́rin tí ó pọ̀ jùlọ ní ìpínlẹ̀ náà: Aba, Bende, Isuikwuato, àti Arochukwu.[3] Olú-ìlú rẹ̀ ni Umuahia tí agbégbè tí ó gbòòrò jùlọ tí ó sì lajú jẹ́ Aba.[4]
Ìpínlẹ̀ Ábíá | |
---|---|
Nickname(s): God's Own State / Ulo Chi/Chukwu in Igbo Language. | |
Ibudo ni Naijiria | |
Orile-ede | Nigeria |
Oluilu | Umuahia |
Ijoba Ibile | 17 |
Idasile | 27 August 1991 |
Government | |
• Gomina | Okezie Ikpeazu(People Democratic party) |
• Awon Alagba | Eyinnaya Abaribe, Uche Chukwumerije, Nkechi Justina Nwaogu |
• Awon aranise Ile-igbimo Asofin | Akojo |
Area | |
• Total | 6,320 km2 (2,440 sq mi) |
Population (2006 ikaniyan)[1] | |
• Total | 2,833,999 |
Time zone | UTC+0 (GMT) |
Geocode | NG-AB |
GIO (2007) | $18.69 billion[2] |
GIO ti Enikookan | $3,003[2] |
Ede ibise | Igbo Geesi |
Website | www.abiastateonline.com/ |
Ìpínlẹ̀ Abia jẹ́ ìpínlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejìlélọ́gbọ̀n tí ó gbòòrò jùlọ ní ààyè tàbí agbègbè àti ẹlẹ́ẹ̀kẹtàdínlọ́gbọ̀n ní iye pẹ̀lú ènìyàn tí ó tó mílíọ́nnù mẹ́rindínlọ́gọ́rùn-ún-lọ́nà-igbalélọ́gọ́rin gẹ́gẹ́ bí àbájáde ọdún 2016.[5]
Lóde-òní àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Abia láti bí ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kúnfún àwọn oríṣiríṣi ẹ̀yà, ṣùgbọ́n àwọn Igbo ni wọ́n gbilẹ̀ jù nínú àwọn olùgbé yìí.
Ní ti ètò ọrọ̀-ajé, iṣẹ́ wíwa epo àti ohun àlùmọ́nì gáààsì ni ó jẹ́ gbòóógì ní ìpínlẹ̀ Abia pẹ̀lụ́ iṣẹ́ àgbẹ̀, nípàtàkì iṣu, àgbàdo, taro, epo pupa, àti pákí. Ilé-iṣẹ́ kékeré kan ń ṣàgbéjáde, pàápàá jùlọ ní agbègbè Aba.[6] Tí ó sì ń gbèrú kíákíá ní iye àti ní Ilé-iṣẹ́, Abia ní ìsopọ̀-ẹlẹ́ẹ̀kẹ́jọ atọ́ka ìdàgbàsókè ènìyàn tó ga jùlọ lórílẹ̀ èdè.[7]
Àwọn Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀
àtúnṣeAwon eeyan pàtàkì
àtúnṣeItokasi
àtúnṣeWikimedia Commons ní àwọn amóunmáwòrán bíbátan mọ́: Ìpínlẹ̀ Abia |
- ↑ Federal Republic of Nigeria Official Gazette (15 May 2007). "Legal Notice on Publication of the Details of the Breakdown of the National and State Provisional Totals 2006 Census" (PDF). Archived from the original (PDF) on 2007-07-04. Retrieved 2007-05-19.
- ↑ 2.0 2.1 "C-GIDD (Canback Global Income Distribution Database)". Canback Dangel. Retrieved 2008-08-20.
- ↑ "History of Abia State Nigeria" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-09-18. Retrieved 2021-09-18.
- ↑ "Aba | History & Facts | Britannica". www.britannica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-03-12.
- ↑ "Figure 1. Map of abia State showing the 17 local government areas.". ResearchGate (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-03-12.
- ↑ "Abia". Encyclopædia Britannica. Retrieved 14 December 2021.
- ↑ "Human Development Indices". Global Data Lab. Retrieved 15 December 2021.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |