Chioma Okoye
Chioma Okoye jẹ́ òṣèré, ònkọ̀wé àti agbéréjáde tí ó wá láti ìlú Aguleri-Otu, èyí tí ó n bẹ ní ìjọba agbègbè ti Ìwọ-òòrùn Anámbra, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó ti kópa nínu fíìmù Nollywood tó lé ní 100 láti ìgbà tí ó ti bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2002.[1] Lẹ́hìn gbígba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àmì-ẹ̀yẹ, [2] Chioma ti di àwòkọ́ṣe nínu ìdi-iṣẹ́ fíìmù Nollywood. Ó jẹ́ aláàkóso Purple Ribbon Entertainment. [3]
Chioma Okoye | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 3 Oṣù Keje 1983 Kaduna, Naijiria |
Orílẹ̀-èdè | Naijiria |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Naijiria(1983–iwoyi) |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Yunifásítì ìlú Èkó |
Iṣẹ́ | Osere |
Ìgbà iṣẹ́ | 2002-iwoyi |
Website | purpleribbonentertainment.com |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeA bí Chioma ní ìlú Kàdúná níbi tí ó dàgbà sí pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀.[4] Orúkọ ìyá rẹ̀ n jẹ́ Òkóyè Nàómì, bẹ́ẹ̀ ṣì ni orúkọ bàbá rẹ̀ (olóògbé) jẹ́ Alàgbà Joseph Òkóyè, eni tí ó kú ní Oṣù Kẹẹ̀rin Ọjọ́ Ọgbọ̀n, Ọdún 2013. Chioma lọ sí ilé-ìwé Faith Nursery and Primary school ní Ìpínlẹ̀ Kàdúná àti Christ the King Seminary Nnobi ni Ìpínlẹ̀ Anámbra. Lẹ́hìn náà, ó lọ sí Yunifásítì ìlú Èkó níbití ó ti kẹ́ẹ̀kọ́ Ìtàn-àkọọ́lẹ̀.[5]
Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀
àtúnṣeChioma bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ṣíṣe nípasẹ̀ Pete Edochie tí ó jẹ́ àbúrò bàbá/ìyá rẹ̀. Ó rí ànfàní yìí ní ìgbà kan tí ó tẹ̀lé Pete Edochie lọ sí ibi tí wọ́n gbé ṣe ìpèsè eré. Ipa àkọ́kọ́ rẹ̀ wáyé nínu fíìmù No Shaking, èyítí ó ṣe ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré bíi Victor Osuagwu àti Sam Loco Efe. Lẹ́hìn náà ló tún kópa nínu eré Nothing Spoil pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Chinedu Ikedieze, Osita Iheme, àti Uche Ogbuagu. Ó gbé àkọ́kọ́ fíìmù rẹ̀ jáde tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Aso-Ebi Girls.[6] Lẹ́hìn tí ó ti hàn nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù tó lórúkọ, ṣíṣe ìfihàn nínu fíìmù Abuja Connection (2003) mú ìrànlọ́wọ́ bá òkìkí rẹ̀ nídi iṣẹ́ fíìmù.[7][8]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
àtúnṣeỌdún | Àkọ́lé | Ipa | Àwọn àkọsílẹ̀ |
---|---|---|---|
2003 | Slow Poison (Agala) | ||
Drummer Boy | |||
2004 | Abuja Connection | ||
True Romance | |||
2005 | Too Late | ||
2013 | Aso-ebi girl | ||
Prof and Den Gun | |||
The World Richest Family |
Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀
àtúnṣeỌdún | Ẹ̀yẹ | Ẹ̀ka | Èsì |
---|---|---|---|
2007 | African Youth Awards | Òṣèré tí ó dára jùlọ lédè Gẹ̀ẹ́sì | Gbàá |
2004 | City People awards for Excellence | Òṣèré tí ó dára jùlọ | Gbàá |
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Chioma Okoye". mcomet. mcomet. Archived from the original on 7 March 2014. Retrieved 8 February 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Chioma Okoye". nigeriadailynews. nigeriadailynews. Archived from the original on 27 March 2011. Retrieved 17 February 2011.
- ↑ "Chioma Okoye’s got Selling Points". Nollywoodwatch. WatchMan. Archived from the original on 10 June 2008. Retrieved 8 June 2008. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Chioma Okoye’s typical DAY". Punchng. Nonye Ben-Nwankwo and Ademola Olonilua. Archived from the original on 11 January 2014. Retrieved 11 January 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Chioma Okoye’s note to Jonathan". Indepthnigeria. Bimbo. Archived from the original on 2 March 2014. Retrieved 22 April 2011.
- ↑ "Chioma Okoye comes calling with "Aso-Ebi Girls"". Vanguardngr. Ayo Onikoyi. Retrieved 11 May 2013.
- ↑ "The World’s Richest Family From Purple Ribbon Entertainment". Ogus Baba Blog. ChicBenita. Retrieved 13 August 2013.
- ↑ "Chioma Okoye’s note to Jonathan". Vanguardngr. Vangurdngr. Retrieved 22 April 2011.