Osita Iheme
Osita Iheme, MFR tí wọ́n bí ní ogúnjọ́ oṣù kejì ọdún 1982 (February 20, 1982) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó di gbajúmọ̀ òṣèré ìlúmọ̀ọ́kà tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí "Pawpaw" látàrí ipa tó kó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá-ìtàn Pawpaw nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń Aki na Ukwa pẹ̀lú Chinedu Ikedieze. Òun ni olùdásílẹ̀ Inspired Movement Africa, èyí tí ó dá sílẹ̀ láti ṣe móríyá fún àwọn màjèsín àti ọ̀dọ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Áfíríkà lápapọ̀.
Osita Iheme MFR | |
---|---|
Iheme at the 2014 Africa Magic Viewers Choice Awards | |
Ọjọ́ìbí | 20 Oṣù Kejì 1982 Mbaitoli, Imo, Nigeria |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Naijiria |
Ẹ̀kọ́ | ìjìnlẹ̀ kọ̀m̀pútà,Lagos State University |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Lagos State University |
Iṣẹ́ | Actor |
Lọ́dún 1988, Iheme gba àmì ẹ̀yẹ Lifetime Achievement Award, èyí tí African Movie Academy Awards fún un.[1] Wọ́n kà á sí ọ̀kan nínú àwọn òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó gbajúmọ̀ jùlọ.[2]
Lọ́dún 2011, ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà ìṣèjọba Ààrẹ Goodluck Jonathan fún un ní àmì ìdálọ́lá ọmọ ẹgbẹ́ ọlọ́lá Order of the Federal Republic (MFR). [3]
Ìgbà èwe
àtúnṣe[4][5] Ó jẹ́ ọmọ bíbí Mbaitoli ní ìpínlẹ̀ Ímò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ṣùgbọ́n ìpínlẹ̀ Abia ló gbé dàgbà, ó sìn kàwé gbàwé ẹ̀rí dìgírì nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kọ̀m̀pútà ní ifáfitì Lagos State University.[6]
Àtòjọ àwọn sinimá-àgbéléwò rẹ̀
àtúnṣe
|
|
|
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Coker, Onikepo (4 May 2007). "Africa Celebrates Film Industry at AMAA 2007". Mshale Newspaper (Minneapolis, USA: Mshale Communications). Archived from the original on 3 March 2012. https://web.archive.org/web/20120303204433/http://www.mshale.com/article.cfm?articleID=1407.
- ↑ Muchimba, Helen (23 September 2004). "Nigerian film lights Zambia's screens". BBC News (London, UK: BBC). http://news.bbc.co.uk/2/hi/africa/3674322.stm.
- ↑ "BN Bytes: Genevieve Nnaji, Stephanie Okereke, Amaka Igwe, Aliko Dangote & Jim Ovia receive National Honours – Photos from the Ceremony". bellanaija.com. Retrieved 24 September 2014.
- ↑ M'bwana, Lloyd. "Who is older between Aki and Paw Paw?? As Aki celebrates his 41st birthday". www.maravipost.com. Retrieved 11 September 2019.
- ↑ Adikwu, Marris (14 August 2019). "The Nigerian Film Stars Behind Some of Twitter’s Greatest Memes". Vulture. https://www.vulture.com/2019/08/osita-iheme-chinedu-ikedieze-twitter-memes.html. Retrieved 13 September 2019. "Don’t be fooled by Iheme and Ikedieze’s size — they’re both grown men (Iheme is 37 and Ikedieze is 41)."
- ↑ Cornel-Best, Onyekaba (6 May 2005). ".DYNAMITES. That's what we are". Daily Sun (Lagos, Nigeria). Archived from the original on 10 May 2005. https://web.archive.org/web/20050510225149/http://sunnewsonline.com/webpages/features/showtime/2005/may/06/showtime-06-05-2005-001.htm. Retrieved 5 September 2010.