Christie Ade Ajayi (tí a bí ní ọdún 1930) jẹ́ akọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ nínú ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ fún àwọn ọmọdé ti Nàìjíríà. O jẹ́ onkòwé onírúurú ìwé èdè gẹ̀ẹ́sì fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, ó si ri gẹ́gẹ́ bí ojúṣe láti máa kọ àwọn ìtàn tí Nàìjíríà tí kìí ṣe àjòjì sí àwọn onkàwé rẹ̀. Pẹ̀lú ìrírí ọjọ́ pípẹ́ nínú iṣẹ́ olùkó tí ó ní, ó tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ aláápọn fún oríṣiríṣi ẹgbẹ́ tí ètò ẹ̀kọ́ ọmọdé àti àwọn ọmọdé jẹ́ lógún.

Ìgbésí Ayé Rẹ̀

àtúnṣe

A bí Christie Aduke Martins ní ọjọ́ kẹtẹ̀lá oṣù Kẹta Ọdún 1930 ní Ile Oluji, ní Ìpínlẹ̀ Ondo, Christie Ade Ajayi (tí a tún le kọ bí Ade-Ajayi) lọ si Ilé-ẹ̀kọ́ Àwọn ọmọbìnrin ti Kudeti ni Ìlú Ìbàdàn (èyí tí a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ilé ìwé St. Anne báyìí ) o tún lọ sí Ilé Ìwé Olùkọ́ Gíga tí United Missionary, ní Ìlú Ìbàdàn níbi tí o ti kẹ́kọ̀ọ́ láti jẹ́ olùkọ́. [1] O tún kẹ́kọ̀ọ́ ni Ìlú Lọ́ndọ̀nù ní Froebel Institute [2] àti ní Ilé Ìwé Gíga fún Ìdánílẹ́kọ̀ọ́ níbi tí o ti gba ìwé ẹ̀rí fún ẹ̀kọ́ gíga nínú ẹ̀kọ́ Ìdàgbàsókè Ọmọ ni ọdún 1958. [1] Láàárín ọdún 1952 sí ọdún 1978, ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ ni ọpọlọpọ àwọn ilé ìwé ní Nàìjíríà àti ọ̀kan ní Ìlú Lọ́ndọ́nù, ó si di olórí ilé -ẹ̀kọ́ Gíga.[3] Ó tún lọ si Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga ti Ìpínlẹ̀ San Jose, California níbi tí o ti gba ìwé ẹ̀rí ní Ìṣàkóso Ilé Ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti Alákóso ni ọdún 1971. [1] Ó fẹ́ JF Ade Ajayi ní ọdún 1956, ó ṣí bí ọmọ márùn-ún pẹ̀lú. [4] Ọ̀rẹ́ ẹbí wọn kan ti ṣapejuwe “ìwà ọ̀yàyà rẹ̀” àti “ilé tí ń gbani lálejò” ti ìdílé rẹ̀.[5]

Àwọn Ìtọ́kási

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 Otokunefor, Henrietta C. (1989). Nigerian Female Writers: A Critical Perspective. pp. 99–100. https://books.google.com/books?id=xbcyAAAAIAAJ. 
  2. Fayose, Philomena Osazee Esigbemi (1995). Nigerian Children's Literature in English. https://books.google.com/books?id=XuTyAAAAMAAJ. 
  3. Ifaturoti, Kunle (1994). To Have and to Hold: Salute to Forty Years of Married Life. https://books.google.com/books?id=iBEOAQAAMAAJ. 
  4. Bown, Lalage (September 10, 2014). "JF Ade Ajayi obituary". The Guardian. https://www.theguardian.com/books/2014/sep/10/jf-ade-ajayi. 
  5. Peel, J. D. Y. (2015). "J. F. Ade Ajayi: A Memorial". Africa 85 (4): 745–749. doi:10.1017/S0001972015000571. https://dx.doi.org/10.1017/S0001972015000571.