Colin Powell
Colin Luther Powell ti won bi (ọjọ́ìbí 5 April, 1937 - Oṣu Kẹwa ọjọ 18, ọdun 2021) jẹ́ ẹni àyẹ́sí ọmọ ilẹ̀ Améríkà àti Ọ̀gágun oníràwò mérin to ti fèyìntì kúrò ní Ilé-isé Ológun Jagunjagun ilè Améríkà. O tun jé Alákòso Òrò Òkèrè ilè Améríkà láti 2001 - 2005 lábé Ààrẹ George W. Bush. Ohun ni ẹni aláwòdúdú àkókó ti yio gun orí ipò yi.[1][2][3][4] Nígbàtí wa ni ẹnu isé ológun, Powell tún je Alábàágbìmọ̀pọ̀ Ọ̀rọ̀ Àbò Orílẹ́-èdè ile Améríkà (National Security Advisor, 1987-1989); Apèse, Ilé-isé Alase àwọn Ológun Jagunjagun ilè Améríkà (U.S. Army Forces Command, 1989); àti Alaga Ijokopápo àwọn Ògá Ọmọ-ológun ilè Améríkà (Chairman, U.S. Joint Chiefs of Staff, 1989-1993), orí ipò yi lówà nígbàtí Ogún Ikùn Odò Persia selè. Ohun ni o jẹ́ ẹni aláwòdúdú àkókó, àti soso títí dòní, ti yio kópa nínú Ijokopapo àwọn Ògá Ọmọ-ológun ilè Améríkà (Joint Chiefs of Staff).
Ọ̀gágun Colin Luther Powell | |
---|---|
65th Alakoso Oro Okere ile Amerika | |
In office January 20, 2001 – January 26, 2005 | |
Ààrẹ | George W. Bush |
Deputy | Richard Armitage |
Asíwájú | Madeleine Albright |
Arọ́pò | Condoleezza Rice |
12th | |
In office October 1, 1989 – September 30, 1993 | |
Ààrẹ | George H. W. Bush Bill Clinton |
Deputy | Robert T. Herres (1989) David E. Jeremiah (1989-1993) |
Asíwájú | William J. Crowe |
Arọ́pò | David E. Jeremiah |
16th | |
In office 1987–1989 | |
Ààrẹ | Ronald Reagan |
Deputy | John Negroponte |
Asíwájú | Frank Carlucci |
Arọ́pò | Brent Scowcroft |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 5 Oṣù Kẹrin 1937 New York City, New York, U.S.A. |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | Republican |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Alma Vivian Johnson Powell |
Alma mater | City College of New York George Washington University |
Profession | Soldier Statesman |
Military service | |
Allegiance | United States of America |
Branch/service | Army |
Years of service | 1958-1993 |
Rank | General |
Unit | 3rd Armored Division Americal Division |
Commands | Forces Command |
Battles/wars | Vietnam War Invasion of Panama Gulf War |
Ìgbà èwe
àtúnṣeA bí Colin Luther Powell ni ọjọ́ 5 osù kerin odún 1937 ní Harlem to jẹ àdúgbò kan ní ìlú New York fún Luther Theophilus Powell àti Maud Arial McKoy ti wọn ko wá sílè láti ilè Jamaika. O si dàgbà ní South Bronx. Apá àwọn òbí re kan tún wa láti ilè Skotlandi àti Irelandi. Powell lo si ilé èkó Morris High School to fi ìgbà kan jẹ ti ìgboro ní Bronx, o parí níbẹ̀ ní 1954.
Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ní Ilé-iṣẹ́ Ológun
àtúnṣePowell darapo mo Reserve Officers' Training Corps ni ilè èkó City College ní New York o si sàlàyé re léyìn ìgbà na gẹ́gẹ́ bi ìrírí tí o mu inu re dunjulo laye re, pe ohun ti ri ohun ti ohun fẹ́ràn tí ohun si mọ̀ọ́ ṣe, lókàn re pe "öhun ti wa ara ohun ri." Gẹ́gẹ́ bi Kèdẹ́ẹ̀tì, Powell darapò mo ẹgbẹ́ àwọn Ayìnbọn Pershing ní City College. Nígbàtó parí èkó re ní City College ní 1958, ó gbà ipò gẹ́gẹ́ bi igbákẹ̀ta ajagun ní Ilé-isé Ológun Jagunjagun ilè Améríkà (second lieutenant, United States Army).[5] Òṣìṣé ọmọ-ogun lo jẹ fún odún 35, o di orísirísi Ilé-isé apèse àti ipò alábàṣiṣépò mú títí to fi gòkẹ̀ dè ipò Ògágun ní 1989.[6]
Ọjọ́ọdún tó dé àwọn ipò rẹ̀
àtúnṣe- Igbákẹta Ajagun (Second Lieutenant): June 9, 1958
- Igbákejì Ajagun (First Lieutenant}: December 30, 1959
- Ajagun Ile-ise Ologun Jagunjagun ile Amerika (Captain, U.S Army): June 2, 1962
- Àgbàogun (Major): May 24, 1966
- Igbákejì Akógun (Lieutenant Colonel): July 9, 1970
- Akógun (Colonel): February 1, 1976
- Ọ̀gágun Ẹlẹ́ẹ̀ṣọ́ (Brigadier General): June 1, 1979
- Ọ̀gágun Àgbàogun (Major General): August 1, 1983
- Igbákejì Ọ̀gágun (Lieutenant General): March 26, 1986
- Ọ̀gágun (General): April 4, 1989
Okùn | Ipò | Ọjọ́ọdún |
---|---|---|
ỌGG-GEN | 1989 | |
IỌG-LTG | 1986 | |
ỌA-MG | 1983 | |
ỌẸ-BG | 1979 | |
AKO-COL | 1976 | |
IAK-LTC | 1970 | |
AO-OMAJ | 1966 | |
AJA-CPT | 1962 | |
2AJA-1LT | 1959 | |
3AJA-2LT | 1958 |
Àwọn Ebun àti eye
àtúnṣeAwọn ìlẹ̀máyà
àtúnṣeAlábàágbìmọ̀pọ̀ Ọ̀rọ̀ Àbò Orílẹ́-èdè
àtúnṣeNigbato di omo odun 49, Powell di Alábàágbìmọ̀pọ̀ Ọ̀rọ̀ Àbò Orílẹ́-èdè fún Àare Ronald Reagan lati 1987 titi di 1989 lai fi ipò re sílè gẹ́gẹ́ bi igbákejì ògágun (lieutenant general). Nígbàtó parí isé Ìgbìmò Òrò Àbò ilè Améríkà, Powell gbà ìgbésókè si ipò Ògágun lábé Àare George H.W. Bush, o si ṣiṣé nígbà die gẹ́gẹ́ bi Alásẹ, Ilé-isé Apèse àwọn Ológun Jagunjagun ilè Améríkà, to un mójútó gbogbo Ológun Jagunjagun, Ológun Jagunjagun Alágbẹ́pamó, àti àwọn ẹyo Ilé-isé Ológun Olúsọ́ ilè Améríkà (U.S. National Guard) fun orile Améríkà, Alaska, Hawaii àti Puerto Rico.
Alága Ijókopapo àwọn Oga Omo-ologun
àtúnṣeÀfúnse isé ológun to se gbèyìn, láti October 1, 1989 títí di September 30, 1993 ní gẹ́gẹ́ bí Alága ìkejìlá Ijókopapo àwọn Ògá Ọmọ-ológun, èyí ni ipò ológun tógajúlo ní Ilé-isé Alákòso Òrò-àbò ilè Améríkà (U.S. Dept. of Defense).
Itokasi
àtúnṣe- ↑ The first Áfríkà Améríkà secretary of state, Colin Powell Archived 2008-06-04 at the Wayback Machine., The African American Registry
- ↑ Biographies - Colin Powell: United States Secretary of State, African American History Month, US Department of Defense
- ↑ Colin Powell, Britannica Online Encyclopedia
- ↑ Profile: Colin Powell, BBC News
- ↑ "Secretary of State Colin L. Powell (biography)". The White House. 2003-04-29. Retrieved 2007-02-03.
- ↑ "Colin (Luther) Powell Biography (1937 - )". The Biography Channel. A&E Television Networks. Archived from the original on 2007-08-07. Retrieved 2007-05-31.
Ìwé kíkà lẹ́kùnréré
àtúnṣe- Powell, Colin A. and Joseph Persico, My American Journey, Ballantine Books, 1995. ISBN 0-345-40728-8
- Excerpts from My American Journey, Archived 2013-08-25 at the Wayback Machine. Time, September 18, 1995
- DeYoung, Karen, Soldier: The Life of Colin Powell, Alfred A. Knopf, 2006. ISBN 1-4000-4170-8
- "Alex Haley’s Other Roots: African-Americans with Irish Ancestors". February 25, 2006. Archived from the original on 2006-04-14. Retrieved 2008-02-22.
Fídíò
àtúnṣe- Address to the National Summit on Africa Archived 2011-04-15 at the Wayback Machine. - Washington, DC - February, 2000 - Technical Note: playback requires Flash 10 Player
Àwọn Ìjápò Íntérnétì
àtúnṣeWikimedia Commons ní àwọn amóunmáwòrán bíbátan mọ́: Colin Powell |
- Colin Powell: America's Best Leaders from US News & World Report
- Remarks to the United Nations Security Council, February 5, 2003
- Complete text, audio, video of Colin Powell's Remarks to the UN Security Council AmericanRhetoric.com
- "Colin Powell On the issues"
- African Americans in the U.S. Army
- "Curveball" Revelations Indicate falsified info used to start Iraq war and esp used for Powell's UN presentation on Iraq WMDs
- Colin Powell Quotes
- The American Presidency Project: Remarks on the Retirement of General Colin Powell in Arlington, Virginia, September 30, 1993
- Àdàkọ:Worldcat id