Dele Momodu

Oníwé-Ìròyín
(Àtúnjúwe láti Délé Mọ́mọ́dù)

Olóyè Délé Mọ́mọ́dù èyí ti orúkọ àpèjá àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ Ayòbámidélé Àbáyọ̀mí Ojútẹlẹ́gàn Àjàní Mọ́mọ́dù, (tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù karùn-ún ọdún 1960, 16th May, 1960) jẹ́ gbajúmọ̀ akọrọ̀yìn, oníṣòwò àti asọ̀rọ̀ṣínilọ́yẹ̀ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Òun ni olórí àti olùdásílẹ̀ ìwé-ìròyìn olóṣooṣù àwọn aláfẹ́ ní Nàìjíríà àti ní gbogbo àgbáyé, Ovation International. Lọ́dún 2015, ó dá ilé-iṣẹ́ tẹlifíṣàn sílẹ̀ tí ó pè ní l Ovation TV àti ìwé-ìròyìn ayélujára tí ó The Boss. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmìn ẹ̀yẹ ni Mọ́mọ́dù tí gbà nínú iṣẹ́ rẹ̀ lágbo òṣèlú, okowò, ìṣe-ọ̀nà lítíréṣọ̀, ìmúra àti lágbo fàájì, pàápàá jùlọ orin. Òun ni ó máa ń kọ abala kan tí ó pè ní "Pendulum" lọ́sẹ̀ọ̀sẹ̀ nínú ìwé-ìròyìn This Day. Nínú abala yìí ni ó ti máa ń kọ̀wé awíkoko lójú ọlọ́rọ̀ lórí ètò òṣèlú àti àwọn nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́́lọ́wọ́. [1] [2]

Dele Momodu
Ọjọ́ìbí16 Oṣù Kàrún 1960 (1960-05-16) (ọmọ ọdún 64)
Ile-Ife, Nigeria
Iléẹ̀kọ́ gígaObafemi Awolowo University
Iṣẹ́Journalist/ceo
Ìgbà iṣẹ́Publishing 1996–present

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Campbell, Mike. "Yoruba Names". Behind the Name. Retrieved 2020-02-18. 
  2. "Dele Momodu: An African Icon At 50! By Kayode Mallami". Sahara Reporters. 2013-06-17. Archived from the original on 2013-06-17. Retrieved 2020-02-18.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)