Dénrelé Adémikìtán Ọbasá

Denrelé Adémikìtàn Ọbasá (1878-1948), jẹ́ ọmọ bíbí Ilé-Ifẹ̀ àmọ́ tí ó fi Ìlú Èkó ṣe ibùgbé. Ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn akéwì ilẹ̀ Yorùbá lásìkò ọdún 1920s. Òun ni olóòtú àgba fún ìwé -ìròyìn ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, tí ó ń gbé jáde pẹ̀lú èdè orísi méjì, tí ìwé-ìròyìn náà sì jẹ́ ẹkejì irú rẹ̀ tí yóò ma sọ̀ròyìn lédè abínibí. [1]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Dénrelé ní ìlú Ilé-Ifẹ̀, àmọ́ tí ó fi Ìlú Èkó ṣe ibùgbé. Ó fìgbà kan ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí kanlé kanlé ṣáájú kí ó tó kọ́ṣẹ́ ìwé títẹ̀ tí ó sì tún dara pọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé Paterson Zochonis. Ọbasá padà dá ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé tirẹ̀ sílẹ̀ tí ó pè ní Ìlàre. Ilé iṣèẹ́ ìtẹ̀wé rẹ̀ yí ni ó fun ní ànfàní láti tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ oníyebíye rẹ̀ jáde pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Lára àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tó lààmì laka ní:

  • Àwọn Akéwì (ewì).

Àwọn Ìtọ́ka sí

àtúnṣe