Damba: Ọdún Damba
Ọdún Ìbílẹ̀ Damba jẹ́ ọdún ìbílẹ̀ tí ó tóbi jù ní orílẹ̀ èdè Ghana, èyí tí àwọn ará Ìwọ̀ àríwá, ìlà Òòrùn Northern, Savanna, North East, Upper East àti apá ìlà Ìwọ̀ oòrùn Upper West ti àgbègbè Ghana.[1] Nígbà díẹ̀ sẹ́yìn, Damba ti di ọdún ìbílẹ̀ ti gbogbo orílẹ̀ èdè èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlejò láti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn ń rọ́ wá láti wò. Ọdọọdún ni wọ́n ń ṣe ọdún ìbílẹ̀ yìí ní àwọn orílẹ̀ èdè Germany, USA, and UK.[2][3][4]
Láti inú Dagbani ní orúkọ Damba ti ṣẹ̀wá. Lára àwọn ẹ̀dá èdè náà ni Damma láti inú èdè Mampruli àti Jingbenti láti inú èdè Waali. Ní oṣù Damba, oṣù kẹta ti kalẹ́ńdà Dagomba ni wọ́n máa ń ṣe ayẹyẹ ọdún Damba. Ìdí tí wọ́n fí ń ṣàjọyọ̀ ọdún ìbílẹ̀ yìí ni láti ṣayẹyẹ ohun ìní iyebíye wọn, ìtàn àti ìjòyè ti Dagbon àti àwọn ìjọba tó yí wọn ká. Dagbon jẹ́ ibi ìbí tí ó ṣakópọ̀ ìjọba, ìjòyè àti àwọn ìdílé tí ń jọba ní orílẹ̀ èdè Ghana àti Burkina Faso. Oṣù Damba tún papọ̀ mọ́ oṣù kẹta ti kalẹ́ńdà àwọn Mùsùlùmí, Rabia al-Awwal. Ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣàjọyọ̀ ọdún Damba ni láti ṣayẹyẹ ìbí àti ìsọlórukọ ti Muhammad, ṣùgbọ́n ìdí ayẹyẹ náà ti yí padà láti máa ṣe ìgbéga ohun ìní wọn àti ìjòyè. Ọdún ayẹyẹ Damba yìí tún ni àwọn ara Gonjas ti àgbègbè Savanna ti gbà gẹ́gẹ́ bí ayẹyẹ wọn. Àwọn ará Gonja ní oṣù pàtó èyí tí wọ́n máa ń ṣajoyọ̀ ayẹyẹ yìí. Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n pín ayẹyẹ yìí sí ni; ti Somo Damba, ti Naa Damba (ọba) àti ti Belkulsi (àkókò ìdágbére).
Ìṣe Ayẹyẹ Náà
àtúnṣeAyẹyẹ náà yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìkéde ti ìbéèrè oṣù láti ọwọ́ Yidan Moli, sí àwọn ará Yaa Naa. Ní ọjọ́ kọkànlá oṣù náà, “Somo” Damba yóò bẹ̀rẹ̀ , ‘Naa’ (àwọn ọba) Damba yóò sì tẹ̀le ní ọjọ́ kẹtàdínlógún. Wọ́n yóò wá fi “bielkulsi” parí ,[5] èyí tí ó jẹ́ òtéńté ayẹyẹ náà, tí yóò sì parí ni ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Damba.[6] Ní àkókò yìí ni wọn yóò ṣe ọ̀pọ̀ àdúrà sí àwọn bàbá ńlá wọn, ìlù lílù àti ijó jíjó, àwọn ìdílé yóò sì máa bẹ àwọn ọ̀rẹ́ wọ́n wò pẹ̀lú ẹ̀bùn.[7] Lára ayẹyẹ náà tún ni Binchera Damba, níbi tí àwọn ọ̀dọ́ yóò ti wọ àwọn aṣọ tó ti ṣá ṣùgbọ́n tí ó gbóge, àti Shinkaafa Gahimbu (ṣíṣa ìrẹsì)
Yila Bohambu (ìgbáradì fún orin kíkọ)
àtúnṣeAlẹ́ ni wọ́n máa ṣe ìgbáradì sílẹ̀ fún kíkọ àwọn orin Damba, àwọn ọmọọ̀dọ̀ obìnrin láàfin, káàkiri ààfin pàtàkì pàtàkì Dagbon àti ìjọba tó yi ká ni wọ́n yóò máa darí àwọn orin náà. Èyí yóò wáyé ní àwọn ọjọ́ mẹ́wàá àkọ́kọ́ oṣù náà.
Binchera Damba
àtúnṣeÈyí jẹ́ ìṣafíhan aṣọ tó ti ṣá pẹ̀lú ijó jíjó. Káàkiri àwọn ààfin ni èyí tí máa ń wáyé. Àwọn ọ̀dọ́ sì ni olùkópa pàtàkì níbẹ̀.
Somo Damba
àtúnṣeÈyí níṣe pẹ̀lú àdúrà gbígbà àti ijó jíjó.
Shinkaafa Gahimbu
àtúnṣeÈyí níṣe pẹ̀lú ṣíṣa ìrẹsì. Ó tún níṣe pẹ̀lú àwọn àlùfáà ti ìgbìmọ̀, èyí tí àwọn Yidan Moli ti ààfin Gbewaa yóò darí.
Nahu Glibu
àtúnṣeKíkó àwọn màlúù jọ, àwọn ìjòyè ni yóò ṣe èyí.
Naa Damba
àtúnṣeDamba ti ọba lèyí. Ó níṣe pẹ̀lú ijó jíjó àti ọ̀pọ̀ ìwọ́de ti ẹṣin.
Belkulsi (ìdágbére)
àtúnṣeÌwọ́de àti ìdágbére aláfẹfẹ aláràbarà.
Damba ọdún 2023
àtúnṣeAyẹyẹ ti ọdún 2023 wáyé lọ́nà tí wọ́n kò lérò, ó wáyé láàárín oṣù kẹsàn-án sí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kẹwàá. Òtéńté rẹ̀ (Bielkulsi) yẹ kó wáyé lọ́jọ́ kẹrin oṣù kẹwàá, ọdún 2023. Àwọn ìlú mìíràn ṣe ayẹyẹ ìdágbére tiwọn nínú òjò. Síbẹ̀síbẹ̀, nítorí òjò ńlá tó rọ̀, ìwọ́de tó yẹ kó wáyé láàfin Gbewaa, ni wọ́n sún di Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹwàá, ọdún 2023. Àwọn àlejò àti àwọn tí ń ṣayẹyẹ káàkiri gbogbo àgbéyè ni wọ́n rọ́ lọ sí àwọn ààfin àti gbọ̀ngán káàkiri orílẹ̀ èdè Ghana fún ayẹyẹ aláràbarà yìí. Àwọn ènìyàn pàtàkì pátákí láti orílẹ̀ èdè Togo náà wà lórí ìjókòó ni ààfin the Gbewaa fún ayẹyẹ náà.
Lára ayẹyẹ tọdún 2023, eré ìdíje bọ́ọ́lù àfẹsẹ̀gbá wáyé láàárín ìlú Kumbungu àti Savelugu. Gbọ̀ngán Aliu Mahama Sports Stadium tó lè gbà ju ènìyàn 20,000 ló kún lọ́jọ́ náà.[8] Kumbungu àti Savelugu ní ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́rán láàárín ara wọn, èyí tí wọ́n pè ní Dachahali nínú Dagbani. Àwọn ènìyàn pàtàkì wá sí ìdíje náà pẹ̀lú àwọn ìjòyè ńlá ńlá láti ìlú Tolon, Savelugu àti Kumbungu.
Tún wo
àtúnṣeÀwọn Ìtọ́kási
àtúnṣe- ↑ "Festivals in Ghana". www.ghanaweb.com. Retrieved 27 December 2011.
- ↑ Mohammed, Mutaka (2021-12-21). "U.S: Dagbon Diaspora celebrate Damba Festival". Diamond 93.7FM (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-10-18.
- ↑ admin (2021-12-15). "Northern Ghana Diaspora C’nity in New Jersey to celebrate Damba Festival, Dec 18". Ghanaian Times (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-10-18.
- ↑ "Northern Ghana Diaspora Community celebrates Damba Festival - MyJoyOnline". www.myjoyonline.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-12-22. Retrieved 2023-10-18.
- ↑ "Kpanjɔɣu". www.wikidata.org. Retrieved 2023-03-03.
- ↑ "Dagbon marks Damba Festival after 17-year break". Archived from the original on 2019-11-19. Retrieved 2020-01-18. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Damba Festival". Visit Ghana. Retrieved 2020-01-18.
- ↑ "Historic Savelugu-Kumbungu football clash fills 21,000-capacity Aliu Mahama Stadium". GhanaWeb (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2023-10-08. Retrieved 2023-10-09.
Ìjápọ̀ Tìta
àtúnṣe- Media related to Damba: Ọdún Damba at Wikimedia Commons