Daniel Ademinokan jẹ́ òṣèrékùnrin, àti aṣàgbéjáde fíìmù ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó ti ń ṣiṣẹ́ òǹkọ̀tàn láti ọdún 1990, àmọ́ ó di gbajúmọ gẹ́gẹ́ bí i olùdarí fíìmù fún fíìmù Black Friday, èyí tí wọ́n ṣe ní ọdún 2010. Òun ni olùdarí àgbà àti olùdásílẹ̀ Index Two Studios LLC, èyí tí òun àti ìyàwó rẹ̀ ìgbà kan jìjọ ni Stella Damasus. Lẹ́yìn tí òun àti ìyàwó rẹ̀ pínyà ní ọdún 2020, Daniel ṣe ìdásílẹ̀ Leon Global Media, LLC pẹ̀lú àgbéjáde fíìmù GONE. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, Daniel ń gbé ní Houston, Texas.[1][2][3][4]

Daniel Ademinokan
Orúkọ àbísọDaniel Oritsebawo Ademinokan
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian, American
Iléẹ̀kọ́ gígaDigital Film Academy, New York Film Academy, University of Ibadan
Iṣẹ́
  • Film & TV Director
  • Screenwriter
  • Film Producer
Ìgbà iṣẹ́1990s-Present
OrganizationIndex Two Studios LLC, Léon Global Media LLC
Notable work
Olólùfẹ́
Websitehttps://www.danielademinokan.com/

Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Daniel gboyè ẹ̀kọ́ nínú ìmọ̀ Computer Science ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lẹ́yìn èyí, ó kó lọ sí United States, níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe fíìmù ní Digital Film Academy, ní New York. Ó tẹ̀síwájú láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Digital Cinematography ní New York Film Academy.

Iṣẹ́ tó yàn láàyò

àtúnṣe

Daniel bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i òǹkọ̀tàn, tí ó kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn tí wọ́n sọ di fíìmù, èyí tó gbajúmọ̀ ní àọn ọdún tó tẹ̀lé ọdún 1990. Ó di gbajúmọ̀ lẹ́yìn tí ó ṣe àgbéjáde fíìmù Black Friday, èyí tí wọ́n yàn fún àmì-ẹ̀yẹ márùn-ún ọ̀tọ̀tọ̀ ní Africa Movie Academy Awards. Fíìmù kúkurú rẹ̀, ìyẹn No Jersey, No Match tó jáde ní ọdún 2010, èyí tí Gabriel Afolayan kópa nínú gba àmì-ẹ̀yẹ ní Abuja International Film Festival, èyí tí wọ́n ṣàfihàn ní Hoboken Film Festival ní New Jersey.

Ìgbésí ayé ara ẹni

àtúnṣe

Daniel fẹ́ Doris Simeon ní ọdún 2008, wọ́n sì pínyà ní ọdún 2011. Àwọn méjèèjì bí ọmọkùnrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ David Ademinokan, tí wọ́n bí ní ọdún 2008. Daniel fẹ́ Stella Damasus ní ọdún 2012, àmọ́ wọ́n pínyà ní ọdún 2020.[5]

Àwọn fíìmù rẹ̀

àtúnṣe
  • Gone (2021)
  • Shuga (TV series)
  • Here (Short 2019/II)
  • Between (2018/III)
  • The Other Wife' (2018)
  • The Search (2012/V)
  • Ghetto Dreamz: The Dagrin Story (documentary 2011)
  • Unwanted Guest (2011)
  • Eti Keta (2011)
  • Bursting Out (2010)
  • Too Much (2010/I)
  • Modúpé Tèmi (Video 2008)
  • In the Eyes of My Husband (video 2007)
  • In the Eyes of My Husband 2 (video 2007)
  • In the Eyes of My Husband 3 (video 2007)
  • Onitemi (video 2007)
  • The Love Doctor (video 2007)
  • Omo jayejaye (video 2006)
  • Black Friday (2010)

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Ademinokan Opens the ‘Gone’ Thriller – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com. Archived from the original on 2022-07-30. Retrieved 2022-07-30.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "‘Gone’ Thriller Hits Calgary Black Film Festival – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com. Archived from the original on 2022-07-30. Retrieved 2022-07-30.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "Stella Damasus, Daniel Ademinokan celebrate wedding anniversary". TheCable Lifestyle (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-05-28. Retrieved 2022-07-30. 
  4. "Official Website of Daniel Ademinokan | Home". dabishop (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-30. 
  5. Wesley-Metibogun, Shade; THEWILL (2021-05-30). "Stella Damasus, Ex-Husband in War of Words" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-08-01.